Herder-Farmers: Oluwo ti Iwo ní àwọn adári tó gba Fulani láàyè gan ní ìṣòro Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdul-Rasheed Adewale Akanbi ni awọn adari to ti di ipo mu lorilẹede Naijiria gan an lo jẹbi ipaniyan to n waye lorilẹede Naijiria.
Ọba Akanbi sọ eyi ninu lẹta to kọ si Aarẹ Muhammadu Buhari lori iṣekupani gba ọwọ awọn afurasi Fulani darandaran kaakiri orilẹede Naijiria.
O ni iṣoro kan ṣoṣo ti Naijiria n koju lọwọ ni eto aabo to dẹnukọlẹ nitori iṣekupani, ijinigbe to n waye lojoojumọ.
''A bi orilẹede Naijiria pẹlu ọpọlọpọ isoro paapaa pẹlu awọn adari ti ko fi ọgbọn ṣe eto awọn Fulani/Bororo ti wọn gba laaye lati duro ni awọn igbo ijọba kaakiri''
Oluwo fi kun un pe "awọn to ti ṣe adari lorilẹede Naijiria ṣẹyin lo pe awọn Fulani yii wa si inu igbo,lai si ina ọba, iyawo, ọmọ tabi ohun igbayegbadun fun wọn.''
''Awọn ti ko ri ohun igbayegbadun yii ni wọn n ji awọn eniyan gbe, ti wọn si hu iwa ọdaran ninu igbo ijọba''.
''Amọ, awọn Fulani darandaran ti wọn laju wa ni igboro, ti wọn si n gbe laarin ilu, ti wọn si n ba awọn da ẹran wọn kaakiri''.
''Ko si inu baba ti yoo dun ti awọn ọmọ rẹ ba fo sanlẹ ku lojiji, nitori naa inu mi ko dun si gbogbo ipaniyan to n waye kaakiri orilẹede Naijiria, paapaa ni ilẹ Yoruba.
Bakan naa ni Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdul-Rasheed Adewale Akanbi fikun wi pe ki awọn adari mura ni kiakia lati fi opin si eto aabo to dẹnukọle ohun.
Oba Akanbi ba awọn eniyan kẹdun, to si gbadura fun gbogbo awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ipọnju ipaniyan ati ijinigbe naa pe ki edua fun wọn ni iranwọ lati la asiko naa kọja.
Ọ̀kan lára àwọn adarí Yorùbá laó pe Sunday Igboho fún iṣẹ́ tó ń ṣe

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Mi ò gbàgbọ́ pé ààrẹ Buhari ń fọwọ́ ra àwọn Fulani lórí
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba AbdulRasheed Akanbi ti ni ọna abayọ kan ṣoṣo to wa si iṣoro ikọlu laarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran nilẹ yoruba ni ki gbogbo awọn lọba lọba pawọpọ ki wọn si bẹrẹ si ni sọrọ pẹlu ohun kan.
Oluwo n sọ̀rọ̀ lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC lorii iṣoro abo to n koju awọn ipinlẹ Yoruba kaakiri lọwọlọwọ.
O ni oun gbagbọ ninu ki ibudo sinsin maalu lati dipo ki awọn Fulani darandaran maa da maalu wọn kiri ilu ati oko oloko.
Oluwo ni eyi n ṣiṣẹ daadaa fun awọn orilẹede ilẹ okere bẹẹ si ni awan kan naa n ṣe e ni Naijiria.
O fi ara rẹ ati gbajugbaja olorin Fuji Kwam1 ṣe apẹrẹ o si ni ilana to tọ ni awọn n lo lati sin maalu tawọn.
"Ẹgbọrọ maalu nla ni ọrẹ mi Kwam1 ni oju kan ti wọn ko wọn si dẹ ni wọn ti n jẹ, eyi si lo dara ju fun awọn maalu yẹn".
Ọba yii ni iṣoro to n doju kọ ẹkun naa jẹ ohun to yẹ ki gbogbo eniyan pawọpọ lati doju ija kọ.
"Iṣoro wa ni pe ẹnu awọn Ọba Yoruba o ko".
"Awọn Emir ẹkun Ariwa ni ẹgbẹ tiwọn ti kii ṣe ti ipinlẹ nikan ṣugbọn apapọ bẹẹ si ni wọn ni adari ati ilana aatẹle amọ nilẹ Yoruba, a o ni ilana idari kankan laarin awọn Ọba".
- À ṣé ara mi ni isó tí ń rùn, tí èmi náà ń ṣépè fún ẹni tí Jamiu Azeez ń sọ - Mama Ereko
- Woli Sotitobire tún yọjú! Ó ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yáá lónìí láti tún ẹjọ́ dá
- Ọlọ́pàá dá ọkùnrin méjì tó ń ní ìbálòpọ̀ ọkùnrin sọ́kùnrin padà sí ìlú abínibí wọn
- Àláfíà ti jọba ní Ibarapa - Adarí ikọ̀ Amotekun
- Irú ìkọlù wo ló ń wáyé ní Osun tí ìjọba fi kéde òfin kónílé-ó-gbélé 24 hours?
- Kí lẹ tún fẹ́ kí LCC ṣe lẹ́yìn tí gbogbo iwádìí ti parí ní Toll Gate? - Segalink
- Ìdí tí mo fi kọ lẹ́tà sí Pa Josiah Akindayomi pé mi ò fẹ́ jẹ G.O nìyìí- Pasítọ Adeboye
- Ọba tó wàjà àmọ́ tí òkú rẹ̀ gbúdọ̀ jókòó sórí ìtẹ́ ṣáájú ìsìnkú
Ọba Akanbi ni o yẹ ki ilẹ Yoruba kọkọ dẹkun ki awọn ara ilẹ okeere to wa n ra ilẹ ninu awọn igbo wọn maa fi ṣe aburu.
Bakan naa lo ni awọn ibode orilẹede kan faaye gba oniruuru awọn to ni ero aburu lọkan lati maa wọle lọfẹ lofo.
Oluwo ni owo aladani ni ọsin ẹran maalu to si yẹ ki onikaluku to ni i mojuto nkan rẹ.
Ni tirẹ, kikọ ibudo fun sisin maalu ṣi ni ọna to dara ju ti ijba lee lo lati dẹkun ki awọn darandaran maa da maalu kiri lati jẹ.
"Ko yẹ ki Fulani Darandaran kanakan wa loju popo mọ ṣugbọn ẹ o le gba nkan lọwọ eeyan tẹẹ ba fun un ni nkan mii pada.
O ni "too ba fẹ ṣe owo maalu, owo aladani ni ṣugbọn nini ẹkọ to peye ṣe koko".
Nigba ti a bi i pe ṣe aarẹ Buhari n ṣe ohun to yẹ fun abo orilẹede yii, Oluwo ṣe afiwe akitiyan aar Buhari pẹlu iṣẹl Coronavirus pe "ṣe a le ni torii pe Coronavirus bẹ silẹ lasiko iṣejọba rẹ pe oun lo fa a?".
Torinaa o ni oun o gbagbọ pe aarẹ Buhari n fọwọ ra awọn Fulani orilede yii lori.
Ohun ti maa sọ fun Sunday Igboho ti mo ba ri i
Oluwo ti ilu Iwo sọ fun BBC pe ọkan lara awọn adari rere ni Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si sunday Igboho yoo jẹ fun iran Yoruba.
O sọ pe awọn eeyan ko ni idi kankan lati maa ro ohun to ti ṣe ri latẹyinwa toripe ko sẹni ti ko dẹṣẹ ri.
Ọba AbduRasheed ni ti oun ba ti ri aaye lati ba Sunday Igboho sọrọ, oun yoo sọ gbogbo ohun to nilo fun un.
O ni imọ ṣe koko. "Bi mo ba ti ri i maa ba sọ ọrọ to nilo".
"Ọmọ mi ni Sunday Igboho, gẹgẹ bi ọmọ Yoruba ti mo si jẹ Oriade, ọmọ mi ni, arakunrin mi si ni pẹlu tori naa, maa gba a nimọran".

















