WHO wẹ Nàìjíríà yán kàn-kàn lára àwọn orílẹ̀èdè tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19

Ajọ eleto ilera agbaye

Oríṣun àwòrán, WHO

Lọjọ Abamẹta to kọja ni ajọ eleto ilera lagbaye fi alaye sita pe orilẹede Naijiri ko si lara awọn ti awọn gbe ote le pe wọn ko ni ri abẹrẹ ajẹsara arun Covid-19 gba latipasẹ igbimọ COVAX.

Naijaria ati awọn orileede mẹjọ miran ni iroyin kọkọ gba ori ayelujara kan pe igbimọ COVAX ti ajọ ilera agbaye WHO gbe kalẹ sọ pe ko ni lanfaani lati ri abẹrẹ ajẹsara Covid-19 gba.

Idi ti a gbọ ko ju pe wọn ko ni ipese awọn aaye irinsẹ ti yoo mu ki awọn abẹrẹ ajẹsara yi maa tutu ṣaaju igba ti wọn yoo fi lo wọn.

Ajọ WHO ṣagbatẹru gbigbe igbimọ COVAX kalẹ lati pin ọgọọrọ biliọnu abẹrẹ ajẹsara ọhun kaakiri awọn orilẹede mejilelaadọrun to ku diẹ kaato fun ni ti ọrọ owona.

Ẹwẹ, aṣoju ajọ eleto ilera lagbaye WHO, Walter Mulombo fi lede nibi ipade oniroyin kan lọjọ kẹfa oṣu keji pe orilẹede mẹrin pere nilẹ Afirika ninu mẹtala ni wọn fi orukọ wọn sara iṣi kini fun abẹrẹ ajẹsara ti Pfizer and bioNtech.

O ni ajọ WHO ni ifarajin lati ran gbogbo orilẹede Afirika lọwọ ki wọn lee ri abẹrẹ naa gba.

Iroyin to gbode kan tẹlẹ

Lasiko ti adari ajọ naa lẹkun Afrika,Dokita Matshidiso Moeti n ba awọn akọroyin sọrọ loju opo ayelujara ni iwe iroyin Naijiria Punch sọ pe o fi ọrọ yi lede.

Lotitọ, Dokita Moeti ni ninu awọn orileede mẹtala to kọwe ranṣẹ lati jẹ anfaani abẹrẹ yi, mẹrin pere lati ilẹ Afrika lo jaweolubori.

Ninu alaye to ṣe, Moeti ni awọn ko le foju silẹ ki abẹrẹ ajẹsara yi ṣofo.

O ni "Nkan bi ẹgbẹrun lọna ookolelọọdunrun abẹrẹ ajẹsara Pfizer-BioNTech ni wọn ti ya sọtọ forileede Africa mẹrin - Cape Verde, Rwanda, South Africa ati Tunisia.''

''Abẹrẹ yi ti gba ontẹ fun lilo pajawiri ṣugbọn awọn orileede yi gbọdọ le fi awọn abẹrẹ yi pamọ saaye amu nkan tutu to kaju osuwọn minus 70 degrees Celsius''

Ki ni awọn alaṣẹ Naijiria sọ

Saaju asiko yi ti ọrọ jẹyọ nipa aaye ti wọn yoo ko awọn abẹrẹ ajẹsara si, ijọba Naijiria ni aaye wa tawọn yoo ko wọn si.

Adari ajọ idagbasoke ilera alabọde Naijiria Dokita Faisal Shuaib gẹgẹ bi Punch ti se sọ, ni ko si ootọ ninu iroyin to gbode pe Naijria ko laaye ti yoo ko abẹrẹ Covid-19 si.

Ohun tawọn eeyan ro ni pe o yẹ ki Naijiria wa lara awọn orileede i yoo lewaju lati le jẹ anfaani abẹrẹ ajẹsara yi.

Lara awọn orileede to wa nilẹ Afrika, Naijiria ni o ṣe ipo kẹfa lori akasọ awọn ti ọwọja aarun yi ti peleke.

Àkọlé fídíò, Amope Onibata: Kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ló gbà kí ń ṣe bàtà fún àwọn

Only South Africa, Morocco, Tunisia, Egypt and Ethiopia have higher infection rates than Nigeria. But Morocco and Egypt have already independently obtained vaccines and begun distribution while South Africa, which has the highest burden of the disease in Africa, has already procured one million doses of the Oxford-AstraZeneca vaccine, produced in India but has yet to begin distribution.

Nigeria has, however, received no COVID-19 vaccine even as its rate of infection has continued to surge.

Unlike the other vaccines on the market, the BioNTech/Pfizer vaccine, which has the highest WHO rating, is expected to be stored at 70 degrees Celsius which Nigeria could not meet.