Tope Alabi: Ìlúmọ̀ọ́ká akọrin ẹ̀mi náà ní ìdílé kòlà-kòṣagbe l'òun ti wá

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Tope Alabi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi to pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2019 sọ fun BBC Yoruba pe, idile kola-kosagbe ni oun ti wa.

Nigba to sọ nipa igbesi aye rẹ, Tọpẹ Alabi ṣalaye pe ọmọ ọdun meje si ni oun wa, ti wọn ti sọ asọtẹlẹ fun awọn obi oun pe, oun yoo sisẹ sin Ọlọrun.

O ni ọmọ ọdun mẹjọ ni oun wa bakan naa ti oun fi darapọ mọ ẹgbẹ osere Adẹrupọkọ nilu Ibadan lati maa se ere tiata, ki oun to tun lọ sọdọ oloogbe Isọla Ogunsọla

Tọpẹ Alabi to ni oun n kọ ile iwe kan lọwọ fun iṣẹ orin, wa gba awọn eeyan nimọran lati mase lo ẹbun ẹlẹbun, tori o dara ki onikaluku mọ ẹbun ti Ọlọrun ba fun.

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi

Nigba to n sọrọ lori awọn ipenija to n koju rẹ, Tọpẹ Alabi ni ọrọ alufansa ti awọn eeyan kan maa n sọ nipa awọn olorin ni kii fun awọn ni iwuri, to si laa pe, oun si n kọ orin nipa ijọba ọrun, tori ko si ohunkohun to lee gba orin ijọba ọrun ni ọwọ oun.

O fikun pe, ọwọ oun di pupọ ni ko jẹ ki oun maa kọ orin fun awọn elere tiata mọ bi o tilẹ jẹ pe, owo ti oun maa n gba fun orin kikọ pọ lọwọ wọn, sibẹ, wọn si maa n fi orin inu ere lọ oun.

Tọpẹ ni ojoojumọ ni oun maa n gba imisi orin lati ọdọ Ọlọrun, to ba si jẹ pe bẹẹ ni oun se n se awo orin jade ni, ilẹ yoo ti kun.

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi

O tun salaye pe, oun ko mọ ohunkohun nipa boya awọn alawo lo sin oku adari ijọ to n lọ tẹlẹ nilu Eko, Oloogbe, Oluṣọagutan Iretiọla Ajanaku.

Lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba, Tọpẹ Alabi sọ pe, Ọlọrun ti sọ fun oun tẹlẹ ki Ajanaku to ku pe, oun ko gbọdọ lọ si ile ijọsin rẹ mọ, bẹẹ si ni orilẹede Amẹrika ni oun wa nigba ti Ajanaku dagbere faye ati igba ti wọn sin in.

Tọpẹ salaye pe ko si ọ̀rọ̀ ifẹ ikọkọ laarin oun ati ojisẹ Oluwa naa, gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti n sọ kiri, pẹlu afikun pe ti iru eyi ba wa, Ọlọrun ni yoo se idajọ laarin awọn.

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Tope Alabi

O fikun pe o to ọdun meji ti oun ko ti lọ sile ijọsin Ajanaku mọ, ki ojisẹ Ọlọrun naa to jade laye pẹlu afikun pe, gbogbo aye gan lo mọ pe aarin oun ati Ajanaku ko gun mọ ki onitọun to jade laye.