Minisita: Ileeṣẹ apòògùn 20 lo jẹbi síse òògùn ikọ́ Codeine

oògùn ikọ́ olómi codeine

Oríṣun àwòrán, Frankieleon

Àkọlé àwòrán, Àṣìlò èròjà codeine àti awọn òògùn mi i maa n ṣe àkóbá fún ara

Ọwọ ileeṣẹ eto ilera ni Naijiria ti tẹ igo oogun ikọ olomi to n lọ si bi i miliọnu mẹta (2, 405,724) to ni eroja codeine ninu.

Eyi waye lẹyin ayẹwo atigbadegba kan ti ajọ to n mojuto ipese ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, ṣe.

Igbesẹ naa gẹgẹ bi minisita fun eto ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewọle ṣe sọ, jẹ ọna lati ti tubọ fi ipinnu ijọba apapọ lati f'opin si aṣilo oogun ikọ olomi to ni codeine ninu, ati awọn oogun mi i l'orilẹede Naijiria han.

Àkọlé fídíò, Fídíò òògùn ikọ́ Codeine: Àpọ̀jù rẹ̀ ń ya ọ̀dọ́ ní wèrè

Iwe iroyin Nigerian Tribune jabọ pe, Ọjọgbọn Adewọle sọ eyi di mimọ nilu Abuja lasiko to n tẹwọ gba abọ iwadi igbimọ ti ileeṣẹ eto ilera gbe kalẹ lati mojuto aṣilo oogun ikọ olomi to ni eroja codeine ninu.

Abọ iwadi naa fihan pe ogún ninu mẹtalelogun awọn ileeṣẹ to n ṣe oogun oyinbo ti wọn ṣe ayẹwo si lo jẹbi ọrọ naa.

Ati pe ibudo ti awọn ileeṣẹ naa n ko awọn ọja wọn si ni ọwọ ti tẹ awọn oogun ikọ naa.