Davido yóò pín ₦300m káàkiri ilé ọmọ òrukàn ní Nàìjíríà

Aworan Davido

Oríṣun àwòrán, davidoofficial2

Gbajugbaja akọrin takasufe ọmọ Naijiria nii David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ti kede itọrẹ owo fawọn ile ọmọ orukan kaakiri orileede Naijiria.

Loju opo rẹ ni Twitter lo ti kede owo ọọdunrun miliọnu Naira gẹgẹ bi itọrẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ fun ti ọdun yii.

Igba akọkọ kọ ni yi ti yoo maa ṣe irufẹ itọrẹ fawọn alaini lawujọ.

Nibi eleyi to ṣe sẹyin owo to gba jọ ti awọn ololufẹ rẹ da fun lasiko ọjọ ibi rẹ lo ko jọ to si fi kun to pin fun awọn ọmọ alainiya ni Naijiria.

O ni oun yoo ṣe alaye ẹkunrẹrẹ lori bi awọn yoo ṣe pin owo naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Asiko ti Davido fẹ pin owo yi jẹ asiko ti nkan le fun ọpọ ni Naijiria.

Jakejado orileede Naijiria ni awọn araalu n kerora ebi, ọwọngogo ọja ati airiṣẹ.

Awọn to leekun lapa to si ni obi laa n sọ yi ka to wa sọ pe awọn ọmọ alainiya ti ọpọ ti gbagbe wọn lawujọ.

Davido ko ṣẹṣẹ maa pin owo bayii.

Ni oṣu Kọkanla ọdun 2021, o fi N250m tọrẹ fun ile awọn ọmọ alainiya 292 lati fi ṣami ọjọ ibi ikọkandinlọgbọn rẹ.

Ni oṣu Keje ọdun 2023, a gbọ pe o tun pin N237m fun awọn ile ọmọ alainiya 424 ni Naijiria.

Ọdun 2022 lo ṣe idasilẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ DAF ti o si ni eredi idasilẹ ajọ yi ni lati pa omije rẹ loju awọn alaini lawujọ.

Ninu awọn ogo akọrin ni ilẹ Africa ni Davido wa to si ti gba aimọye ami ẹyẹ nile ati lẹyin odi fun iṣẹ orin kikọ rẹ.