Boko Haram: Oluwatobi Adeigba, Ọkọ mi ń lọ siṣẹ́ fún àjọ INEC ló kàgbákò ikú - Opó Adeigba

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'

Pẹlu bi awayemalọ kan o ṣe si, ọna ti awọn mii gba lọ ṣi ń sọ ọpọlọpọ ẹbi ati ara sinu ibanujẹ ailopin.

Ọmọ ipinlẹ Kogi ni Adeigba Oluwatobi to ti di oloogbe bayii latari igbesunmọmi Boko Haram ni ipinlẹ Yobe nibi to ti sinruulu lọdun 2011.

Amọ lati igba naa di akoko yii, iyawo rẹ ṣi n wa ẹkun mu lojoojumọ nigbakuugba to ba n sọ itan bo ṣe ṣẹlẹ.

Kii kuku ṣe pe o n rinrin rederede kiri, iṣẹ ti wọn gbe fun un lati lọ ṣe gẹgẹ bi oṣiṣẹ agunbanirọ ajọ eleto idibo, INEC nigba naa ni ọkọ to wa ninu rẹ kan rekọja lori ọra dudu kan loju popo lai mọ pe iku iku ni wn gbe sinu ọra naa.

"Dẹrẹba gan ri ọra "Poly Bag" ọhun, o n wo o niwaju ṣugbọn ko mọ pe ado oloro lo wa ninu rẹ. Wọn ti tẹ ẹ tan, o kan bugbamu ni".

Iyawo oloogbe, Adefunke Adeigba to ni awọn kaakiri dọ awọn gomina ipinlẹ ti ọkọ rẹ ti wa ati ti ipinlẹ ti wọn n gbe titi titi, ṣi n rọ ijọba lati ran idile oun lọwọ ki iya ma baa jẹ awọn ọmọ ti Danjiel Oluwatobi fi silẹ lọ.