#Revolution March: Ìjọba Buhari ń wùwà bíi ìjọba Abacha lórí ọ̀rọ̀ Ṣoworẹ- Ṣoyinka

Wole Soyinka ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency

Ọjọgbọn Wole Soyinka ti sọ pe ijọba aarẹ Muhammadu Buhari n wuwa bi ijọba ologun labẹ oloogbe aarẹ Sani Abacha.

Soyinka bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣe mu ajefẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore nile rẹ.

Ọjọgbọn Soyinka ni o dabi igba tawọn agbesunmọmi mu yan lọganjọ oru nile rẹ.

Soyinka ni igbesẹ naa lodi sẹtọ ọmọniyan Soworẹ gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria.

Soyinka ṣalaye pe ko si ohun kan to tumọ si iditẹ gbajọba ninu gbogbo ọrọ ti Sowore sọ.

Bakan naa, agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana na sọ pe ṣisẹ iwọde ko ni ohun kankan ṣee pẹlu iditẹ gbajọba.

O sọ pe ọmọ Naijiria lẹtọọ labẹ ofin lati fẹhonu wọn han lori ohun ti ko ba tẹ wọn lọrun.

Àkọlé fídíò, Ayinla Kollington: ọ̀rẹ́ ni èmí àti Barrister kó tó jáde láyé
Àkọlé fídíò, Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

Ẹwẹ, ile iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti ṣalaye pe Sowore n gbero lati fi ifẹhonu han da Naijiria ru pẹlu awọn kan nilẹ okere lati ṣe mu.

Agbẹnusọ fun ile iṣe ọtẹlẹmuyẹ sọ fun BBC awọn fọwọ ofin mu Ṣoworẹ nitori o n gbero lati ditẹ gbajọba orilẹede Naijiria pẹlu ifẹhonu han.

Ile iṣẹ ọlọpaa ko sọ bo ya awọn yoo mu ẹnikẹni to ba kopa ninu iwọde ọhun lọjọ Aje.