Ìjọba Èkó: À fẹ́ kí asaajú ẹ̀sìn yí èrò aráàlú padà lórí ìwà àìtọ́, ìjẹkújẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede ipinnu rẹ lati gbe isẹ le awọn asaaju ẹsin, to fi mọ awọn pasitọ ati imaamu lọwọ, ti yoo si maa san owo osu fun wọn.
Igbesẹ yii lo ni yoo mu ki wọn lee seto itaniji fawọn araalu lati kẹyin si iwa ijẹkujẹ ati awọn iwa aitọ mii to kun awujọ wa dẹnu.
Kọmisana fọrọ mọlẹbi ni ipinlẹ Eko, Abdulhakeem Abdulateef lo sisọ loju ọrọ yii lasiko eto ilanilọyẹ kan fawọn imaamu atawọn ọmọwe jake-jado ipinlẹ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kọmisana naa tun fikun pe ijọba ipinlẹ Eko yoo tubọ maa fara kinra pẹlu awọn asaaju ẹsin naa, to si tun rọ wọn lati jẹ awokọse rere, ki wọn si tun maa sewuri fawọn ọmọlẹyin wọn lati takete si iwa ijẹkujẹ.
"A setan lati gbe isẹ le ọpọ wọn lọwọ nipa pipese owo osu fun wọn, ki wọn lee maa se atilẹyin fun ijọba lati fun awọn araalu ni ilanilọyẹ si iwa rere. A gbagbọ pe eeyan Ọlọrun ni awọn Imaamu ati Pasitọ, Nitori naa la se nilo iranlọwọ yin lati sewuri fun iwa ọ́mọluabi lawujọ, paapa nidi iwa ijiyin isẹ iriju ẹni ati titako iwa ibajẹ."
Abdulahateef fikun pe Ọlọrun yoo beere lọwọ gbogbo wa lati jiyin isẹ wa taa gbe ile aye se ni ọjọ idajọ. Nitori naa lo se yẹ ki awọn asaaju ẹsin yii lewaju wa si ọna to tọ nitori pe awokọse wa ni wọn.

Oríṣun àwòrán, @Governor Ambode
Sugbọn ọpọ eeyan lo ti n fi ero wọn han oju awọn opo ikansira ẹni lori itakun agbaye, bi awọn eeyan kan se tako igbesẹ yii si lawọn mii fara mọ.
Loju opo Twitter, @AASCHE_KAATZE, o ni iroyin to dara ni eyi, ti oun si lero pe wọn yoo maa san owo osu fawọn Onisango naa, ti gbogbo ẹni ti ko nisẹ lọwọ yoo si maa di ojisẹ Ọlọrun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post













