Ẹ̀mẹẹ̀ta l'ọ́sẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba yóò máa wá sí ibi iṣẹ́ - Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Babajide Sanwo Olu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti pasẹ fun awọn osisẹ ijọba lati maa wa si ibi iṣẹ fun ọjọ mẹta laarin ọsẹ.
Bakan naa ni Gomina tun kede yiyọ ida mẹdọgbọn ninu owo ọkọ BRT fun araalu.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu Ileeṣẹ momaworan TVC ni Gomina ti kede pe oun gbe igbesẹ yii lati dẹkun bi ọwọngogo ṣe gbode ni ipinlẹ Eko ati lorilẹede Naijiria.
Sanwo-Olu ni aanu araalu ṣe oun pupọ, sugbọn gẹgẹ bi olori ilu, ijọba gbọdọ wa ojutu si iṣoro ọrọ aje to n fa ebi ni ilu.
“A fẹ bẹrẹ pẹlu awọn osisẹ ijọba wa, lati ibẹrẹ ọsẹ to n bọ, awọn osisẹ ijọba to wa ni ipele kẹrinla ati awọn to kere si ipele yoo ma wa si ibisẹ ni ọjọ mẹta laarin ọsẹ, ti awọn to wa ni ipele mẹdogun soke yoo ma ni ọjọ mẹrin laarin ọsẹ,”
Gomina ni pẹlu gbogbo ohun ti ijọba n lakọja, ijọba rẹ n gbiyanju lati pari oju ọna reluwe ati awọn nnkan mii ti yoo mu irinna rọnu laarin igboro Eko.
Sanuwo Olu fikun pe ijọba ti yọ ida mẹdogun kuro ni owo ọkọ BRT, Reluwe ati Ferri, ti ọrọ si n lọ lọwọ pẹlu awọn ẹgbẹ awakọ lati mu adikun ba iye owo ọkọ akero ‘Yellow Bus’.
Bakan naa ni ijọba ti se eto idanimọ fun awọn ile olounjẹ ni awọn ijọba ibilẹ lati ma fun eeyan ẹgbẹrun kan ni ounjẹ ni ẹkan lojumọ.
Gomina wa kesi awọn ileeṣẹ aladani lati wa nnkan miiran ti awọn le ṣe lati ran awọn araalu lọwọ gẹgẹ bi wọn ṣeṣe lasiko itankalẹ aarun Corona.
“Asiko lati ran awọn araalu lọwọ ni a wa yii.”















