Jumoke Oyeleke: Iya Jumoke kọ̀ láti lọ ilé tí ìjọba rẹ́ǹtì, ó ní òun ò lè padà sí ẹ̀sẹ̀ àárọ̀ lẹ́yìn ilé mè-rẹ́ẹ̀ǹtì

Àkọlé fídíò, Ilé tẹ́ẹ rò pé ìjọba Eko fún wa, wọ́n rẹ́ǹtì rẹ̀ ni, a kò tíì rí N1Miliọ̀nù kankan di àsìkò yìí - Iya Jumoke

Iya to bi Jumoke Oyeleke to wa niwaju ṣọọ́bu iya rẹ ti ibọn Ọlọpaa ba lọjọ iwọde EndSARS lọdun 2020 nipinlẹ Eko ti ṣalaye iru ile gaan ti ijọba ipinle Eko ni ki wọn maa gbe.

Ko han pe iya Jumoke n binu si ohun ti ijọba ṣe fun wọn yii amọ alaye rẹ ni wipe oun atawọn ọmọ oun ko le pada maa lọ wa ile ti wọn yoo rẹnti lẹyi ti owo ile ba ti tan nibi ti ijọba ni ki wọn lọ maa gbe.

LTV

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga

Ọpọ eniyan lo ro pe ile ọfẹ ati ẹbun owo ọfẹ ni ijọba Eko bu fun idile yii ni nkan bii ọsẹ diẹ sẹyin amọ nigba ti BBc Yoruba de ile iya Jumoke, ọtọ ni alaye ti a ba.

" Wọn o sọ fun emi naa pe awọn n bọ, wọn kan pe mi pe ki n wa ti mi o si mọ ibi ti a fẹ lọ".

O ni wọn kọkọ wa si ile oni pako ti awọn ṣi n gbe lati ya fọto ki wọn to mu oun lọ si ile ringindin kan ni Ikorodu l'Eko pe asiko ọdun meji lawọn san owo fun awọn lati gbe nibẹ.

Ile Iya Jumoke

Oríṣun àwòrán, LTV

"Owo ti wọn ni wọn fun wa, miliọnu kan, a o tii ri nkankan, koda ko tilẹ ran nkankan ninu owo ileewe awọn ọmọ ati owo ọja".

Iya Jumoke ni pipada wa sibi ti awn n gbe lọwọ lọwọ ko lee ṣeeṣe tori ẹlomiran yoo ti ko sibẹ to si jẹ pe ile me-rẹnti ni ijọba gba.

Ile ti ijọba rẹnti

Oríṣun àwòrán, LTV

"Nkan ti mo fẹ ni ile ti a ko ni nilo lati maa san owo rẹnti mọ ati pe ki Ọlọrun ran wọn lọwọ lati ri nkan ti wọn fẹ fa yọ ninu ẹjọ iku ọmọ mi ti wọn n da".