Rwanda: Awakọ̀ 700 kò sí panpẹ òfin, 191 ṣẹwọn lórí ẹsùn wiwakọ lẹyìn tí wọ́n mọtí

Oríṣun àwòrán, Rwanda Police
Laarin ọsẹ meji pere ni ọwọ ti tẹ awakọ ẹẹdẹgbẹrin ni Rwanda.
Awọn ọlọpaa lorile-ede Rwanda ti n tẹra mọ mimu awọn awakọ ti wọn fẹsun kan pe wọn wako lẹyin ti wọn ti muti.
Ni nnkan bi ọsẹ meji loṣu Kẹsan nikan,o kere tan wọn ti mu awakọ to le ni ẹẹdẹgbẹrin ti mọkanlelaadọwa ninu wọn si ti ṣẹwọn lori ẹsun yi.
Ṣugbọn pupọ ninu awọn ti o ko si panpẹ ofin yi ni wọn ko tẹle ofin bo ti ṣe tọ lati mu awọn.
Wọn ni Yatọ si owo itanran aadọjọ dọla ti awọn ẹlẹsẹ yoo san, awọn ti o ba jẹbi ẹsun a maa sun ahamọ bii ọjọ marun un lai ṣe pe ile ẹjọ paṣẹ bẹẹ.
Awọn ọlọpaa Rwanda ni awọn ko dakẹ lori idanilẹkọọ fawọn eeyan nipa aburu wiwakọ lẹyin ti eeyan ba mu ọti tan.
Arakunrin kan to ba BBC sọrọ to si ni oun ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ pe awọn ọlọpaa ko ni irinṣẹ kankan lati jẹri pe lootọ leeyan muti.
Ofin ilẹ Rwanda sọ pe ida 0.08 BAC (blood alcohol concentration) ni igbalaaye rẹ wa fawọn awakọ amọ awọn eeyan ni ọlọpaa ko ni irinṣẹ to peye lati fi mọ aridaju iye ọti ti eeyan ba mu.














