Tope Alabi: Ẹni tó kọ orin "Oniduro Mi E se o" fèsì

Aworan Tope Alabi, Tolu Adelegan

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi, Tolu Adelegan

Olorin to kọ "Oniduro Mi ẹ ṣe o" eyi to jẹ orin to ti gba ẹnu ọpọlọpọ kaakiri lati fi mọ riri ore Ọlọrun, Tolu Adelegan ti fesi lori fidio ti gbajugbaja Olorin Tope Alabi ti ni orin to kọ ko pọn Ọlọrun le.

Ninu fidio kan nibi ti Ajihinrere Tope Alabi ti n ṣe iṣẹ iranṣẹ orin lọwọ ninu ijọ nla kan lo ti kẹnu bọ ọrọ to ni Ọlọrun ju keeyan dede maa pe ni Oniduro lọ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Oniduro mi

Kí ló fa gbas-gbos láàrin Tope Alabi àti Olórin tó kọ "Oniduro Mi e se"?

"Ọlọrun kọja Oniduro sir, emi naa fẹran orin yẹn amọ ọjọ ti mo fẹ kọ ọ ẹmi mimọ ni gbẹnu ẹ sọhun".

Tope ni kii ṣe pe oun n sọ pe orin kan o dara amọ o ni iru aṣaro ti eeyan maa n ṣe pẹlu ẹmi mimọ to ba ti fun eeyan ni imisi.

"To ba jẹ bi ẹmi mimọ ṣe n gbe e wa ni eeyan n sọ ni, onikaluku a kan maa sọ isọkusọ ni, o ni lati tun un da ro daadaa koo to gbe orin yẹn jade".

Olorin Tope Alabi ni oun funra oun ti kọ orin ri ti oun si tun yi i pada.

O ni "Jesu ko duro fun wa, o ku fun wa ni tori naa o kọja pe eeyan n duro fun eeyan, ẹni to lọ sori agbelebu lati ku, wọn na a lẹgba, a tut si i lara, a gun un lọkọ lẹgbẹ, a fiya jẹ ẹ, a pe e ni ẹlẹ́ṣẹ ti kii ṣe, ẹ wa sọ pe oniduro ni... Ẹ ma maa fi nkan ti ko dara we Ọlọrun, Ọlọrun pọ ju bẹẹ lọ".

Àkọlé fídíò, 'Walahi kìí ṣe irọ́ pé Fulani ń dá àwọn èèyàn lọ́nà nílẹ̀ Yorùbá, ìrírí mi rèé'
Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Tope Alabi ṣe afiwe ẹni ti baba rẹ ku ti awọn kan si n fọwọ sọya lati ṣe oniduro gẹgẹ bii baba amọ to kan jẹ ẹta lasan.

Nigba to di owurọ oni ọjọ Aiku, ọjọ kẹtala oṣu kẹfa ni Arabinrin Tolu Adelegan Ayonitemi naa fi atẹjade si oju opo rẹ pe oun pinu lati ma sọrọ amọ o dupẹ lọwọ gbogbo awn eeyan to ti n fesi lori ọrọ naa lati ṣe atilẹyin fun un.

"Si ogo Ọlọrun, gẹgẹ bi if Ọlọrun ni mo fi maa n kọ awọn orin mi ati nipasẹ ọrọ Ọlọrun, iyẹ Bibeli mi, ẹlomiran le maa gba imisi lọdọ awọn ọlọrun kekeke o tabi nibomiran amọ Jesu Krisiti nikan lemi gbojule".

O ṣalaye pe oun o ni oke mii lẹyin Ọlọrun toripe Jesu ni igbẹkẹle, baba, oludari, oloore, ireti oun kii ṣe Ọlọrun miran.

Ọdun 2014 ni Adelegan ni Ọlrun fun oun ni imisi orin naa eyi to jẹ orin ikeji to kọ ninu awo orin "Ikede Ẹẹkeji".

O fi atẹjade sita pe laipẹ, ifọrọwanilẹnuwo yoo jade nipa orin naa ọkan ninu eyi ti BBC Yoruba n ṣewadii lati gbe jade laarin ọjọ diẹ.

Ẹwẹ, awọn eeyan ti n fi ero, iwoye ati itumọ tiwọn sita lori ọrọ yii ti olorin naa si n fi atẹjade idaniloju rẹ sita pe oun ko gba orin yii nilana okunkun tabi ọna ti ko mọ ju ọdọ ẹmi mimọ lọ.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò