Wọn tí sọ Nàìjíríà di Zimbabwe: Alága ẹgbẹ́ NLC figbe ta

Alága ẹgbẹ òṣìṣẹ́ NLC, Joe Ajaero, tí ni ìjọba orilẹ ede Naijiria ti sọ Naijiria di orilẹ ede Zimbabwe látàrí ebi àti ìyàn tó wà lorilẹ èdè Nàìjíríà.
Ajaero ni ojúṣe ìjọba ni láti rí pé ètò ààbò wà fún tonile talejo,láti mojuto eto ọrọ̀ ajé,kì wọ́n sì mu igbe ayé dẹ̀rùn bá mútù-mùwà.
Ẹgbẹ́ òsìsẹ́ NLC gúnlè ètò ìwọ́de nílùú Abùjá látàrí ọwọn gógó oúnjẹ,ètò ààbò tí ko péye àti ìníra to de ba àwọn ènìyàn.
Ọpọlọpọ àkọlé ni àwọn ènìyàn gbe dani lára wọn ni eyi to sọ pe 'ebi ń pa wá'.
Tí a ò bá gbàgbé pé lọ́sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ òsìsẹ́ NLC fi ìkéde síta pé àwọn yóò se ìwọ́de ọlọ́jọ́ méjì ní lọ́jọ́ ketadinlọgbọn, oṣù Kejì àti ọjọ́ kejidinlọgbọn osu keji lórí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ bí owó náírà se di yẹpẹrẹ,bí owó ilé- ìwé se gbówó lórí àti bí ìníra se de ba gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria.
Àwọn òṣìṣẹ́ NLC bẹ̀rẹ̀ ètò ìwọ́de ni ilé ẹgbẹ́ Labour House to wa nílùú Abùjá,tí wọ́n sì gbé ètò ìwọ́de náà lọ si Ile Asofin orileede Naijiria.
Bákan náà, bí àwọn òṣìṣẹ́ NLC se parí ìwọ́de tiwọn naa ni àwọn kan náà tún gbé ìwọ́de tiwọn náà wà sí ilê ìgbìmọ̀ aṣòfin láti wá fi atilẹyin wọn hàn sì ìjọba ààrẹ Ahmed Bọla Tinubu.
Lára àwọn akọle tí wọn gbé lọ́wọ́ wí pé'Tinubu yóò se atunto sì ètò ọ̀rọ̀ ajé.ojú yóò tí àwọn ọ̀tá Naijiria,abbl.


Oríṣun àwòrán, @TUC
Ẹgbẹ osisẹ TUC ti kede síta pe awọn ko pẹlu ifẹhonhan ati ìwọde ọlọjọ meji ti ẹgbẹ osisẹ Labour NLC gunle lati fi tako ọwọngogo to gbode lẹyin yíyọ owo iranwọ epo bẹntiroolu.
TUC salaye pe idi ti awọn ko fi fọwọsowọpọ pẹlu NLC ni pe iwọde ti wọn gunle yii ko sinu igbesẹ akọkọ to jẹ mọ fifun ìjọba apapọ ni ọjọ mẹrinla lati se atunṣe sì owo oṣu awọn osisẹ ninu oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Festus Osifo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja lori awọn igbesẹ tí ìjọba le gbe lati tako ọwọngogo to gbode lasiko yii.
" Ko si adehun pe ìwọde yii ma waye, ti a ba jọ n se nnkan papọ, a jọ ma bọ sita lati bá yín sọrọ.
"Lọjọ tí kede jade nípa ìwọde, n jẹ ẹ ri ọmọ ẹgbẹ TUC nibẹ. Mo mọ pe gbogbo yin ri lẹta nipa ìwọde, awọn ọmọ ẹgbẹ NLC nikan lo wa fun.
"Pẹlu eyi, o ti han gbangba idi ti a ko le fi kopa. A ko ba wọn lọwọ ninu adehun.
Ẹ fi aye gba kiko oúnjẹ wọle lati okun- TUC gba ìjọba ni ìmọ̀ràn
Aarẹ ẹgbẹ osisẹ TUC ni awọn ti ṣeto ọna abayọ fun ìjọba apapọ lati tako ọwọngogo to gbode lasiko yii.
Osifo ni o se koko ki Aarẹ Tinubu fi aye gba pe ki kiko oúnjẹ wọle si orilẹede Naijiria lati oke okun.
O tẹsiwaju pe orilẹede Naijiria ko ti rí irufẹ lasigbo yii paapa lasiko ologun.
"Awọn ọmọ Naijiria ni lati wa laye ki wọn le mọ pe igbesẹ Aarẹ Tinubu jẹ eyi to rẹwa.
"Kiko oúnjẹ lasiko yii yoo mu adikun ba ebi to gbode lasiko yii lorilẹede Naijiria.
"Ijọba ni lati fi aye gba kiko oúnjẹ wọle laarin ọsẹ meji."
A ò ní ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè lórí ọrọ̀-ajé Nàìjíríà tó ń ṣòjòjò lọ́wọ́ yìí - Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/Facebook
Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe ijọba oun ko ni idahun si gbogbo ibeere lori iṣoro to n koju orilẹede Naijiria lọwọ yii.
Amọ, aarẹ ni ko si ẹni to le bu oun pe ijọba oun ko gbiyanju lati wa ojutuu si ipenija to n koju Naijiria bayii.
Tinubu sọrọ yii nibi ipade to ṣe nile iṣẹ ijọba l’Abuja lọjọ Aiku pẹlu awọn gomina atawọn akọṣẹmọsẹ nipa ọrọ-aje to yan lati ṣiṣẹ pọ wa ọna abayọ si ọrọ-aje Naijiria to n ṣojojo.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni gomina Charles Soludo ipinlẹ Anambra, Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun; gbajugbaja oniṣowo, Aliko Dangote, Abdul Samad Rabiu, Tony Elumelu, ati Ọgbẹni Segun Ajayi-Kadir to jẹ ọgagba ajọ M.A.N. to n ri awọn ileeṣẹ to n ṣe nnkan tawọn araalu n lo.
Aarẹ Naijiria ti sọ fun igbimọ yii lati ṣe ipade pọ loorekoore ki wọn si gba ijọba ni imọran lori ọna abayọ si eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.
Tinubu sọ pe ‘’ẹ jẹ ki a wo ohun ti a n ṣe daadaa ati awọn ohun to ku diẹ kaato ti a n ṣe ati ohun ti a le ṣe lati jẹ ki ọrọ-aje Naijiria pada bọ sipo.
Gẹgẹ bi mo ti ṣe sọ siwaju, awọn ọmọ Naijiria nikan ni ijọba mi lati tẹ ẹ lọrun.
Ọrọ awọn akẹkọọ jẹ ijọba mi logun, bakan naa ni ọrọ awọn agbẹ, awọn oniṣowo, to fi mọ awọn baba ati iya.
A n wa ọna lati ṣe iranwọ fawọn ọmọ Naijiria ti ko ri ọwọ họri, a fẹ fun wọn ni ireti.’’
Tinubu ni bo tilẹ jẹ pe ijọba oun le ma ni gbogbo idahun sawọn ibeere lori ipenija to n koju Naijiria lọwọ, o fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ọrọ-aje Naijiria yoo pada bọ wa sipo labẹ ijọba oun.















