Tinubu, tètè dá owó ìrànwọ́ epo padà, kí ara le dẹ aráàlú - Àwọn Olùwọ́de l‘Osogbo

Awọn Oluwọde

Agbarijọjọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọẹni (Civil Societies Coalition) nipinlẹ Ọsun ti pariwo sita wi pe, inira ti isejọba Bola Tinubu da silẹ ti pọ ju.

Wọn ni awọn fẹ ki Aarẹ Tinubu da owo iranwọ ori epo petirolu pada ki inira yii le dopin.

Alaga fun ẹgbẹ ajafẹtọẹni naa, Waheed Lawal, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe kaka ki ewe agbọn dẹ lori inira orile-ede Naijiria, se lo tun le koko si.

Bakan naa lo rọ Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke pe ko lo owo ti ijọba apapọ fi ransẹ si, fun ara ilu lọna to yẹ.

Awọn Oluwọde

"Tinubu, jọ̀ọ́ mase sọ eto isejọba Naijiria dì oniyara kan"

Nigba ti oun naa n ba BBC Yoruba sọrọ lasiko iwọde ọhun, Frederick Adegoke to jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ Civil Societies woye pe nigba ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu de orí ìjọba ni inira ati osi pọ si.

"Ida lọna aadọrin eeyan lo nbẹ ninu osi ati isẹ, ki Aarẹ Bola Ahmed Tinubu to gba ìjọba.

Amọ ni asiko ìjọba Aarẹ Tinubu yii, ni isẹ ati osi wa n peleke si lojojumọ, ti oun jíjẹ ko si se ra mọ lọja mọ bayii."

Frederick Adegoke tun rọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu pe ko maa sọ eto isejoba orile-ede Naijiria dì yara kan nitori awọn ko ni fi aye gba iru ijọba bẹẹ rara.

Bakan naa ni Wale Balogun ni ibi ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu n mu orile-ede Naijiria lọ ko ye awọn rara.

" ijọba tun fẹ fi owo kun owo ina mọnamọna bayi, mo si rọ gbogbo olugbe Ipinlẹ ọsun lati jade sita ni ọjọ Aje to nbọ fun ifehonuhan ti awọn NLC.

Oniruuru orin eebu ni awọn oluwọde naa kọ, ti wọn si pe ọpọ akọle lọwọ lati se ifehonuhan naa.

Àkọlé fídíò, Lion Attack: Ọwọ́ Olawuyi ni wọ́n bí Kìnìún tó pa á sí, ẹ̀mí òṣìṣẹ́ rẹ̀ ló fẹ́ dóòlà - OAU

Ìwọ́de gbòde ní Osogbo torí ebi, ìṣẹ́ àti òṣì tó gbòde ní Nàíjíríà

Atẹjade

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ajafẹtọẹni (OCSC) ẹka ti ipinlẹ Osun ti kede pe awọn yoo gunle iwọde kan lonii, Ọjọbọ, ọjọ Kejilelogun osu keji ọdun yii.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ ajafẹtọẹni naa fisita, eyi ti Comrade Waheed ati Olowu dijọ fọwọsi lo sisọ loju ọrọ yii.

Bakan naa ni wọn kede pe gbagede Nelson Mandela Freedom Park to wa nilu Osogbo ni iwọde naa yoo ti gbera sọ.

Aago meje aarọ owurọ oni ni iwọde naa yoo bẹrẹ.

"Ẹ tete fopin si isoro to n ba araalu finra lẹka ọrọ aje"

Atẹjade naa salaye pe ohun ti iwọde ọhun yoo da le lori ni isẹ ati osi to n peleke si lorilẹede Naijiria.

Lara awọn koko to wa ninu atẹjade ti ajọ OCSC naa n pin kiri lori ayelujara lo ni “Aarẹ Bola Tinubu, jẹ ki awọn mẹkunnu mi.”

Bakan naa ni wọn tun kọ sita pe “ Ẹ tete fopin si isoro to n ba araalu finra lẹka ọrọ aje.

Ẹ fopin si ebi ati bi owo igbeaye ọmọniyan se lọ soke ni Naijiria.”

Bẹẹ ba gbagbe, irufẹ iwọde to n tako ọrọ aje to dagun yii ati ọwọngogo ounjẹ to gbode lorilẹede yii ti kọkọ waye saaju lawọn ilu bii Ibadan, Kano ati Kogi.