Borno Zabarmani massacre: Ípànìyàn tó wáyé ní Borno fihàn pé omi n bẹ lámù fún ètò ààbò - Tinubu

Ípànìyàn tó wáyé ní Borno lọ́jọ́ Sátidé fihàn pé omi n bẹ lámù fún ètò ààbò ní Naijiria - Tinubu
Bí Boko Haram ṣe pa àwọn àgbẹ̀ ní Borno fihàn pé ọ̀rọ̀ ààbò Naijiria n fẹ́ akitiyan si - Bola Tinubu
Oloye ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu ti sọ pe bi Boko Haram ṣe pa awọn agbẹ onirẹsi nipinlẹ Borno lọjọ Satide fihan pe igbogun ti awọn agbesunmọmi ṣi nilo akitiyan si ko to o le wa sopin.
Ninu lẹta kan ti Tinubu kọ si gomina ipinlẹ Borno, Zulum, lati ba kẹdun iṣẹlẹ naa to waye ni Zabarmani, lo ti sọ eyi.
Ko din ni agbẹ onirẹsi mẹtalelogoji ti Boko Haram bẹ lori nibẹ.
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ nípà olùdíje mèjì tó lágbára nínú ìdìbò Ghana rèé
- Àyà mi já nígbà tí Ganduje rọ Sanusi lóyè Emir Kano tó fi Bayero síi, ṣùgbọ́n...- Ooni Ile Ife
- Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kan ṣoṣo ni aṣòfin mẹ́rin ń pín lò! Àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun pariwo sí Gómìnà wọn
Ọpọlọpọ eeyan lo si ti bu ẹnu ẹtẹ lu ipaniyan naa.
Tinubu sọ pe pipa ti wọn pa awọn agbẹ naa, to n tiraka lati pese fun ẹbí wọn ati oúnjẹ fun orile-ede Naijiria, ko yatọ si iwa ika ati ti Satani.
O gboriyin fun Gomina Zulum, fun gbogbo akitiyan rẹ lati ri pe awọn ti ogun sọ di alainilelori, pada si ilu abinibi ati isẹ oojọ wọn.
Eyi to ni o ti mu idagbasoke ba ipese oúnjẹ ni Naijiria, ati idunnu ba awọn eeyan naa.
Ìdí tí ààrẹ Buhari ṣe padà gbà láti yọjú si ilé ìgbìmọ̀ aṣójú-ṣòfin tórí ọ̀sẹ́ Boko Haram
Adari ile igbimọ aṣojuṣofin ilẹ Naijiria, Femi gbajabiamila ti fi lede pe aarẹ Muhammadu Buhari ti gba lati wa siwaju ile aṣojuṣofin bayii.
Eyi ko sẹyin ọrọ ikọlu to waye ni ilu Kushebe Zabarmani nibi ti ikọ Boko Haram ti dumbu ọpọlọpọ awọn agbẹ onirẹsi to bẹẹ ti ko tii ni pato onka iye awọn to fori fa iku naa.
Ọjọbọ ọsẹ ni Gbajabiamila n sọ fun awọn oniroyin lẹyin to ṣepade kan pẹlu aarẹ ni ile rẹ.
Lọjọ Aje ọsẹ ni ile igbimọ aṣojuṣofin Naijiria kọwe pe aarẹ Buhari lati wa wi tẹnu rẹ nipa iṣoro aabo to n koju orilẹede yii.
Bakan naa, o tun ṣalaye awọn igbesẹ ti ijọba rẹ n gbe lati fopin si iwa iṣoro yii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ikọ Boko Haram latẹnu adari wọn tun ṣẹṣẹ ṣe fidio kan jade ni ninu eyi to ti ṣalaye bi awọn ṣe pa awọn agbẹ naa.
- Ìwé àkàgbádùn láti ọwọ́ Fagunwa, Faleti, Iṣọla, Ogunniran àti Okediji tó yẹ kí o kà lásìkò yìí...
- Ìdí tí a fi pa àwọn àgbẹ̀ onírẹ̀sì ní Borno, Boko Haram ṣàlàyé nínú fídíò tuntun
- COVID-19 gbẹ̀mí èèyàn kan lọ́jọ́rú, èèyàn 122 tún ti ní COVID-19 ní Nàìjíríà
- 'Àwọn ọmọ 5 kọ́ ló sọnù, ọmọ 28 ló sálọ síléeṣẹ́ foyúngbowó nípinlẹ̀ Ogun'
- Ìwé àkàgbádùn láti ọwọ́ Fagunwa, Faleti, Iṣọla, Ogunniran àti Okediji tó yẹ kí o kà lásìkò yìí...
'Boko Haram ti gbilẹ̀ kan nílẹ̀ Hausa, wọ́n ti ń ní "Check Point" láti gba owó lọ́wọ́ àwọn àgbẹ̀'
Gẹgẹ bi ile igbimọ aṣofin mejeeji ṣe n ke si aarẹ buhari lati da wa wi tẹnu rẹ ati pe ko gba iṣẹ lọwọ awọn ọga awọn ologun tori wọn ni wọn ti kuna ninu iṣẹ wọn.
Ile igbimọ aṣofin agba ni tiwọn to tẹnu mọ ọ́ pe ọrọ̀ aje orilẹede Naijiria ti wa di akurẹtẹ gbaa to bẹẹ to fi jẹ wipe awọn Boko Haram ti n gbe nkan di ọna lawọn apa ibi kọọkan ni Borno.
Awọn ibudo yii ni wọn ti n da awọn agbẹ to n lọ si oko duro lati maa gba owo lọwọ wọn". Tori eyi wọn ni dandan ni ki aarẹ ṣe atunto ẹka abo ni Naijiria.
Igba kẹta ree ti ile aṣofin n funpe si aarẹ Buhari lati yọ awọn ọga awọn ologun. Titọ yii n jẹ jade latari awọn agbẹ onirẹsi tawọn Boko Haram dumbu bi ẹran ni Borno ti ko si tii si ojutuu.

Oríṣun àwòrán, @Thenichenews
Niṣe lawọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati wa ṣalaye ibi ọrọ de duro nipa eto abo orilẹ-ede Naijiria.
Wọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn aṣoju lati ipinlẹ Bornu da aba pe o yẹ ki Aarẹ Buhari yọju si ile ọhun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, opin ọsẹ to kọja yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram dumbu eeyan mẹtalelogoji bi ẹni dumbu ẹran ninu oko irẹsi kan ni ipinlẹ naa.
- 'Àwọn agbébọn tó pá Olufon ti Ifon ti ṣe ohun èèwọ̀ ní ilẹ̀ Yoruba'
- Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé àǹfàní tó wà nínú gbígba ajaguntà láti kojú Boko Haram
- Awakọ̀ agbókùú, ọlọ́pàá, ológun, oníròyìn ló máa ń kọ́kọ́ dìbò ní Ghana, bó ṣe ń lọ rèé
- Olorì Aláàfín tẹ́lẹ̀, Anuoluwapo Adeyemi gba àmì ẹ̀yẹ lórí ipa tó kó nínú oge ṣíṣe
Ṣaaju ni ariyanjiyan ti kọkọ waye laarin awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju lori boya ki wọn ke si Aarẹ tabi ki wọn ma ṣe bẹẹ.
Eyii to mu ki agbẹnusọ ile naa, Femi Gbajabiamila parọwa si awọn eeyan ọhun pe ko bojumu lati ke si Aarẹ lati wa tu aṣiri igbesẹ ti ijọba n gbe lori eto abo, nitori ko le so eso rere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣugbọn awọn kan ninu ile naa faake kọri pe ko si ohun to buru ninu ki Aarẹ wa ṣo fun awọn ọmọ Naijiria awọn ohun to n ṣe lori eto abo ẹmi ati dukia wọn.
Ṣugbọn lẹyinorẹyin, ọkan lara awọn to daba pe ki wọn pe Aarẹ, Ahmed Jaha ni o ti di ọranyan ki Aarẹ yọju sile naa, ti awọn aṣoju miran si ṣegbe lẹyin rẹ ki gbogbo ile to gba aba ọhun wọle.
Bo tilẹ jẹ pe ile igbimọ aṣoju naa fọwọ si pe ki Aarẹ wa wi tẹnu rẹ lori eto abo Naijiria, wọn ko tii sọ ọjọ ti Aarẹ yoo wa.
Ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2020 ni awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ṣekupa awọn eeyan mẹtalelogoji lagbegbe Marrabati ati Hammayya, lẹba ijọba ibilẹ Jere, ni ipi9nlẹ Bornu.















