BBC Africa Eye: Ìwádìí tú àṣírí bí ààrẹ orílẹ̀-èdè DR Congo ṣé lú owó aráàlú ní pónpó
Ninu iwadii ti ẹka to n tọ pinpin iṣẹlẹ lawujọ BBC Africa Eye ṣe yi, ọpọ ohun to ṣẹlẹ nipa owo ti aarẹ tẹlẹ lorileede DR Congo Joseph Kabila ko pamọ lo lu sita.
Iwadii ọhun ṣafihan bi wọn ṣe fi ọna alumọkọrọyi ko miliọnu dọla pamọ si akoto owo awọn ileeṣẹ to wa ni DR Congo to jẹ ti mọlẹbi ati awọn alajọṣepọ aarẹ yi.
Bẹẹ naa si ni iwadii yi tan imọlẹ si awọn idunadura kan ti ko tọna ti a ri pe wọn ṣe lati ileeṣẹ aarẹ lasiko ti Kabila wa ni ori alefaa.
Iwadii yi taa jọ ṣepọ pẹlu awọn ile ifowopamọ kan tu ọpọ aṣiri to ṣe pe afi ki eeyan wo fọnran fidio yi ko to le mọ nkan taa n sọ.