Oníkẹ̀kẹ̀ NAPEP: Àwọn ọlọ́pàá ń gba owó kòtọ́ lọ́wọ́ wa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onikẹkẹ NAPEP ni ilu Maiduguri, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Borno, ya bo awọn opopona marosẹ to wa nilu naa ni owurọ ọjọ aje lati fi ẹhonu han lori ohun ti wọn pe ni "bi ọlọpa ṣe n fi awọn jẹun"
Awọn opopona to lorukọ bii opopona Baga, opopona Maiduguri si Damaturu, ati agbegbe Lagos street, ni wọn fi kẹkẹ wọn di pa lagbegbe ileeṣẹ awọn ọlọpaa nibẹ.
"O to gẹẹ, gbogbo igba lawọn ọlọpaa fi n gba owo lọwọ wa lai ni idi kan pato. Nigba miran, wọn a gba owo to to N1,500 tabi N2,500 lọwọ wa."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọpọ awọn olugbe ilu Maiduguri ni wọn ni lati fi ẹsẹ rin lọ si ibi iṣẹ wọn.
Awọn eeyan miran ti wọn ni ọkọ ara wọn ni wọn ni lati yago fun awọn opopona ti awọn onikẹkẹ NAPEP naa ti gbajọba.
Awọn ọlọpaa ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.









