Covid-19 vaccine: Abẹ́rẹ́ tí àjẹsára Pfizer ṣe yóò di lílò láti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ní UK

Pfizer

Oríṣun àwòrán, @thehill

Orilẹ-ede United Kingdom ni orilẹ-ede akọkọ lagbaaye ti yoo buwọlu lilo abẹrẹ ti ileeṣẹ apoogun Pfizer/BioNTech ṣe fun iwosan coronavirus.

Ajọ to ṣe akoso oogun lilo ni UK, MHRA sọ pe abẹrẹ naa lagbara lati pa arun coronavirus, o si yẹ ní nilo.

Akọwe ajọ eleto ilera ilẹ UK, Matt Hancock ṣalaye pe abẹrẹ bii 800,000 ni yoo wa fun nilo lati ọṣẹ to n bọ lọ.

Awọn agbalagba at'awọn olutọju wọn ni yoo kọkọ lanfaani lati gbabẹrẹ yii, lẹyin naa lawọn to ti le lọgọrin ọdun at'awọn oṣiṣẹ eleto ilera yoo gbabẹrẹ ọhún.

Pfizer

Oríṣun àwòrán, @Reuters

Abẹrẹ Pfizer ni abẹrẹ to ya julọ lati jade, oṣu mẹwàá pere ni wọn fi poo pọ.

Iru awọn abẹrẹ bẹẹ le to ọdun mẹwaa lati poo pọ nigba mii.

Ẹwẹ, olootu ijọba UK, Boris Johnson ni abẹrẹ yii lo maa jẹ kí awọn eeyan UK gbaye gbádùn, ohun naa lo si maa jẹ ki ọrọ aje UK gberu síi.

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'