Diego Maradona: Ọlọ́pàá 200 ni yóò máa ṣọ́ ibojì Maradona torí àwọn olè

Ibi isinku Diego Maradona

Oríṣun àwòrán, Casa Rosada

Yoruba bọ wọn ni ohun ti a ba fi silẹ, ni ewurẹ n gbe.Eyi lo mu ki ijọba orile-ede Argentina ṣeto fun igba ọlọpaa ti yoo maa ṣọ iboji agbaọjẹ agbabọọlu tó lọ, Diego Armando Maradona.Ijọba ni ohun gbe igbesẹ yii lati dena mọ awọn ole to lee fẹ ji nkan ninu ibojì naa.

Awọn alaṣẹ ilẹ naa bẹru pe awọn janduku le lọ ji awọn ohun mere mere to wa ni iboji naa ti ko ba si eto abo to mọyan lori níbẹ.

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'

Ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto aabo sọ pe awọn ẹṣọ yoo duro wamu wamu lati ṣọ ibi isinku síi Bella Vista lẹyin olu ilu Argentina, Buenos Aires fun o kere tan fun ọsẹ kan.Ijọba ko fẹ ki ohun to ṣẹlẹ lọdun 1987 nigba ti awọn janduku ji ohun mere mere ko ninu ibojì Aarẹ Argentina tẹlẹ ri, Juan Peron lọ.Maradona to ṣagbatẹru bi Argentina ṣe gba ife ẹyẹ agbaye ọdun 1986, dagbere faye lẹni ọgọta ọdun.Aisan ikọlu ọkan lo ṣekupa Maradona lẹyin to ṣiṣẹ abẹ ọpọlọ tan tori ẹjẹ to da si i lọpọlọ.Bi awọn ọmọ ilẹ Argentina ti fẹran Aarẹ Peron bi oju, ni wọn ṣe fẹran akọni agbabọọlu Maradona naa.