Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ewu wà nínú gbígbé oúnjẹ pamọ́ sínú ẹ̀rọ a mú omi tutù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Abdullahi Bello Diginza
- Role, BBC Hausa
- Reporting from, Abuja
Ẹrọ a mu omi tutu ti oloyinbo mọ si refrigerator ni o wa fun sise itọju nnkan lati ma bajẹ paapa omi to wa ni ike tabi kọpu.
Ẹwẹ, awọn eeyan n lo ẹrọ yii lati ko ounjẹ si ati awọn ohun mii to wulo pamọ sinu rẹ lati ma le jẹ ko le bajẹ.
Eyi to gbajumọ ju ti wọn ma gbe sinu ẹrọ naa ni ounjẹ sise, ti wọn ko le jẹ tan, ọbẹ sise, ẹran sise tabi tutu ti wọn ko fẹ ko bajẹ.
Sugbọn awọn onimọ iṣegun ti jẹ ko di mimọ pe ewu wa ninu lilo ẹrọ yii lati gbe ounjẹ pamọ si, to si aisan si ago ara eeyan ti ko ba sọrọ.
Dokita Auwal Musa Umar, olori fun ẹgbẹ awọn dokita onimọ nipa ounjẹ lorilẹede Naijiria, ti ẹka ipinlẹ Kano ni ewu mẹrin lo wa nipa gbigbe ounjẹ si ẹrọ amu omi tutu yii
Sisọ adun ounjẹ nu
Ounjẹ ti wọn ba gbe sinu ẹrọ amu omi tutu ma padanu adun to wa ninu rẹ.
Ti adun to ba ounjẹ wa ba ti pora, ko si anfani ti ounjẹ naa le ṣe mọ.
O ni adun ounjẹ lo jẹ ki a ni oye irufẹ ounjẹ ti a n jẹ
“Ti o ba ti padanu adun to ba ounjẹ wa lati ilẹ, o ni le jẹ,” Dokita salaye.
Pipadanu awọn ohun aṣaralore to wa ninu ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita ni ounjẹ ti wọn ba gbe sinu ẹrọ yii lo ṣeeṣe ko padanu awọn eroja aṣaralore to wa ninu ounjẹ naa eyi to yẹ ko ṣe anfani fun ago ara wa.
O ni sisọ adun ninu awọn ounjẹ yii nu yii lo n fa nnkan ti a n pe ni ‘Ebi to farapamọ’.
Awọn eroja kan wa to le parun it wọn ba ri otutu tabi ooru to pọju.
“Eroja vitami C tabi vitami B wa lara awọn vitami to ma n parun ti wọn ba wa ninu ẹrọ amu oni tutu fun igbapipẹ”.
Dokita Auwal fikun pe aisi awọn eroja yii ninu ago ara awọn eeyan le mu ewu dani nitori bi wọn ṣe n parun ninu ẹrọ amu omi tutu ti a n gbe wọn si.
Awọn eroja yii lo ma gbe ogun ti awọn aarun to ba kọlu ago ara , fun idi eyi, ti wọn ko ba wa ni ago ara, o le fa ọpọlọpọ ewu.
Àfikun omi ara
Jijẹ ounjẹ ti wọn gbe pamọ si ẹrọ amu omi tutu le fa ara sisan gẹgẹ bi onimọ ṣe salaye.
O fikun pe ounjẹ ti wọn ba gbe sinu ẹrọ amu omi tutu ma n ko ọra to wa ninu ounjẹ jọ, to si jẹ pe ti wọn ba tun gbe kana, ki se gbogbo ọra naa ni yoo kuro.
“A dẹ mọ pe ti ọra ba pọju, o le jẹ ki eeyan sara asanju, eyi to tun le fa orisiri aisan.”
Ifunpa to ga soke,
Dokita Anwal Musa Umar ni fifi ounjẹ papmọ sinu ẹrọ yii le fa ki iyọ lekun ninu ounjẹ.
“Bi ẹrọ naa ṣe n tutu le fa afikun iyọ sinu ounjẹ.
“Ọpọlọpọ aisan ni eyi le fa nitori bi ẹrọ na ṣe ko ọra jọ.”
Yatọ si ifunpa giga ati aisan ọkan, itọ suga, aisan kidirin ni eyi ke fa sago ara eeyan.
“Gbigbe oubjẹ sinu ẹrọ yii ma di iyọ sinu ounjẹ naa.”
Irufẹ ounjẹ wo lo le wa ninu ẹrọ yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Anwal Musa Umar ni awọn nnkan to yẹ ki a ma ko pamọ sinu ẹrọ amu oni tutu ni omi mumu, ati awọn eso olomi kọọkan,
“Ninu wọn ko ki n bajẹ, fun idi eyi ti wọn ba wa ni ẹrọ amu omi tutu, ko si ipalara ti wọn le ṣe.
“Awọn ounjẹ wo ni ko yẹ ko wa ninu ẹrọ yii?"
Onimọ yii ni awọn ounjẹ to ba le bajẹ ni ko yẹ ko wa ninu ẹrọ amu omi tutu.
“Ounjẹ to ba jẹ bi ẹran, ẹfọ ati awọn nnkan mii ni ko yẹ ki a gbe sinu ẹrọ amu omi tutu.
“Awọn ounjẹ to ba ti le padanu adun ni ko yẹ ki a gbe sinu ẹrọ yii..”
O ni ti ẹfọ ba pẹ ju ninu ẹrọ yii, o le padanu awọn vitami ati eroja to wa ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọna miiran to fi le gbe ounjẹ pamọ
Dokita ni iwadii fihan pe ounjẹ ti a ba gbe pamọ ko gbọdọ kọja wakati mejidinlaadọta.
O ni awọn ounjẹ to ba jẹ pe wọn din le lo ọjọ mẹrin lai bajẹ.
“To ba ti jẹ pe o fi nnkan bo ounjẹ, o le wa lai bajẹ fun ọjọ mẹrin.”
- Sisaa
- Sisun
- Didan
- Yiyan
Ṣe o tọna lati gbe ounje to ba ti di kana pada.
Ọpọ eeyan lo ma n gbe ounjẹ kana lẹyin ti wọn ba gbe kuro ninu ẹrọ amu omi tutu ki wọn to jẹ.
Ẹwẹ, Dokita ni gbigbe ounjẹ si ẹrọ yii fun igba pipẹ le ma jẹ ki kokoro wa ninu ounjẹ naa.
“Sugbọn kete ti wọn ba ti gbe sita, ni o ṣe ki kokoro tẹnu bọ ounjẹ nitori adikun to n de ba bi o n ṣe tutu,
O wa fikun pe ti ounjẹ naa ba ti de ori ina, o ni iye gbigbona ti yoo ṣekupa awọn kokoro to ti ẹnu bọ ounjẹ naa.















