Wo ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe láti gbọn ìṣẹ́ dànù lára aráàlú

Aworan gominina ipinle Eko, Ogun ati Oyo

Oríṣun àwòrán, Facebook

Awọn gomina ipinlẹ Yoruba kan ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lori ati mu adinku ba ebi to n pa araalu latari ọwọngogo nnkan to gbode lorilẹ ede Naijiria.

Laipẹ yii l'awọn eeyan bẹrẹ síi ṣe ìwọ́de l'awọn ipinlẹ kan lati fi ẹhonu wọn han lori bi gbogbo nnkan ṣe di wiwọn papaa julọ ounjẹ.

Ọpọ lo tu jade laipẹ yii lati ṣe ifẹhonuhan niluu Ibadan, Osogbo ati nipinlẹ Kogi, Niger to fi mọ Kano lapa ariwa Naijiria nibi ti wọn ti kepe ijọba lati ojutuu si ọwọngogo to gbode.

Ajọ NBS to n ri si iṣiro nkan sọ pe igba àkọkọ ree ti ounjẹ at'awọn nkan mii yoo won julọ niyi fun bii ọgbọn ọdun.

Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ṣe ipade pẹlu gomina awọn ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji laipẹ yii nibi ti o ti sọ fun won pe ki wọn gbe igbesẹ lati ṣe iranwọ fawọn eeyan ipinlẹ wọn lori bi gbogbo nkan ṣe di wiwọn.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko kede adinku owo ọkọ ati ipese ounjẹ

Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko kede ni Ọjọbọ pe ijọba oun ti ṣeto lati maa pese ounjẹ ẹẹkan lojumọ fun ẹgbẹrun kan eeyan ni gbogbo ijoba ibilẹ kọọkan nipinlẹ naa.

Sanwo-Olu ni eyi jẹ ọkan lara ọna ti ijọba oun fẹ gba lati mu adinku ba ebi to n pa araalu.

Gomina ni pẹlu gbogbo ohun ti ijọba n lakọja, ijọba rẹ n gbiyanju lati pari oju ọna reluwe ati awọn nnkan mii ti yoo mu irinna rọnu laarin igboro Eko.

Sanuwo Olu fikun pe ijọba ti yọ ida mẹẹdọgbọn kuro ni owo ọkọ BRT, Reluwe ati Ferri, ti ọrọ si n lọ lọwọ pẹlu awọn ẹgbẹ awakọ lati mu adikun ba iye owo ọkọ akero ‘Yellow Bus’.

Sanwo-Olu tun mu adinku ba iye ọjọ t'awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Eko yoo maa lọ si ibi iṣẹ.

Aworan ounje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina ni "a fẹ bẹrẹ pẹlu awọn osisẹ ijọba wa, lati ibẹrẹ ọsẹ to n bọ, awọn osisẹ ijọba to wa ni ipele kẹrinla ati awọn to kere si ipele yoo ma wa si ibisẹ ni ọjọ mẹta laarin ọsẹ, ti awọn to wa ni ipele mẹdogun soke yoo ma ni ọjọ mẹrin laarin ọsẹ.”

Gomina wa kesi awọn ileeṣẹ aladani lati wa nnkan miiran ti awọn le ṣe lati ran awọn araalu lọwọ gẹgẹ bi wọn ṣeṣe lasiko itankalẹ aarun Corona.

Ijọba Oyo pin ₦500m fawọn olokoowo kekeke

Ijọba Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti pin ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira fun awọn olokowo kekeke ti iye wọn le ni ẹgbẹrun meji lati ṣowo.

Owo ọhun, to jẹ owoya ni wọn pin labẹ eto Sustainable Action for Economic Recovery (SAfER).

Ṣaaju ni gomina Makinde ti kọkọ ṣeleri pe ijọba oun yoo pese owo naa fun awọn olokowo ọhun, eyii ti wọn yoo san pada pẹlu ele diẹ.

Owo naa ni ijọba Oyo pin nipasẹ awọn ile ifowopamọ alabọde meje kaakiri ipinlẹ ọhun.

Apapọ iye awọn oṣiṣowo to ri owo naa gba, gẹgẹ bii atẹjade ijọba ni 2,078.

Nigba to n sọrọ lori owo naa, alaga SafER, Otunba Segun Ogunwuyi ni gomina Makinde gbe igbesẹ ọhun lọna sti ṣatilẹyin fun awọn oniṣowo kekeke, ati pe ijọba mọ ojuṣe wọn lara eto ọrọ aje ipinlẹ naa.

Ogunwuyi, to tun jẹ olori oṣiṣẹ gomina Makinde ni ọpọ oniṣowo ipinlẹ Oyo lo jẹ oniṣowo kekeke.

O fi kun pe niwọn igba ti ijọba ba le ṣatilẹyin fun wọn, yoo rọrun fun awọn eeyan naa lati ṣowo ati lati jere, eyii ti yoo mu ọ

Ijọba ipinlẹ Ogun pin ounjẹ ati owo fun araalu

Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede igbesẹ lati pin ounjẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa.

Ijọba gomina Dapo Abiodun ni ounjẹ bi irẹsi, ẹwa ati gaari l'awọn yoo pin fun araalu.

Gomina Abiodun sọ loju opo X rẹ pe ijọba ti ṣe eto lati bẹrẹ si ni pin ọgọrun tirela irẹsi fawọn araalu ni kiakia.

Gomina ni awọn agbalagba at'awọn ti ko ri ọwọ họri yoo gba irẹsi ọfẹ, nigba t'awọn mii yoo lanfaani lati ounjẹ naa ni iye ti wọn n ta a tẹlẹ ki dọla to bẹrẹ si ni wọn sii.

Aworan ounje

Oríṣun àwòrán, Other

Bakan naa ni gomina wi pe ijoba ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati lo biliọnu marun un naira ti ijọba apapọ gbe fun ipinlẹ naa fun iranwọ lori ọwọngogo to gbode.

Gomina ipinlẹ Ogun tun kede ẹgbẹrun l'ọna aadọta naira gẹgẹ bi owo iranwọ fun ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn akẹkọọ ni ipinlẹ naa.

Ijọba kede owo iranwọ fun ẹgbẹrun l'ọna aadọrin eeyan eyi t'awọn oloyun wa ninu wọn.

"ijọba yoo fun ẹgbẹrun l'ọna ọgọrun akẹkọọ ijọba ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ni ẹgbẹrun mẹwaa gẹgẹ bi iranwọ.

A o tun pin iwe marun un marun un fun gbogbo akẹkọọ ile ẹkọ ijọba alakọbẹrẹ ati girama ti gbogbo wọn jẹ 850,000," Abiodun lo sọ bẹẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ijọba ipinlẹ Osun ṣe ifilọlẹ igbimọ lori ipese ounjẹ

Gomina Ademola Adeleke ipinle Osun ti Kede pe ijọba oun ti ṣe ifilọlẹ igbimọ kan ti yoo ṣiṣẹ lori ati pin ounjẹ fun araalu.

Gomina Adeleke ni ijọba oun n ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe iranwọ fun araalu lori ọwọngogo ounjẹ at'awọn nkan mii.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ gomina, Olawale Rasheed fi sita ṣe sọ, gomina Adeleke sọ fun igbimọ to gbe dide naa lati ṣiṣẹ lori ọna ti ounjẹ yoo fi pọ ni ipinlẹ Ọsun.

Lara ohun ti ijọba ni ki wọn ṣiṣẹ le lori ni bi eto ọgbin yoo ṣe gbooro sii ni ipinlẹ Osun.

Bakan naa ni gomina tun sọ fun igbimọ ohun lati ṣe amojuto iye tawon ontaja n ta ounjẹ ni ipinlẹ Osun.

Gomina Adeleke tun sọ fun igbimọ naa lati sọ fun ijọba iru igbesẹ to ba yẹ lati gbe to le mu adinku ba ebi to n pa araalu.

Gomina fun igbimọ naa ni ọjọ diẹ lati jabọ fun ijọba lori ohun ti wọn ba fẹnu ko le lori