Tinubu, kéde ìlú ó fararọ ní Nàìjíríà lórí ọ̀wọ́ngógó tó gbòde - Àjọ ọmọ lẹ́yìn Krístì PFN

Oríṣun àwòrán, Office of the SA on Social Media to PBAT/x
Ajọ ọmọ lẹyin Kristi PFN ti rọ Aarẹ Bola Tinubu lati kede ilu o fararọ lorilẹede latari bi ọwọngogo ṣe gbode lasiko yii.
Aarẹ ajọ naa, Biṣọọbu Wale Oke lo sọ eyi lasiko ipade apapọ ọmọ lẹyin Kristi ti ajọ CPFN/PFN níbi tí wọn ti sọrọ nipa gbogbo ìnira tí ilu n la kọja lasiko yii
O ni "A ni lati gbajumọ ìnira ti a n la kọja eyi to ti mu kudiẹkudiẹ ba eto ọrọ Aje.
"A n rọ gbogbo awọn Oludije ninu eto idibo to kọja lati gbe ede ayede silẹ, ki wọn si fa alaafia mọra.
"Kí wọn gba nnkan ti ileẹjọ sọ, kí wọn fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Tinubu lati mu idagbasoke sí ilu.
"Bi a ṣe pe nnkan o fararọ lasiko yii ni Naijiria, ọwọngogo, epo gbewo lori, elo ikọle gbewo lori, oúnjẹ, simẹnti, irinna.
"Ṣìbẹsibẹ owo oṣu osisẹ o gbe owo lori.
"Aarẹ ni lati gbe igbesẹ ni kiakia lati wa irọnu fun ọmọ Naijiria, ti wọn si se afihan ijọba awarawa han pe ijọba le tan ìṣòro araalu.
"Aarẹ Tinubu ni lati gbe igbesẹ lori owo oṣu awọn osisẹ kaakiri orilẹede sugbọn sibẹsibẹ wọn ní lati koju eto ọrọ aje to mẹyẹ."
Oke tun wa kesi Aarẹ Tinubu lati kede ilu o fararọ lori eto abọ to mẹyẹ to da eto alaafia laamu.
"Mo rọ Aarẹ lati boju wo ileeṣẹ ifowopamọ daada nítorí awọn Ọga banki n kowo araalu sapo.
"Awọn eeyan Naijiria n padanu ẹmi wọn, awọn ọdọ ko ni isẹ, awọn osisẹ fẹyinti o ri eto wọn gba.
"A n rọ Aarẹ lati fọ ileeṣẹ Banki mọ lati bu ọla fun owo Naira. Owo oṣu osisẹ ìjọba ko le ra epo sinu ọkọ.
O gba a ladura pe ki Ọlọrun da si ọrọ Naijiria, ko si se iranlọwọ fun Aarẹ ati ikọ rẹ lati mu idagbasoke ba ilu.















