#DaysOfRage: Sowore ní ìwọ́de náà kò ni gbèdéke ọjọ́ tí yóò parí

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

O ti to asiko lati sọ fun ijọba orilẹede Naijiria pe o to gẹẹ, bawọn ọmọ ipinlẹ Kwara ti sọ ninu idibo gbogbogbo to lọ.

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Ṣowore lo sọ bẹẹ nigba to gba BBC Yoruba sọrọ lori ifẹhonu han ''Days of Rage'' ti yoo bẹrẹ lọjọ Aje, ọjọ Karun un oṣu kẹjọ.

Ṣowore to jẹ ọkan lara awọn to ṣagbatẹru ifẹhonu han naa ṣalaye pe, ipinlẹ mẹtalelogun ni ifẹhonu han naa yoo ti waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa, awọn ọmọ orilẹede Naijiria to wa loke okun naa yoo darapọ mọ ifẹhonu han ọhun kaakiri agbaye.

Ṣowore ni ifẹhonu han yii, ti yoo bẹrẹ laago meje aarọ ko ni gbedeke ọjọ ti yoo pari, o ni o digba ti ijọba ba gbe igbesẹ ti yoo mu irọrun ba awọn ọmọ Naijiria kawọn to dẹkun ifẹhonu han.

Ṣowore ṣalaye pe, lara awọn to n fẹhonu han yoo lọ si ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati sọ ẹdun ọkun wọn fawọn aṣofin.

Awn obinrin ti ebi n pa to gbe ọmọ dani

Oríṣun àwòrán, @MubailuG

O ni ebi n pa awọn ọmọ Naijiria, ati pe ijọba ko faye ilọsiwaju silẹ fawọn ọmọ Naijiria, o sọ pe asiko ti to fawọn ọmọ Naijiria lati gbara wọn silẹ loko ẹru ati airiṣẹṣe.

Ṣowore fesi si ọrọ kan tawọn eeyan kan n gbe kiri lori ayelujara pe Ṣowore wa lara awọn to n ṣagbatẹru ifẹhonu han nitori pe o fidi rẹmi ninu idibo aarẹ to lọ.

Ninu esi rẹ, Soworẹ ni o si eyi kii ṣe igba akọkọ ree t'oun yoo darapọ mọ awọn to n ṣewọde.

O ni oun ti bẹrẹ si ja fẹtọ ọmọniyan lati igba ti oun ti wa nile iwe giga Fasiti Eko titi di asiko yii.

Ìfẹ̀hónú hàn ńlá ń bọ̀ ní Nàíjíríà lọ́jọ́ Aje láti bèèrè fún ìṣejọba rere

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni korajo

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Iroyin kan to n ja rainrain lawọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye ti fi ye ni pe iporogan, ifẹhonu han ati iwọde alagbara kan n bọ lọwọ Aje, ọjọ Karun osu kẹjọ, ni orilẹede Naijiria.

Iwọde ọhun ti wọn pe akọle rẹ ni #DaysOfRage abi #Revolution now ni awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni n lewaju rẹ, labẹ akoso oludije fun ipo aarẹ tẹlẹ, Ọmọyẹle Soworẹ, ti yoo si gbera ni aago mẹsan aarọ.

Koda, ẹgbẹ awọn agbẹjọro nipinlẹ Eko naa ti ikede ati fọnran aworan sita loju opo Twitter pe, awọn yoo gba ẹjọ ro lọfẹ fun ẹnikẹni tawọn agbofinro ba mu sahamọ nitori iwọde naa nitori awọn ọmọ Naijiria ni asẹ labẹ ofin lati se iwọde alaafia.

Gẹgẹ bi awọn alakoso iwọde naa ti wi, ida mẹrinlelọgọrin ninu ọgọrun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn ti setan lati darapọ mọ iwọde naa ni orilẹede Mọkanlelogun yika Naijira.

Fila to n sọ nipa iwọde naa

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Bakan naa ni wọn ni bi iwọde yii ba se n lọ yika Naijiria, naa ni yoo waa waye nilẹ United Kingdom, tawọn ọmọ Naijiria to wa nibẹ yoo si pejọ pọ si ileesẹ asoju ijọba Naijiria to wa nilu London fun iwọde.

Lara awọn ohun ti awọn ajafẹtọ ẹni naa n beere fun ni ilana isejọba rere eyi ti yoo dẹ awọn ọmọ Naijiria lọrun, paapa nidi ipese ina ọba to duro re pklu owo ti ko gunpa, ki ijọba si tun se atunse awọn ibudo ifọpo wa eyi ti yoo mu opin de ba asa ka maa ko epo wọle.