Ṣé lóòótọ́ ni pé Dapo Abiodun ń ṣètò 'palliative' N10,000 lójú òpó ayélujára f'aráàlú?

Aworan Gomina Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, ogunupdatee

A ko lọwọ ninu eto pinpin iranwọ paliatiifu kankan loju opo ayelujara fun awọn eeyan ipinlẹ Ogun.

Igbe ree ti ijọba Gomina Dapo Abiodun fi sita lati le tako iroyin ti wọn juwe gẹgẹ bi ayederu to gba oju opo ayelujara pe ijọba n ṣeto paliatiifu ẹgbẹrun mẹwaa Naira fun araalu.

Ninu atẹjade ti oluranwọ pataki si Gomina lori ọrọ iroyin ati ibaraẹnisọrọ, Kayode Akinmade, fi sita, o ni patapata ni ijọba Ogun fi wẹ ọwọ rẹ mọ lori iroyin yi to si kesi araalu lati ṣọra fun tori pe o daju wi pe gbajuẹ ni wọn fẹ si ṣe.

Eeyan kọọkan ni iroyin oju opo yi sọ pe Gomina Dapo Abiodun yoo fun ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira gẹgẹ bi owo iranwọ jakejado ipinlẹ ọhun.

Ikede iranwọ yi ṣe agbekalẹ oju ila opo kan tawọn eeyan le tọ lati fi jẹ anfaani owo iranwọ yi.

Bẹẹ naa ni wn tun gba awọn eeyan ni imọran lati ṣalabapin iroyin yi.

Lasiko ti nkan ko fararọ fun ọpọ ọmọ Naijiria yi, ibikibi ti iranwọ ba ti wa ni ọpọ a maa tẹwọ gba a lae bikita.

Awọn ijọba ipinlẹ kọọkan ti kede iranwọ tawọn mii naa si ti bẹrẹ eto iranwọ ni paapa ounjẹ lati le maye dẹrun faraalu.

Ipinlẹ Ogun ninu atẹjade yi sọ pe awọn ko ṣeto owo pinpin amọ awọn ko dẹkun ifarajin nipa mimu ayẹ dẹrun faraalu.

Akinmader sọ pe ''ijọba Gomina Abiodun ko sinmi lati mu adinku ba iṣoro ti araalu n koju nipa awọn eto iranwọ taa ti gbe jade lati ọdun 2019 ati eto iranwọ biliọnu marun un taa kede laipẹ yi''

Ijọba wa kilọ fun araalu lati yago fun oju opo to n kede iroyin ofege to si sọ pe ti ikede kankan yoo ba waye, loju opo ijọba ti gbogbo eeyan mọ lawọn yoo fi si.

Aworan oju opo ti ijọba Ogun sọ pe opo gbajuẹ ni

Ijọba ko kede boya awọn eeyan kan ti kagbako gbajuẹ loju opo yi ṣugbọn wọn fi oju opo naa sinu atẹjade ti wọn gbe sita.

Bẹẹ si ni wọn kilọ pe ki awọn eeyan ma tọ oju opo naa lọ tabi ki wọn fi iroyin nipa ara wọn ṣọwọ sibẹ.

BBC gbiyanju lati tọ oju opo yi lọ taa si ri wi pe awọn to ṣeto rẹ fi aworan Gomina Dapo Abiodun sibẹ gbagada.

Bakan naa ni wọn tun faaye silẹ nibi ti awọn araalu yoo ti wọ oju opo naa lọ.

Nigba ti a o fi ri oju opo yi, eeyan to le ni ẹgbẹrun mejilelọgọjọ lo ti fi ifẹ han si oju opo yi tawọn aimọye eeyan naa si ti ba wọn ṣe alabapin oju opo naa.