Maina Arrest- DSS ti mú Maina àti ọmọ rẹ ní ile Itura kan l'Abuja

Ọwọ ti tẹ Maina àti ọmọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, EFCC page

Àkọlé àwòrán, Abdulrasheed Maina Alaga ana fun eka owo ifẹyinti

Ajọ Ọlọpaa abẹnu ti a mọ si DSS ti fi panpẹ ọba mu alaga ana fun eto owo ifẹyinti ni Naijiria, Abdulrasheed Maina.

Ninu ọrọ ti alukoro ajọ naa, Peter Afunayan, fi lede ni ọjọru ọsẹ yii, sọ wi pe lootọ ni ọwọ ṣikun ajọ naa ti tẹ ẹ.

Ajọ naa ni ọwọ wọn tẹ Maina ati ọmọ rẹ ọkunrin kan, Faisal, ẹni ogun ọdun.

Ọwọ tẹ wọn ni ile itura kan ni, Pennysylvania Avenue, Utako, Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ni ọgbọn ọjọ Oṣu to kọja.

Ṣe ṣaaju ni wọn ti fi ẹsun kan an wi pe owo to to bii biliọnu meji lo poora sọwọ Maina ni ọfiisi Olori awọn Oṣiṣẹ Ijọba apapọ.

Maina ni o jẹ adari ni ẹka ti o n ri si bi igbokegbodo owo ifẹyinti ti n lọ ni Naijiria fun bii ọdun meta.

Lọdun 2015 ni ajọ Ọlọpaa ọtẹlẹmuye ti kọkọ fi ẹsun ikowojẹ oni biliọnu meji naira kan an.

Maina ṣe alaga naa lati ọdun 2010 si ọdun 2013. O tun jẹ alakoso agba fun awọn Aṣọbode pẹlu awọn ti o n boju to ọgba ẹwọn.

Ni ọdun 2013 ni awọn Aṣofin ti ni ki wọn fi panpẹ ọba gbe Maina ṣugbọn ti o fẹse fẹ ẹ lo si orilẹ-ede Saudi Arabia.

Nigba ti o di ọdun 2015, ni ajọ ti o n risi iṣowo ilu baṣubaṣu EFCC, ti pe fun wiwa Maina lawari ti obinrin n wa nkan ọbẹ ri.

Ni ọdun 2016, ni Maina kede pe, awọn Aṣofin ti da oun lare ki oun si maa lọ ni alaafia.

Àkọlé fídíò, Nigeria Independence Day: Wo ìlérí tí àwọn ènìyàn ṣe