Yoruba Film: À ṣé ara mi ni isó tí ń rùn, tí èmi náà ń ṣépè fún ẹni tí Jamiu ń sọ- Mama Ereko

A ṣe ara mi ni isó tí n rùn, tí ẹmi náà ṣépè fún ẹni ti Jamiu ń sọ- Mama Ereko
Àkọlé àwòrán, Mama Ereko àti Jamiu Azeez
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Etí tó bá àlọ, ó di dandan kó gbọ́ àbọ̀, lórí ọ̀rọ̀ àwọn òṣèré tíátà tó gba orí ayélujára kan láti bi ọja mẹ́ta sẹyin.

BBC Yoruba kan sí Morenike Alausa Sulaimon, Mama Ereko lati mọ iha to kọ si ọrọ Jamiu ati igbesẹ to ti gbe.

Tí ẹ o bá gbàgbé, ìbèérè tó gba orí ayélujára kan ni pé Tani àgbàlagbà tó fẹ́ fi ọwọ́ ọla gbá gbá Azeez lójú.

Lóru àná ni fọ́ran míràn tún jẹyọ lọjú òpó instagram Morenike Alausa Sulaiman tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí mama Ereko náà tó fi gbé èrò tirẹ̀ síta lórí ọ̀rọ̀ náà.

Mama Ereko sọrọ nínú fọ́nran onísẹ́jú méje dín díẹ̀ níbi tó ti sàlàyé ǹkan ti irú ìgbésẹ̀ tí òun gbé nígbà ti òun rí fọ́ran ti jámiu ṣe lórí pé àwọn jí iṣẹ́ òun.

Àkọlé fídíò, Wo ìgbé àyé ìyá àti ọmọbìnrin tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun

Ipa wo ni màmá Ereko kó nínú ọ̀rọ̀ náà?

Nínú fọ́ran náà mámá sàlàyé pé ni kété tí òun gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ni òun bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣépè ńlá-ńla fún gbogbo ẹni tó dán irú rẹ̀ wò láì mọ̀ pé òun gan ni Jamiu Azeez ń sọ.

"Aṣe èmi ni Jamiu ń báwi pé mo lo ìtàn òun".

"Lọ́ọ̀tọ́ ni mo fẹ́ lo àuntí Ramọta láti ṣe fíìmù, Odunlade sì ni ó fún mí ni déètì ọjọkejidinlogun oṣù kéji ọdun 2021 lati inú oṣù kejìlá, gẹ́gẹ́ bi àsìkò tí yóò ráyè.

Mí o tii wọ location,Okiki Afolayan ni adarí eré mi òun kan náà lo dari eré ọkọ Ramọ tí Jamiu Azeez ṣe.

Okiki ati Afeez Eniola lo ni kí a má bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ọdún, eré Ọlọ́ba ni tèmi, ìyàwó sì ni Azeez ṣe fún Ramọ".

Mama Ereko fi kun un o ni, "nígbà tí èmi gan gbọ́, ara ta mí pé taló ṣe irú èyí fún ọmọ yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣépè nínú ibí tí àwọn ènìyàn tí n sọ̀rọ̀ lábẹ́ fọ́nrán tirẹ̀, mó tún lọ ba á lẹ́yìn, mo tùú nínú pé kó má sunkún mọ́, mó tún 'se èpè míràn fún àwọn tó ṣe irú rẹ̀, láì mọ̀ pé èmi ló n báwí".

Mama Ereko ni awọn eniyan bẹ̀rẹ̀ si ni pe oun lọ́tùn lósì pé wọ́n sọ pé ìyá àgbà kan ni wọ́n lò wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí, toun sì pe àbúrò Ramọ pé lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbi eré Azeez, ibi ere míràn wo ni wọ́n tún lọ? ó ni kò sí.

"Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́ ni ọgá Latin tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ pè mi láti sọ ojú abẹ níkòó pé emi gàn ni Jamiu sọ pé ó ṣe irú iṣẹ́ náà.

Mó wá ní èmi ló n bá wí láti àárọ̀ tí gbogbo ènìyàn ń ṣepè lé mi. Ilẹ̀ Imọ̀ ni àkọlé eré ti tèmi, Ọkọ Ramọ ni ti Jamiu". Mama Ereko ni ibo lo gba jọ ara wọn?

"Mo ni ẹlẹri tó pọ̀, Ogogo wà nínú iṣẹ́ mi, ìwé mi wà lọ́wọ́ ẹ, Wumi Toriola wa níbẹ̀, kí gbogbo ènìyàn pé àwọn wọ̀nyìí láti bèrè bóyá mo tí ya iṣẹ́, Pasuma àti àwọn eléré jànkan jànkan ló wà nibẹ̀".

"Mama Ereko ṣẹ́ ọ̀pọ̀ èpè lórí pé tí òun bá mọ̀ nípa rẹ̀"

Kíni ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ́ Tampan gbé?

Lówúrọ̀ òní bákan náà ni BBC Yoruba bá mama Ereko sọ̀rọ̀ ló sàlàyé pé ẹgbẹ́ ti pé àwọn méjèèjì papọ ati pé ọ̀rọ̀ náà ti ní ìyànjú.

Mama Ereko ni ọ̀rọ̀ náà kan dun òun ni nítorí òun kò mọ̀ pé ara òun ni isó tí ń rùn.

Kò sí ẹni ti yóò ṣe ti kò ni dún, ara ló ta mi bi gbogbo ènìyàn ṣe n ṣepe lé mi lórí láti ààrọ̀ tó fi di alẹ́."

"Gbogbo èpè yẹn ko ni ṣe lé ẹnikẹni lórí". Mama ni awn mejeeji ti jọ re epep naa kuro lori ara awọn.

Ẹ̀wẹ̀ ni nínú fọ́ràn ti olórí ẹgbẹ́ Tampan fi síta lówùrọ̀ òní ni Baba Latin tó jẹ́ olórí ẹgbẹ náà sàlàyé pé, ọ̀rọ̀ náà ti tan nílẹ̀.

O fa Jamiu Azeez sẹgbẹ̀ pẹ̀lú tó sì gbà á láàyè láti ṣàlàyé pé èdè àìyedè lásán ni ǹkan tó sẹ́lẹ̀, àti pé àwọn ti yánjú ọ̀rọ̀ náà.

Jamiu tọrọ aforíjì lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tó si ni kí wọ́n máa retí Oko Ramo.

" Èdè àiyedè lásàn ni ǹkan tó ṣẹlẹ, mó sì ti bẹ Màmá kó má bínu, wọ́n sì ti ṣàdúrà fún mi".

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Jamiu Afeez faraya sáwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lóríi sinimá rẹ̀ pẹ̀lú Aunty Ramota

Oṣere Jamiu Afeez

Oríṣun àwòrán, Jamiu Afeez

Gbajugbaja ọdọkunrin oṣere fiimu Yoruba, Jamiu Afeez ti figbe ta pe awọn kan n pa oun lẹkun ojoojumọ lori iṣẹ ti oun fi oogun oun ṣe.

Amọ taa gan ni akẹgbẹ rẹ to n bawi?

Jamiu sọrọ o kunlẹ ninu atẹjade rẹ ṣugbọn ko darukọ ẹni kankan, atanpako lo kan fi n juwe ọọkan.

Ṣe ni oju Jamiu kun rọ́rọ́ tẹ o mọ pe eeyan to ti sunkun yo leleyii fun ọjọ melo kan sẹyin gẹgẹ bi oun funrarẹ ṣe sọ ọ.

Àkọlé fídíò, Amope Onibata: Kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ló gbà kí ń ṣe bàtà fún àwọn

"Mo ti sunkun, mo ti sunkun oju mi ti wu, mo ti bi ara mi ni ọpọ ibeere."

Kilode ti oriire ẹda maa n bi ẹda ẹgbẹ rẹ ninu?".

"Kí lo de to jẹ pe ẹda maa n fẹ ki ọmọ ẹda ṣe iṣẹ ko ma ri ere jẹ?".

"Kí lo dé táa maa n fẹ ka nibi ti a ko gbin si?"

Awọn ibeere yii ni Jamiu Afeez ko kalẹ ti ko ye e to si fẹ mọ idahun rẹ. O ni oun kii ṣe ọmọde ninu iṣẹ tiata yii, o ti pẹ gan toun ti bẹrẹ toun si ti kopa ninu ọpọ ere.

Jamiu ni oun o le ka iye fiimu toun funra oun ti gbe jade amọ eyi to ṣẹṣẹ ṣe jade laipẹ yii gangan ni o ni awọn kan n fa were lẹsẹ lori rẹ o.

Pẹlu bi fiimu naa ṣe pariwo to to gba gbogbo ori ayelujara kan lai tilẹ tii jade lati asiko ti wọn ti n ṣe e lọwọ, o ni awọn kan fẹ ba iṣẹ oun jẹ.

Fiimu "Ọkọ Ramota" ti Jamiu Afeez kọ yii gbayii nitori akanda ẹda kan to lo ninu fiimu gẹg bi aya rẹ eyi tawn eniyan tilẹ kọkọ ro pe lootọ ni o gbe e niyawo.

Ṣe ti akitiyan, ọgbọn ori ati gbogbo ọna ti Jamiu lo lati jẹ ki fiimu naa pariwo ni ka sọ ni, amọ Jamiu figbe ta pe awọn kan to tun wa jẹ akẹgbẹ oun ṣaadede bẹrẹ si ni ya fiimu kan naa toun ti ya yii to si ti pariwo lorukọ rẹ.

Jamiu ni gẹlẹ bi oun ṣe gbe toun jade bẹẹ naa ni onitọun n ṣe ẹda iru nkan ti ohun fi oogun oun ṣe ti ẹni naa tun lọ́ pe Aunty Ramota lati wa ṣe fiimu kan naa.

"Mi o le sọ iye wahala ti mo ṣe, ogun ti mo ja lorii fiimu yii, ẹni ti ko yẹ ki n kọ ẹnu si mo ya owo lọwọ rẹ, mi o mọ ẹṣẹ ti mo ṣẹ, boya kẹẹ ba mi bẹbẹ".

Jamiu ni oun ta ilẹ toun nitoripe o wo o pe koun ṣe iṣẹ yii lorukọ oun lai gba owo lọwọ ẹnikẹni.

Lo ba bẹrẹ si ni rawọ ẹbẹ pe ki wọn fi oun we ọmọ wọn ti wọn ba fẹ ki ọmọ wọn naa ṣe oriire. O ni ki gbogbo oṣere tiata ṣaanu oun tori ẹni naa tun lọ ko awọn oṣere to tobi ju awọn ti oun ri fi owo pọọku ko jọ fun ẹda iṣẹ ti wọn n ṣee yii.

Ọ̀rọ̀ yii ti n ka awọn akẹgbẹ rẹ kọọkan lara ti wọn si n rọ ọ wipe ko ma sunkun mọ wipe Ọlọrun yoo ja fun un koda awọn mii ti n gba a nimran igbesẹ to lee gbe ati ọna abayọ.

Bakan naa, aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere, TAMPAN Ọgbẹni Bolaji Amusan ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin ti fesi lorukọ awọn agbaagba ẹgbẹ naa pe awọn ki ara bọ ọrọ naa bo tilẹ jẹ pe o ni o yẹ ko fi to awọn leti to ba fẹ ki awọn ṣe nkankan tori oun naa kan ri i bii gbogbo eniyan ni.

Esii Mr Latin

Oríṣun àwòrán, Jamiu Afeez

Esii Mr Latin

Oríṣun àwòrán, Jamiu Afeez