Olùsọ́ tó ṣe àpérò àyájọ́ olólùfẹ́ léti òkun l'Eko, bá omi lọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/CCC Prophetic Ministry
Olusọ aguntan kan to fi ilu Eko ṣe ibugbe, Oriyomi Remilekun ni omi gbe lọ lasiko apero ayajọ ololufẹ to ṣe pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni eti okun ni agbegbe Ajah nipinlẹ Eko.
Oloogbe naa lo lewaju awọn ọdọ ile ijọsin Celestial Church of Christ, ti ẹka Gbagada lọ si eti okun Avista lọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ọdun 2024.
Oloogbe Remilekun lo di awati lasiko ti awọn akẹgbẹ rẹ n mura lati kuro nibi apero ayajọ naa lọ si ile.
Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti n wa Olusọ naa, ni wọn sawari oku rẹ ni eti okun miran ti ko jina si ibi ti apero naa ti waye.
"Ọjọ́ Aje ni wọn ri oku Olusọ ni eti okun ti ko jinna si agbegbe ti wọn ti ṣe apero ayajọ ololufẹ"
Nigba to n ba ikọ BBC News Yoruba, Philip Oluwatosin, ọkunrin kan to ti kọkọ gbe aworan Oluso sita sori opo Facebook rẹ pe awọn n wa a, fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni ile ijọsin kan naa ni awọn jọ wa.
“Nigba ti a gbọ pe wọn n wa Olusọ, ni a wa naa gbe ikede naa sori ayelujara pe ki awọn eeyan ti wa naa ba wa gbiyanju lati wa.
“Nigba to di ọjọ Aje ni a ri gbọ pe wọn ti ri oku Olusọ ni eti okun ni agbegbe ibi ti wọn ti lọ ṣe apero ayajọ ololufẹ.
“ Gbogbo ẹjọ nipa ohun to sẹlẹ, lo ti wa lọdọ awọn ọlọpaa ni panti bayii.”

Oríṣun àwòrán, Facebook/CCC Prophetic Ministry
"Aago mẹsan an alẹ ti wọn gbera lati kuro ni eti okun, ni wọn ṣe akiyesi pe wọn ko ri Olusọ naa"
Ọkan lara awọn oṣojumikoro to ba Ileeṣẹ iroyin Punch sọrọ salaye pe, ijọ mimọ ti agbegbe Gbagada, lo ko ara wọn jọ pe ki wọn lọ ṣe apero ayajọ ololufẹ ni eti okun.
“Awọn mẹrindinlogun lo ko ara wọn jọ. Wọn kọkọ duro si ile itura kan to sunmọ eti okun, nibi ti wọn ti kọkọ gbafẹ, ki wọn to morile eti okun.
“Ni dede ago mẹsan an alẹ, ti wọn gbera lati kuro ni eti okun, ni wọn ṣe akiyesi pe awọn ko ri Olusọ naa, ti wọn si bẹrẹ si ni ma wa kiri.
“Nigba ti wọn beere lọwọ afẹsọna rẹ, o ni Olusọ fun oun ni foonu pe oun n pada bọ sugbọn ko pada wa.”
Awọn alaṣẹ ile igbafẹ naa fidi isẹlẹ naa mulẹ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe eti okun miiran ni wọn ti sawari oku oloogbe naa.
Ki ni Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?
Ileeṣẹ BBC News Yoruba ti kan si agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lati sọrọ lori isẹlẹ sugbọn a ko ti ri idahun gba lọwọ rẹ.
Kete ti a ba ti gbọ idahun lọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa, ni a yoo fi to yin leti.















