Afe Babalola: Ìpínlẹ̀ Ekiti nìkan ni kò ní ìdàgbàsókè ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Oludasilẹ ile iwe giga Afẹ Babalola ni ilu Ado Ekiti, Oloye Afe Babalọla ti sọ wi pe ipinlẹ Ekiti ko ni idagbasoke kankan nitori ijọba apapọ ti kọ wọn silẹ.
Babalola sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Ekiti lẹyin ti afara to so ilu Ado Ekiti pọ mọ ile iwe giga mejeeji to wa ni ipinlẹ naa ti wo lulẹ, to si la ẹmi eniyan kan lọ.
Agba ọjẹ ninu imọ ofin naa ni ojuti ni ohun ti o sẹlẹ naa, ti o si pe akiyesi ijọba si gbogbo awọn ohun amuludun to ti dẹnu kọlẹ ni ipinlẹ naa.
Babalola ni oke afara to wo lulẹ naa da sun kẹrẹ ọkọ silẹ fun awọn oṣiṣẹ lati Ọjo Aje titi di Ọjọru ti o ba awọn akọroyin sọrọ naa.
Oludasilẹ Ile Iwe Giga Afe Babalola naa wa rọ ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ lati wa wọrọkọ fi sada lori ipo ti awọn ohun ini ipinlẹ naa wa, ki o le tẹsiwaju.









