Davido: Yinka Ayefele sọ ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú olórin Davido tó fi ní kò dà bí àwọn ọ̀dọ́ olórin kan
"Davido ń tọpasẹ̀ bí àwa olórin àtijọ́ ṣe máa ń bọ̀wọ́ fáwọn àgbà olórin tó kọ wa níṣẹ́ ni"
Gbajugbaja ati ilumọọka olorin ni Naijiria, Yinka Ayefele ti sọrọ lori gbogbo ohun tawọn eeyan n sọ si igbesẹ gbajumọ ọdọ olori David Adeleke to n jẹ Davido nipa owo gọbọi to ri ko jọ fun ọjọ ibi rẹ amọ to dari si ọdọ awọn ọmọ alailobi ni Naijiria.


Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga
Yinka Ayefele jẹ́ ko di mimọ pe iwa ire yii latọwọ Davido kii ṣe akọkọ tori o ti ya oun gan lẹ́nu ri lai ṣe pe awọn ti kọkọ pade tabi ni ajọṣepọ.
"Davido ti fi itan ayeraye silẹ̀, kò tíì sí eléré tó ṣe irú ǹkan tó ṣe, àfi táa bá ṣẹ̀ máa ṣe, èèyàn mélò nínú wa ló dẹ̀ lè rí irú àǹfàní yìí tí kò ní kọ́kọ́ rántí ìyá tirẹ̀ tàbí àbúrò. Iwa ọtọọtọ lo wa ninu wa".
Yinka Ayefele ni Davido kò jọ àwọn kan nínú iṣẹ́ orin tá máa tẹ ojú ọ̀gá orin tí wọ́n kọ́kọ́ ń wò bí àwòkọ́ṣe.
“Lọjọ ti mo kọkọ maa pade Davido, lai ṣe pe a ti rira ri tabi ni ajọṣepọ kan, o kọkọ wa di mọ mi latẹyin to n ṣe Daddy mi Daddy mi, inu mi dun”.

O ni o yatọ si awọn olorin kekeke kan to jẹ pe ọla orin ti agba olorin kọ gan lo fi n jẹun amọ wọn lee yẹyẹ agba olorin yẹn ti wọn ba jọ pade.
“Davido tiẹ́ kọkọ bu ọla fun mi, o yọ mọ mi, di mọ mi to tun n pe mi ni Daddy rẹ, inu mi dun”.
Lẹyin igba akọkọ ti awọn olorin mejeji yii pade, Ayefele ni awọn tun ti pade to si n bu ọla fun oun, to n fẹ ba oun ya fọto to si jẹ pe irawọ agbaye ni Davido koda titi de Amẹrika lo ni o tun ti n sare bọ wa ki oun.

Ayefele ni iwa ire ni iwa ti Davido ni ko si si olorin to ti ṣe iru nkan to ṣe fawọn alailobi yii ri afi ti awọn ba ṣẹ maa tọọ lẹyin.

