UK immigration rules: Wo bí o ṣe lè gba físà tóo bá fẹ́ ṣiṣẹ́ ní UK láti ọdún tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, @82ndBigCountry
Wọn ti bẹrẹ si ni f'orukọ sílẹ fun awọn to ba fẹ gba iwe aṣẹ igbelu,Visa lati lọ ṣiṣẹ ni ile Gẹẹsi bẹrẹ lọjọ kini ọdun to n bọ.
Lati le jẹ anfaani yi, awọn oṣiṣẹ lati ilẹ òkèèrè gbọdọ ní ami to to aadọrin 70, ki wọn to le wọle.
Bakan naa ni wọn ni gbedeke yoo wa lori iye awọn akẹkọọ to le wa silẹ Gẹẹsi wa kawe lati ita.
- Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìdájọ́ ikú fún Maryam Sanda tó gún ọkọ rẹ̀ pa
- Díẹ̀ ló kù kí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ di ọjọ́ ikú fún ìyá mi lọ́jọ́ tó bí mi - Seyi Makinde
- Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham
- Ṣé Amotekun ti di "HisbahTekun" ní ìpínlẹ̀ Osun ní?
Ilana tuntun gbigba Visa fawọn akẹẹkọ yi tumo sì pe oṣù mẹfa ṣaaju igba ti won yoo bẹrẹ ẹkọ ni wọn gbọdọ ti fi orukọ silẹ loju opo igbaniwọle.
Ko tan sibẹ, wọn fẹ gbe Visa kan jade lọdun 2021 ti yoo fún àwọn tó bá parí ẹkọ wọn tán lati duro si ilẹ Gẹẹsi fún ọdún kan sí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi eeyan ba pari ẹkọ PhD, ọdun mẹta ni yoo le fi duro lẹyin ẹkọ rẹ.
Bayii ni o ṣe le f'orukọ sílẹ láti ṣiṣẹ ni Uk
Oju opo ayelujara ni iforukọsilẹ ti bẹrẹ ṣugbọn awọn kan yoo ni lati kan si aaye iforukọsilẹ Visa lati fi awọn iwe aṣẹ ti awọn Ileesẹ fẹ gbawọn ṣiṣe.
Wọn tun gbọdọ mu iwe ẹri to ṣafihan pe wọn gbọ èdè gèésì daada.
Awọn iṣẹ ti wọn n wa eeyan fun nilẹ Gẹẹsi ree:
Dokita to n tọju ẹranko
Ayaworan ori kọmputa (Graphics designers)
Web designers
Software developers
Ayaworan ile kikọ
Onisẹ ọna
Akọrin
Wẹlida
Olopo tabi kooki
Cyber security specialist
IT professionals
Onimọ ẹrọ
Onimọ Sayensi
Báyìi ni ìlànà tuntun lórí gbígba físà UK lẹyìn Brexit ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, @cashousenow1
Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ ọ bayii lori ati gba iwa irinna, fisa si orilẹ-ede United Kingdom, papaa julọ lẹyin eto Brexit eyi to tumọ sí pe UK ti fi ajọ EU ilẹ Yuroopu silẹ.
Ijọba orile-ede UK labẹ akaso olootu ijọba, Boris Johnson ti ṣeleri pe, ohun yoo ṣe eto wiwọle ati jijade silẹ naa lọna ti yoo rọrun fun gbogbo eeyan.
Lati ọjọ Iṣẹgun, gbogbo awọn ara ilẹ okeere to n ṣiṣẹ ni UK to fi mọ awọn ọmọ ilẹ ajọ EU gbọdọ bẹrẹ si ni f'orukọ silẹ lori ayelujara lati gba fisa ilẹ UK.
Lilọ bibọ sí UK yoo dopin lọjọ kọkanlelọgbọn oṣù kejila ọdun 2020, amọ ọjọ kọkanlelọgbọn oṣù kinni ọdun 2021 ni UK yoo fi ajọ EU silẹ.

Oríṣun àwòrán, @82ndBigCountry
Ba wo ni ilana wiwọ ati jijade ni UK ṣe kan ọ?
Ilana tuntun wiwọle ati jijade ni orile-ede UK ni yoo sọ awọn to koju oṣunwọn lati ṣiṣẹ nilẹ UK lati ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2021.
Gbigba fisa fawọn to fẹ ṣiṣẹ ni UK yoo máa niṣe pẹlu awọn amuyẹ kan bayii.
Isọri awọn oṣiṣẹ kan wa ti wọn le sọ ede Oyinbo daadaa, o kere tan £25,600 ni owo oṣu ti wọn yoo máa gba.
Owo pọn-un to to £610 si £1,408 lawọn eeyan yoo maa lo lati f'orukọ silẹ fun fisa lati ṣiṣẹ ni UK, wọn sì gbọdọ ni owona to to lati tọju ara wọn.
Bakanna, wọn gbọdọ ni ami idanimọ to mọyan lori.
Awọn to ba ti f'orukọ silẹ fun fisa lati ṣiṣẹ ni UK ni lati duro fun ọsẹ mẹta lati mọ bo ya wọn yege tabi wọn kuna.
Ofin tuntun naa ti wa fawọn to ba fẹ lọ kẹkọọ nilẹ Uk.
Anfaani yoo tun wa fawon to ni talẹnti to tayọ ninu ìmọ ẹrọ, sayẹnsi ati ọrọ aṣa.
- Inú mi dùn lẹ́yìn tí mo ní àrùn HIV ju kí n tó lárùn náà lọ - Christopher
- Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Pfizer kéde ló fa ọ̀wọ́ngógó epo ní Naijiria - Ìjọba àpapọ̀
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara













