Corruption in Nigeria: Ojíṣẹ Ọlọ́run kan ní báwọn òbí ṣe ń jí owó ìlú kò, ní wọ́n ń fi lé ọmọ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Ojisẹ Ọlọrun kan ti woye pe ogun ti aarẹ Muhammad Buhari n gbe ti iwa ajẹbanu ko tii kun to rara.
Oludasilẹ ile ijọsin kan nilu Eko, Wolii Adegboyega Ajani lo woye ọrọ yii lasiko ipade akọroyin kan to ṣe lati sami ayajọ gbigbe ogun tiwa ajẹbanu lagbayee.
Ojisẹ Ọlọrun naa fikun pe, awọn elesinjesin gan ti kuna ninu gbigbe ogun tiwa ajẹbanu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ooni Adeyeye ti Ile Ife fẹ sèrànwọ́ owó iléèwè fún akẹ́kọ̀ọ́ 5 mílíọ̀nù ní Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọn he lẹ́yìn tó lu obìnrin ní jìbitì ìfẹ́ tí iye rẹ̀ tó $15,000 lórí ayélujára
- Àwọn jàndùkú ṣọṣẹ́ nílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun, wọ́n jí ọ̀pá àṣẹ gbé!
- Fr Mbaka, ọmọ ìjọ rẹ̀ kọ̀lu akọ̀ròyìn BBC, wọ́n lù wọ́n ní àlùdojúbolẹ̀
- Háà! Àgbo tí mò ń lò láti jò kó bá mi, ìdí mi ti yọ́ tán - Nkechi Blessing figbe ta
"Ni gbogbo agbaye, tàwọn eeyan ba gbọ nipa iwa ajẹbanu, owo jiji nikan ni wọn maa n ro si eyi to jẹ asise.
O dabi igba ti eeyan n wa ojutu si isoro mẹta amọ ti onitọun gbajumọ ẹyọ kanṣoṣo, to si fi awọn isoro yoku silẹ.

Oríṣun àwòrán, Adegboyega Ajani
Idi ree to fi yẹ ka tete san sokoto wa ko le lati gbogun tiwa ajẹbanu naa.
Nigba to n sọrọ lori bi ajẹbanu naa ṣe n fẹju si, Wolii Ajani ni yoo nira diẹ kiwa ajẹbanu to kasẹ nilẹ ni Naijiria.
"Bi awọn obi ṣe n ko owo ilu, naa ni wọn n fi iwa àjẹbánu ọhun le awọn ọmọ wọn lọwọ, eyi ti ko ni jẹ ka tete ri ọna abayọ siwa ajẹbanu naa."
Ojisẹ Ọlọrun naa ni gbogbo ẹka awujọ ni iwa ajẹbanu ti gogo pupọ, tàwọn oloselu atawọn gbajumọ si n ko owo ilu, ti wọn si tun n fi le awọn ọmọ wọn lọwọ.
Wolii Ajani wa rọ awọn ojisẹ Ọlọrun lati maa waasu tako iwa ibajẹ naa, ko le di ohun itan ni Naijiria
Ọ̀pọ̀ nkan tó n ṣẹlẹ̀ kò jẹ́ kí n gbàgbọ́ pé Naijiria wà ní abẹ́ ìdarí ẹnikẹ́ni - Wole Soyinka

Agba onkọwe, Ọjọgbọn Wole Soyinka ti sọ pe, oun ko gbagbọ pe Naijiria wa ni abẹ idari ẹnikẹni.
O sọ eyi nibi ayẹyẹ ikojade iwe rẹ tuntun, 'Chronicles of the happiest people on earth', nilu Eko.
Ọjọgbọn Wole Soyinka ṣapejuwe ọdun 2020 gẹgẹ bi eyi to ti buru julọ ti oun mọ lorilẹ-ede Naijiria.
O ni kii ṣe nitori ajakalẹ aarun Covid-19 nikan, ṣugbọn ọpọlọpọ awọn iṣẹlẹ to waye, ati iha ti ijọba kọ si wọn.
O to ogoji ọdun ti Soyinka ti n kọ iwe naa, ko to o gbe jade lọdun 2020.
Soyinka ni bi nkan ṣe ri bayii ni Naijiria, awọn ọmọ Naijiria ko mọ ibi ti wọn n lọ, tabi ibi ti irinajo wọn yoo pari si.
"Nnkan ti de ikorita ti eeyan ko ni idaniloju ibi to n lọ, ati ibi ti yoo pari rẹ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣoro ní Ijebu Ode, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo fi lọ sílé Tinubu - Rashidi Ladoja
- ‘Sim Card’ títà àti ìforúkọsílẹ̀ rẹ̀ dèèwọ̀ ní Nàíjíríà - NCC
- Ààrẹ Akufo-Addo la Mahama mọ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ Ghana fún sáà kejì
- Ẹ̀yin tí ẹ máa ń bú àwon tó sanra ni ẹ ń jẹ́ kí wọ́n ronú pa ara wọn - Eniola Badmus
- Ilé aṣòfin kò láṣẹ kankan láti pe ààrẹ Buhari wá rojọ́ lórí ọ̀rọ̀ ètò àbò - Malami
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrín Ronke Odusanya àti bàbá ọmọ rẹ̀, Jago? Nkan tí a mọ̀ nìyíì
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
"Bi mo ṣe sọ tẹlẹ, ọpọlọpọ nkan to n ṣẹlẹ ko jẹ kii eeyan o gbagbọ pe ẹnikẹni wa ni iṣakoso."
Soyinka sọ pe ọdun 2020 kii ṣe ọdun to dara rara fun oun, ni gbogbo ọna.
















