Africa Eye Migrants: Àwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn sálọ orílẹ̀èdè míì ṣe fídíò ráńṣẹ́ sílé
Lọdọọdun ni ẹgbẹgbẹrun awọn eeyan lati orilẹede Ethiopia n fi ẹsẹ rin sa kuro niluu ara wọn lọ si orilẹede Saudi.
O maa n to irin kilomita ẹgbẹrun meji ti wọn maa n rin lati Ethiopia lọ si Saudi Arabia.
Ninu ki wọn gbiyanju lati gba ọna oju omi okun pupa, ki wọn maa pọn apata atawọn oke nla nla, inu igbo aginju ti awọn to wa nilu ilu ko lee ri wọn tabi awọn ọna oju ogun.
"Pupọ ninu wa ko la a ja, a ni lati sin wọn sinu iyẹpẹ. Lati igba ti mo ti pada de ni mo ti n sọ fun gbogbo eeyan pe ki wọn ma wa gba ọna yii salọ mọ".
BBC Yoruba ba lara awọn to n salọ yii rinrinajo diẹ nibi ti wọn ti n ṣalaye bi iku ṣe maa n he wọn lawọn ọna ẹburu yii, ọtọ ni bi wọn ṣe n koju awọn adigunjale iṣẹ ati ebi ninu oju ọjọ to gbona tun gbona janjan pẹlu oorun to to onipele aadọta (50 degree).
Eyi ko jẹ ko ya eeyan lẹnu pe wọn n ku lọna tabi ki ọpọlọpọ wọn pada di atọrọjẹ loju popo.
Wọn sọ awọn aṣiri to di imọran fun awọn mii to ba n gbiyanju lati sa kuro lorilẹede wọn lati wo ohun toju wọn n ri lawọn ọna ẹburu ti wọn n gba.

