Saudi Arabia: Kíni ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Imaam ni Mecca?

Oríṣun àwòrán, @Haramainsharifain
Opọlọpọ awuyewuye lo ti n waye ti ọpọ n beere idi ti awọn ọmọ ogun ilẹ fi n ṣọ awọn aafa to n ṣaaju irun ni Mẹka ati Medina.
Lataari eyi ni awọn alaṣẹ mọṣalaṣi mejeeeji fi sọrọ loju opo facebook wọn ti wọn si ṣalaye ni kikun ohun to ṣokunfa igbesẹ yii.
Awọn eniyan n beere pe ṣe o yẹ kori bẹẹ, koda lasiko ti awọn aafa yii ba n pe irun ninu mọṣalaṣi.
Wọn ni awọn ko deede gbe igbese yii bikoṣe lati pese eto aabo to peye fawọn Imaam naa ni.
- Ìkúnlẹ̀ àbiyamọ o! Saudi fẹ́ gbẹ̀mí 23 ọmọ Nàìjíríà tó gbé òògùn olóró
- Ìkọlù ibùdó epo rọ̀bì Saudi Arabia yóò kóbá jíjẹ-mímu àwọn èèyàn rẹ̀ - Buhari
- Ìjọ̀ba Saudi ti tú Zainab tí wọ́n fẹ̀sùn òògùn olóró kàn sílẹ̀
- Ìjọba Borno bẹ àwọn ọgbọ̀n Alfa Saudi lọ́wẹ̀ láti rẹ́yìn Boko Haram
- Wo àwòdamiẹnu àwòrán Mọ́ṣáláṣí Ànọ́bì ní Medina!
Awọn alaṣẹ naa mẹnuba awọn koko wọnyii pe:
Iṣẹlẹ kan ṣẹlẹ lọdun 2015 nigba ti ọkunrin kan ṣaa deede n pariwo le aafa Sheik Ali Al Hadaify lori lasiko to n pe irun lọwọ ninu mọṣalaṣi nla naa.

Oríṣun àwòrán, @Haramain
Yatọ si iṣẹlẹ tọdun 2015, Lọdun 2011 ni ọkunrin kan tun deede yinbọn fun Sheik Juhany ti ọkunrin naa si bẹrẹ si ni pariwo ninu mọṣalaṣi mimọ naa.
Lasiko ti Aafa Juhany n pe irun Azahar ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ti ọkunrin naa si ja gbohungbohun gba lọwọ Aafa nla naa.
Iṣẹlẹ miran ti awọn alaṣẹ mọṣalaṣi yii mẹnuba ni ti ọkunrin kan to fẹ gun Aafa Sheik Sudais lọbẹ nigba ti o n pe irun ni mọṣalaṣi Ka'bah ni Mecca.

Oríṣun àwòrán, @Haramain
Awọn alaṣẹ mọṣalaṣi nlanla mejeeji ni igbesẹ yii di dandan lasiko yii lati pese aabo fawọn imaamu wọn nitori ọpọ eeyan lo ti da wọn mọ lagbaye.
Wọn ni ẹrọ ayelujara ti jẹ ki ọpọ eeyan da awọn aafa wọnyii mọ ni eyi to jẹ ki awọn kuku ni kawọn ọmọ ogun ilẹ maa ṣọ wọn koda, ti wọn ba n pe irun lọwọ ninu mọṣalaṣi.

Oríṣun àwòrán, @Haramain
Awọn alaṣẹ Ka'bah ni ọpọ ero lo n wa si Mecca ati Medinah fun idi loriṣiiriṣii ni eyi to fi di dandan lati daabo bo awọn aafa Olorun yii lọwọ ikọlu awọn ero.
Wọn ni ọpọ ero lo maa n fẹ fọwọ kan awọn ẹni mimọ yii tabi ki wọn fẹ mu nkan lara wọn lati fihan pe awọn pade wọn ni mọṣalaṣi nla.

Oríṣun àwòrán, @Haramain
Awọn alaṣẹ mọṣalṣi mejeeji ṣalaye pe, lẹyin ti awọn Aafa nla yii ba pari irun ti aabo wọn ti daju ni awọn ọmọ ogun ilẹ to n ṣọ wọn naa a ṣẹṣẹ wa kirun ti wọn lẹyin tawọn ero ba ti pari.















