Borno Zabarmani Rice Farmer Massacre: Àwọn àgbàgbà Òkè Ọya ní ẹ̀mí èèyàn kò níyì mọ́ lábẹ́ ìṣèjọba Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn àgbàgbà Òkè Ọya ń fẹ́ kí Ààrẹ Muhammadu Buhari kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ẹ̀mí èèyàn kò níyì mọ́ lábẹ́ ìṣèjọba rẹ.
Ẹgbẹ awọn agbagba Oke Ọya ni Naijiria, NEF, ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko kọwe fipo silẹ lẹyin to ti kuna lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria.
Awọn eeyan naa lo sọ ọrọ ọhun lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram ṣekupa eeyan mẹtaleogoji ninu oko irẹsi kan lọjọ Abamẹta ni ipinlẹ Borno.
- EndSARS: Olatunde Abolarinwa London Tailor ní òun á ṣe baba fún mi, kò tilẹ̀ dúró ṣe bàbá àwọn ọmọ tirẹ̀ tóríi ìwà Ọlọ́pàá Mopol
- A kò lọwọ́ sí ìwé ìpẹ̀jọ́ tó tako ìdásílẹ̀ ìgbìmò ìwádìí aṣemáṣe ikọ̀ SARS- ọlọ́pàá Nàìjíríà
- Àwòrán àwọn afurasí tí a fi léde kìí ṣe òfegè, ṣùgbọn a dọ́gbọ́n síi - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Àwọn Ọba alayé ní Naijiria ṣàbẹ̀wò sí Ọba Eko, Gómìnà Eko àti Bola Tinubu lẹyin ìwọ́de EndSARS
Wọn ni ijọba Buhari ti tapa si ofin ilẹ Naijiria to sọ pe ojusẹ rẹ akọkọ ni lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn ara ilu.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ na fi lede, ti agbẹnusọ rẹ, ọmọwe Hakeem Baba-Ahmed buwọlu, wọn ni ẹmi eeyan ko niyi mọ labẹ iṣejọba Buhari.
Atẹjade naa ni "labẹ ijọba yii, ẹmi eeyan ko niyi mọ, ọpọ igab si ni awọn ọdanran maa n kọlu awọn eeyan bo ṣe wu wọn."
O tẹsiwaju pe "a ko ri ami kankan pe Aarẹ n gbe igbesẹ lati yẹ́ ibura rẹ lati daabo bo awọn ọmọ Naijiria si."
Awọn agbagba naa sọ pe, ni ilẹ miran, ohun ti adari ti ko ba koju oṣuwọn maa n ṣe ni ko kọwe fiposilẹ.
- A kò lọwọ́ sí ìwé ìpẹ̀jọ́ tó tako ìdásílẹ̀ ìgbìmò ìwádìí aṣemáṣe ikọ̀ SARS- ọlọ́pàá Nàìjíríà
- Ṣé ẹ rántí àkọ́lé àwọn ìwé àkàgbádùn yìí?
- Àwọn Ọba alayé ní Naijiria ṣàbẹ̀wò sí Ọba Eko, Gómìnà Eko àti Bola Tinubu lẹyin ìwọ́de EndSARS
- Àwòrán àwọn afurasí tí a fi léde kìí ṣe òfegè, ṣùgbọn a dọ́gbọ́n síi - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Nigba to n sọrọ lori iṣekupani to waye ni Zabarmari, Baba-Ahmed sọ pe Buhari ti kuna lati tẹti si igbe awọn ọmọ Naijiria lati pese abo to peye fun wọn.
O ni esi ti agbẹnusọ Aarẹ sọ lori iṣekupani naa jẹ eyii ti ko bojumu, ni bo ṣe sọ pe awọn agbẹ ti wọn pa ọhun ko gba aṣẹ lọwọ ileeṣẹ ologun ki wọn to lọ rèé kérè oko wọn.
Ẹgbẹ naa wa kilọ pe o ṣeeṣe ki iyan mu laipẹ yii nitori bi awọn agbẹ ko ṣe ri aye lọ kere oko nitori eto abo to mẹhẹ lagbegbe ọhun.

Oríṣun àwòrán, Iconnews
Ìdí tí a fi pa àwọn àgbẹ̀ onírẹ̀sì ní Borno, Boko Haram ṣàlàyé nínú fídíò tuntun
Ikọ agbebọn Boko Haram ti gbe fidio kan jade bayii ninu eyi ti wọn ti n fi ọwọ sọya pe awọn lawọn pa awọn agbẹ to le logoji ni ilu Koshebe nitosi Maiduguri nipinlẹ Borno.
Awọn agbesunmọmi naa ni ohun to faa tawọn fi pa awọn agbẹ naa ko ṣẹyin bi awọn ara ilu naa ṣe mu awọn ọms ẹgbẹ rẹ kan ti wọn si fa wọn le awọn ọmọogun Naijiria lọwọ.
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Ìdí tí mi ò fi lè parí ìjà pẹ̀lú Ààrẹ Ọ̀nà kakanfò, Gani Adams - Obasanjo
- Ọmọ márùn ún di àwátí ní ilé àwọn ọmọ òrukàn, Stella Obasanjo Motherless Home ní Abeokuta
- Ọlọ́pàá 200 ni yóò máa ṣọ́ ibojì Diego Maradona torí àwọn olè
- Obìnrin olówònààbì ta ọmọ rẹ̀ oṣù mẹ́rin ní N300,000
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti parí láàrin ìdílé Ayinde Barrister àti Kwam 1?
- Soun ilẹ̀ Ogbomoṣo pàdánù ọmọkùnrin rẹ̀
Ọpọ lo ṣi n daro ti wọn si n sọrọ lori bi awọn agbebọn ikọ Boko Haram naa ṣe dumbu awọn agbẹ naa loko irẹsi ti wọn ti n ṣiṣẹ.
Shekau to jẹ olori igun kan lara ikọ Boko Haram ṣekilọ pe irufẹ ipaniyan bẹẹ lawọn yoo maa fi bẹ gbogbo awọn to ba n lẹdi apo pọ pẹlu ileeṣẹ ọmọogun Naijiria.
Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé àǹfàní tó wà nínú gbígba ajaguntà láti kojú Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Facebook / Samuel Aruwan
Orilẹede Naijiria tun ke irora iku ọwọọwọ ni ọjọ Ababmẹta, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2020 nigba ti awsn agbebọn Boko Haram tun kọlu ileto Koshebe nitosi Maiduguri ti wọn gbẹmi awsn agbẹ onirẹsi to le ni ogoji.
Lati igbayii wa lawọn ọmọ Naijiria ti n kebosi sigboro aye ti koowa si n gbe amọran tirẹ kalẹ lori ipo ti eto abo wa lorilẹede Naijiria bayii.
- 'Àwọn agbébọn tó pá Olufon ti Ifon ti ṣe ohun èèwọ̀ ní ilẹ̀ Yoruba'
- Awakọ̀ agbókùú, ọlọ́pàá, ológun, oníròyìn ló máa ń kọ́kọ́ dìbò ní Ghana, bó ṣe ń lọ rèé
- Olorì Aláàfín tẹ́lẹ̀, Anuoluwapo Adeyemi gba àmì ẹ̀yẹ lórí ipa tó kó nínú oge ṣíṣe
- 'Ẹ sọ́ra fún "Christmas Carol", ẹ̀yin tẹ́ẹ sì wà lókè òkun ẹ má wálé o!'
Lara awọn ohun ti wọn gbe kalẹ ni pe ki aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari o gba awọn ajagunta lati ṣe afọmọ aginju Sambisa ati agbegbe etido adagun omi Chad ki wọn koju awọn agbebọn to ti fi ibẹ ṣe ibuba.
Lara awọn eekan to gbe aba yii kalẹ ni gomina Zulum ti ipinlẹ Borno.
Amọṣa awọn to nimọ nipa ọrọ abo lorilẹede yii kan ti n ti ipe naa lẹyin.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ọgbẹni Onyekachi ni ko sohun to buru nibẹ, niwọn igba to jẹ pe awọn orilẹede to nifọn leekannna lagbaye gan n lo ajagunta.
Ọgbẹni Onyekachi ṣalaye pe kii ṣe ọrọ agbekọrọ iyẹwu sọ mọ pe apa ti kun ileeṣẹ smọogun orilẹede yii, nitori naa, ẹni to ba lee ṣe lo yẹ ka bẹ lọwẹ.
O sọ ọ siwaju sii pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti orilẹede Naijiria yoo maa gba awọn ajagunta fi koju wahala Boko Haram. O ni ohun ti Aarẹ ana, Goodluck Jonathan pẹlu ṣe ni.
O ni o han pe ohun elo to to ko si fun awsn ologun nitori naa, titi digba ti ijọba yoo fi lee ra nnkan ija to to, mimu aba lori gbigba awọn ajagunta lo, ko buru ju.
Ṣé àwọn ìjayà ajaguntà ilẹ̀ òkèrè leè bá Nàìjíríà fòpin sí ìṣòro àbò?
Awọn onimọ nipa eto abo gbagbọ wipe lilo awọn ologun ilẹ okere ko lee laye laye wa ojutu si iṣoro abo to n doju kọ orilẹede Naijiria lọwọ lọwọ.
Iha ti awọn onimọ nipa eto abo ni Naijiria kọ si ohun ti gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum sọ ree.
Iṣẹlẹ bi Boko Haram ṣe dumbu ọpọ awọn agbẹ ti ko lonka bayii niha ariwa orilẹede Naijiria, ipinlẹ Borno ti n mu isrọngbesi jade lorii boya awọn ologun Naijiria tilẹ kapaa awn agbesunmmi rara.
Bi agbaye ṣe n kọminu ti wọn si n daro lori iku awọn agbẹ onirẹsi tawọn agbebọn Boko Haram pa lọjọ Abamẹta, gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babangana Umara Zulum ti gbe opo mẹfa kalẹ to ni yoo lee dẹkun atunṣẹ irufẹ ifẹmiṣofo bẹẹ.
Gomina Zulum ṣalaye yii lasiko ti aarẹ ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ahmed Lawal ko iks ti aarẹ ran si ilu Maiduguri sodi wa si ọfiisi rẹ lati daro lori iku awọn eeyan ti wọn pa naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/governor Borno
O ni awọn koko mẹfa ti ijọba aarẹ Buhari gbọdọ tete mu gbọ ree bi o ba fẹ ki opin de ba irufẹ ifẹmiṣofo naa.
1.Ki aarẹ gba awọn ọdọ ipinlẹ Borno si ileeṣẹ ologun lati lee kun wọn lọwọ.
2.Riri daju pe awọn orilẹede to yi agbegbe naa ka bii Chad, Niger ati Cameroun ṣiṣẹ lori wiwagbo dẹkun sawọn isọmọgbe ikọ agbebọn naa to wa letido adagun omi Chad
3.Ki ijọba gba awọn ajagunta lati ṣe afọmọ agbegbe Sambisa.
4.Ki ijọba pese awọn ọkọ ti ado oloro alagbinsinu ilẹ, (Mines) ko lee ran fawọn ologun
5.Ki ijọba ṣe atilẹyin gbogbo to ba yẹ fun kiko awọn ti ogun le lọ sorilẹede Niger ati Cameroun pada wa sile.
6.Mu alekun agbara ba ọrọ aje awọn eeyan ipinlẹ Borno.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Governor Borno
Ṣaaju ni aarẹ ile aṣofin agba, Ahmed Lawan ti ba awọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun lorukọ aarẹ Muhammadu Buhari ni aarẹ ti paṣẹ fawọn ologun lati tubọ mu gbigbogun ti awọn agbebọn Boko Haram lọkunkundun, paapaa julọ nipa gbigbe ija naa tọ wọn lọ si ibuba wọn.
Ẹwẹ, Bulama Bukarti to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ abo ilẹ Afirika ni bi wọn ba ko awọn ologun ilẹ okere wọ Naijiria, ko difa fun opin iṣoro abo.
Torinaa o kilọ pe wọn gbudọ fara balẹ gidi gan bi wọn ba fẹ ṣe iru ipinu yii tori wọn kii ko agba ogun ja wa lati ita.
"Awọn abanijagun ilẹ okere ko ni aaye kankan ninu ofin ilẹ Naijiria ayafi bi wọn ba fẹ tun un ṣe nitori ki wọn lee gba wọn siṣẹ".
Bulama ni lilo awọn abanijagun ilẹ okere lasiko ogun maa n gbowo lori gan tori wọn maa n diidi ya owo gọbọi sọtọ lati gba wọn ni.
O fi kun un pe bi wọn ba tilẹ kọ awọn ọdọ ologun niṣẹ, awọn to kawe ni ki wọn gba.
Agbẹjọro Bulama ni ewu nla wa ninu ki wọn gba awọn puruntu ọdọ ti ko lẹkọ tori yoo kan jẹ asiko fun wn lati tun da orilẹede sinu hila-hilo ni.
Sibẹ, ijọba Naijiria ti sọ lọpọ igba pe awọn run Boko Haram jegejege ki awọn agbesunmọmi ọhun to tun turi jade fun iwa ipa to n pọ sii.
'Nínú ọmọ mẹ́rìndínlógún tí mo bí, ààyò ibẹ̀ gan ni Boko Haram pa'

Oríṣun àwòrán, BELLO ZABARMARI
"Ninu ọmọ mẹrindinlogun ti mo bí, Musfau jẹ pataki, nitori pe akikanju ni. Koda, ẹkún kekere kọ ni iya rẹ sun, nitori iṣẹlẹ yii."
Awọn nkan yii ni Mallam Musa Zabarmani sọ fun BBC nipa ọmọ rẹ, Musfau, to jẹ ẹnikan lara awọn eeyan ti afurasi Boko Haram pa lọjọ Satide lasiko ti wọn kọlu awọn agbẹ nilu Koshebe, nipinlẹ Borno.
Ẹni ọdun mejidinlogun ni Musfau saaju iku rẹ.
Baba rẹ sọ pe kilaasi to kan gun si asekagba nile ẹ̀kọ́ girama agba (SS2) ni ọmọ naa wa, àmọ́ o tun fẹran lati ma a sisẹ yatọ si ẹ̀kọ́.
"Ọdọọdún lo ma n ṣe iṣẹ oko, o si má n fi owo to ba gba ran ẹbí ati iya rẹ lọwọ, nitori pe oun ni àkọ́bí rẹ.
"Koda, a jọ ki ara wa pe o dabọ ni ko to o lọ si oko irẹsi to ti n ba wọn sisẹ. Sugbọn mi o mọ pe igba ikẹhin ti ma a ri niyẹn."
"Ibanujẹ si lo ma n jẹ fun mi, ni gbogbo igba ti mo ba ri ibusun ati awọn ẹrù rẹ ninu yaara. Àmọ́ ki la fẹ ẹ ṣe, akọsilẹ ohun gbogbo wa lọwọ Ọlọ́run."
Ni ti Mallam Labbo Tanimu, ọmọ rẹ meji ati oṣiṣẹ mẹta lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ninu oko irẹsi wọn.
Ọkan lara awọn ọmọ naa, Usman, n mura fun igbeyawo rẹ, ti ikeji, Musa, si ti ni idile ti ẹ.
O ṣalaye pe awọn irè oko oun ṣi wa ninu oko, nitori pe ibẹru ko jẹ ki awọn o lọ.
O si bẹ ijọba lati tete wa opin si iru iṣẹlẹ naa.
Gómìnà Zulum ní àwọn abanijẹ́ ló ń ṣe kèéta ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babagana Zulum ni gbigbogun ti iwa awọn adunkukulajamọni bii Boko Haram ni Naijiria ko lee tan ayafi ti ijọba ba gbogun ti iwa biba ti ọmọlakeji jẹ.
Ọgbẹni Zulum sọ eyi fun ileeṣẹ iroyin BBC lọjọ Aje lẹyin ipaniyan to waye si o kere tan, awọn agbẹ mẹtalelogoji ni ipinlẹ Borno lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kọkanla.
Ipaniyan naa waye ni ilu Koshebe nijọba ibilẹ Mafa ni ẹkun Ila Oorun-Ariwa ipinlẹ Borno eyi to jẹ ibi ija igba de igba ikọ Boko Haram.
"Ko ye awọn eeyan nigba ti mo n sọ ọrọ yii, wọn a ni mo n gbiyanju lati bu ẹnu atẹ lu awọn ologun Naijiria ṣugbọn ọpọ ibatọmọlakeji eeyan jẹ wa ninu ijọba yii!"
Biba ti ọmọlakeji jẹ wa laarin awọn oloṣelu, o wa ninu ile iṣẹ ologun Naijiria koda o wọpọ laarin awọn oṣiṣẹ ijọba"
Gomina ni ọdun mọkanlelaadọta yii fi kun un pe ẹnikẹni ti igba iwa yii ba ṣi mọ lori, o yẹ ki wọn fimu rẹ danrin gidi gan.
Kii ṣe igba akọkọ niyii ti Ọgbẹni Zulum yoo jade lati bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ ologun Naijiria pe wọn ko ṣe to lati da abo bo ẹmi ati dukia ni ipinlẹ oun.
Bo tilẹ jẹ pe o kọ lati da ẹbi naa le iṣẹlẹ ọjọ Abamẹta ti wn ti dumbu awọn agbẹ onirẹsi ni Koshebe lori.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo ṣẹlẹ lọjọ Satide ọjọ kejindinlọgbọn?
Ọgbẹni Zulum fi aridaju ọrọ sita pe awọn Boko Haram yabo oko kan ni Koshebe nibi ti wọn ti kọkọ waasu fun awọn agbẹ to wa nibẹ lẹyin naa ni wn ko wọn sinu ile kan ti wọn ti bẹrẹ si ni mu wọn jade lọkọọkan lati dumbu wọn.
Eeyan mẹtala lo ribi sa asala fun ẹmi wọn gẹgẹ bi ọrọ̀ ti gomina sọ pe awọn adukokomọni ọhun n dumbu awọn eeyan bii ẹran maalu.
Ìjọba ààrẹ Buhari ti sú àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí àìsí àbò
Ooṣa boo le gbe mi, ṣe mi boo ṣe ba mi.
Lo difa fun bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n fesi lọwọlọwọ si iṣoro abo ti ina rẹ n jo ajorẹyin bayii lorilẹede naa paapaa lasiko ti wọn n ṣọfọọ awọn agbẹ onirẹsi to le laadọfa ti wọn dunmbu nipinlẹ Borno.
#SacktheServiceChiefs làwọn èèyàn ń pariwo sí ààrẹ Buhari ti sú àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí àìsí àbò.
Ko si ani ani pe eguna to n joni lọwọ ni iṣoro abo ni lọọlọ yii o si n ru ibinu awọn ara iha ariwa orilẹede yii soke.
Lati igba ti iroyin bi wọn ṣe n pa awọn agbẹ yii ṣe n tan ka orilẹede Naijiria ni ẹru ti n ba awọn ara agbegbe naa pe ko ma jẹ pe opin ti n de fun awọn.
Lọwọlọwọ, wọn ṣi n wa awọn kan lara awọn agbẹ onirẹsi ti awọn agbebọn kọlu ni Borno yala wọn ku ni tabi wọn ye.
Ajọ isọkan agbaye, UN fi sita lọjọ Aiku pe lodi si mẹtalelogoji ti awọn oniroyin Naijiria n gbe jade pe o ku, awọn ti ko din ni aadọfa gangan lo ku.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipo wo ni awọn ilu igberiko Borno wa bayii?
Ọpọ agbẹ ni ẹkun Ila Oorub Ariwa orilẹede yii ti oko wọn ti di apati bayii ni ko le kore eso to kere ju loko wọn nitori iklu awn agbesunmọmi.
Ọkan lara wọn sọ fun BBC pe too ba ri ilu kan ti wọn ti pa gbogbo eeyan ti wọn si n ji wọn gbe, igba mii too ba san owo itanran gan
O ni: "Ki n ma parọ, ijọba ti kuna, wọn ti ja wa kul tori lati ọdun marun sẹyin ni iṣoro ati wahala ti n wa".
"Aarẹ si nilo lati mu ọrọ awọn alaidaaa ni ijba rẹ kuro ko si yi ọna ara toun funrarẹ gan kuro.

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
'Buhari ti kuna'
Ajafẹtọ ọmọniyan kan, comrade Kabiru Dakata ni oun ni toun lero pe asiko ti to fun aarẹ Naijiria lati gbe igbesẹ idajọ
O ni "idajọ akọkọ ta n reti latọdọ aarẹ Buhari ni pe ko fipo aarẹ silẹ, nitoripe ootọ́ ni pe o ti kuna ni ẹka abo, eyi to jẹ ibi to yẹ ko ti ko ipa pataki".
"Bi aarẹ ko ba gbagbe, o ti gba aarẹ Jonathan nimọran ri pe ko fipo aarẹ silẹ nigba ti o fi ẹsun kan Jonathan pe o ja Naijiria kulẹ lẹka didaabo bo Naijiria".
Dakarta ni koda ki aarẹ gba iṣẹ lọwọ gbogbo awọn olori ologun



















