Ayuba Wabba: Ẹ̀yin gómìnà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ìfẹ̀yìntì òṣìṣẹ́, ẹ rìn jìnnà si

Aarẹ ẹgbẹ osisẹ ni Naijiria, Ayuba Wabba

Oríṣun àwòrán, News Agency of Nigeria

Ọrọ aje Naijiria to dagun ti ba ọna miran yọ, to si ti nira fun ọpọ ipinlẹ lati ri owo osu to kere ju san fawọn osisẹ wọn.

Koda, ko ju ipinlẹ marun pere lọ to ni agbara lati san owo osu to kere julọ naa fawọn osisẹ wọn, eyi tii se ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

Koda, nitori ojojo to n se ọrọ aje wa yii, spọ ipinlẹ lo n lọ ya owo lati gbọ bukata sisan owo osu awọn osisẹ, ko to di ariwo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọsẹ to kọja si ni ariwo ta pe awọn gomina ipinlẹ ni Naijiria ti n gbero lati lọ ya Trilliọnu mẹtadinlogun naira ninu owo ifẹyinti awọn osisẹ ti wọn n da pamọ.

Awọn osisẹ n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHeadquarters

Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, tii se alaga igbimọ amusẹya fun igbimọ to wa fọrọ aje lo gbe aba naa siwaju awọn gomina, eyi ti wọn yara fontẹ lu.

Eyi si lo mu ki ẹgbẹ osisẹ nilẹ wa fi igbe ta fawọn gomina lawọn ipinlẹ pe ki wọn mase san iru asọ bẹẹ soro nitori wọn le ru igi oyin.

Aarẹ ẹgbẹ osisẹ NLC nilẹ wa, Comrade Ayuba Wabba wa fewe ọmọ mọ awọn gomina lawọn ipinlẹ leti pe ki wọn rin jinna tefetefe si owo ifẹyinti naa, tori wọn ko ni asẹ lori rẹ.

Awọn osisẹ n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHeadquarters

"Owo ti wọn n fi pawọn fun ifẹyinti awọn osisẹ ni owo yii, ko si wa fun yiya rara.

Awa gẹgẹ bii osisẹ ko ni gba rara, o din ni ida marun osisẹ to n seto mọda-mọda owo ifẹyinti naa.

Owo naa si lo wa lati ọpọ awọn osisẹ ijọba apapọ ati ẹka osisẹ aladani, bawo wa lẹ se kore nibi ti ẹ ko gbin si.?"

Wabba tun wa lu aago ikilọ seti awọn gomina naa pe, ni ọjọkọjọ toun ba gbọ pe wọn ti ya owo ifẹyinti ọhun ni iwọde alagbara yoo bẹrẹ, ti gbogbo osisẹ yoo si da soju popo.

Maina dákú fún ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú, iléejọ́ sáré so ìjókòó rọ̀

Abdulrasheed Maina daku nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, @IamOhmai

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe alaga tẹlẹ fun ajọ to n se akoso owo ifẹyinti, Abdulrasheed Maina ti dku nile ẹjọ.

Bẹẹ ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni wọn di Maina ni apanyaka wa sile lati orilẹede Niger to salọ, ko ma baa fi oju wina igbẹjọ.

Amọ lasiko igbẹjọ ni aarọ oni Maina daku, ti wọn si n gbinyanju lati ji pada sile aye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fidio kan to gba ori ayelujara kan, to se alaye bi wọn se n ji Maina nile ẹjọ lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Abdulrasheed Maina daku nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, @IamOhmai

A gbọ pe deede aago mẹwa kọja isẹju marun ni alaga tẹlẹ fun ajọ to n sakoso owo ifẹyinti daku lasiko ti agbẹjọro rẹ, Anayo Adibe n sọrọ niwaju adajọ Okon Abang.

Isẹlẹ naa si lo mu ki ile ẹjọ so ijoko rẹ rọ fun igba diẹ, ki wọn le fun awọn osisẹ ọgba ẹwọn laaye lati setọju rẹ.

O si pẹ diẹ, ki Maina to yaju saye.

''Abdulrasheed Maina yóò wà ní ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n Kuje kó má ba tún sálọ''

Abdulrasheed Maina

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ileẹjọ giga nilu Abuja ti ni ki Ọga agba ẹka owo ifẹhinti lorilẹede Naijiria tẹlẹ, Abdulrasheed Maina wa ni ẹwọn Kuje titi igbẹjọ rẹ yoo fi pari.

Eyi waye lẹyin ti Maina gbiyanju lati sakuro lorilẹede Naijiria lẹyin ti wọn gba beeli rẹ.

Bakan naa ni ileẹjọ tu beeli rẹ tu beeli rẹ ka nitori o rufin to de beeli rẹ.

Nitori o salọ ni igbẹjọ rẹ ko fi waye fun oṣu kan nitori ko yọju si ileẹjọ.

Ọdun 2012 ni Ajọ EFCC ti fi ẹsun iwa ajẹbanu kan Abdulrasheed Maina, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa lati ọdun 2015.

Abdulrasheed Maina

Oríṣun àwòrán, MEDIAMAFIA

Ọ̀gá "pension" tẹ́lẹ̀, Abdulrasheed Maina tó sákúrò ní Nàíjíríà tí fojú ba ilé ẹjọ́

Ọga agba ẹka owo ifẹhinti lorilẹede Naijiria tẹlẹ, Abdulrasheed Maina ti wa ni ile ẹjọ bayii lori ẹsun iwa ajẹnu.

Eyi waye lẹyin ti Maina gbiyanju lati sakuro lorilẹede Naijiria lẹyin ti wọn gba beeli rẹ.

Ọdun 2012 ni Ajọ EFCC ti fi ẹsun iwa ajẹbanu kan Abdulrasheed Maina, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa lati ọdun 2015.

Ṣé lóòtọ́ ni ọ̀gá "pension" tẹ́lẹ̀, Abdulrasheed Maina ra ilé sí Abuja, Dubai àti Amẹrika?

Ajọ EFCC ti fẹsun kan Ọga agba ẹka owo ifẹhinti lorilẹede Naijiria tẹlẹ, Abdulrasheed Maina pe o ra ile nla si orilẹede Dubai, Amẹrika ati awọn ile miran si agbegbe Jabi, ni ilu Abuja to to iye owo miliọnu meji dọla, owo ilẹ okeere.

Ọkan lara awọn oṣojumikoro to jẹ oṣiṣẹ ajọ EFCC lo sọ bẹẹ ni ile ẹjọ giga to wa ni ilu Abuja.

Bakan naa ni oṣiṣẹ ajọ EFCC naa tun ni ẹlomiran to jẹ ẹlẹri, Adamu Modibbo to mọ nipa ọrọ ti Maina kojọ lọna eru naa ti jade laye nitori arun Coronavirus.

Wọn fikun pe awọn gba iwe eri mejilelọgbọn to fi mọ awọn ẹrọ bii hard disc ati flash drive, to fihan pe Maina ati ẹbi rẹ lo ni awọn ile nla naa.

'' Ileeṣẹ Northrich to jẹ ti Maina ni ọkọ to le ni aadọta ti wọn fi n sisẹ akẹrọ kaakiri, ti wọn si tun ni ile nla ni Dubai.''

''Iyawo rẹ, Laila Abdurrasheed naa ni awọn ileeṣẹ to n ṣe imọtoto ti wọn pe ni Spotless ati Flawless lasiko ti wọn n ṣe iwadii''

Amọ, adajọ Abang to n gbọ ẹjọ naa ti sun igbẹjọ siwaju di Ọjọ Kẹrin, Ọṣu Kejila, ọdun 2020.

Ọjọ Keji, Oṣu Kejila ni awọn agbofinro ni awọn ri Maina mu ni orilẹede Niger Republic lasiko to n tiraka lati sa kuro lorilẹede Naijiria, ki ajọ EFCC to gbe pada si Naijiria.

Ọdun 2012 ni Ajọ EFCC ti fi ẹsun iwa ajẹbanu kan Abdulrasheed Maina, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa lati ọdun 2015.