Barrister - K1 rift: Ìjà parí! Ìdílé Barrister àti K1 Wasiu Ayinde sọ àsọyépọ̀ nílé Obey Commander

Idile Ayinde Barrister ati K1 Marshal

Oríṣun àwòrán, Olasunkanmi Marshal/Facebook

Ko sí a gbé ma já, aja ma tan ni ko daa.

Eyi lo difa fun idile oloogbe agbaọjẹ Olorin Fuji, Sikiru Ayinde Barrister ati K1 De Ultimate, Wasiu Ayinde Marshal ti wọn ti pẹtu sí aawọ to wa laarin wọn.

K1 to tun jẹ Mayegun ilẹ Yoruba ṣalaye pe ile agbaọjẹ olorin Juju, Ajihinrere Ebenezer Obey Fabiyi ni Ikeja ni idile mejeeji ti pade.

Idile Ayinde Barrister ati K1 Marshal

Oríṣun àwòrán, Olasunkanmi Marshal/Facebook

Àkọlé fídíò, 'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'

Alhaji Adisa Oseifa to jẹ ọrẹ korikosun Barrister naa wa nikalẹ nibi Ipade ọhun.

Bakanna, aarẹ ati akọwe agba ẹgbẹ awọn olorin Fuji naa peju pesẹ sibi ipade ati pẹtu sija ọhun.

Àkọlé fídíò, Barister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa
Idile Ayinde Barrister ati K1 Marshal

Oríṣun àwòrán, Olasunkanmi Marshal/Facebook

Gbogbo awọn ọmọ oloogbe at'awọn iyawo lo wa níbẹ, awọn kan tiẹ tun darapọ nipasẹ ẹrọ ayelujara "Zoom.

"Ifarakinra ati pipari ija yii ni yoo bẹrẹ ayẹyẹ iranti ọdun mẹwaa ti Barrister ti papoda.Ọjọ kẹrindilogun oṣu Kejìlá ọdun 2020 yii ni yoo pe ọdun mẹwaa ti Barrister dagbere faye.

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'
Idile Ayinde Barrister ati K1 Marshal

Oríṣun àwòrán, Olasunkanmi Marshal/Facebook