Olubadan: Àláfíà ni mò ń wá ní ìpínlẹ̀ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Olubadan ti ilu Ibadan ni o ya oun lẹnu bi awọn ọba mẹtadinlọgbọn ti gomina ana yan ṣe tun faake kọri pe awọn ko ni gbe ade ori wọn silẹ lati sisẹ pọ pẹlu Olubadan, Oba Saliu Adetunji.
Agbẹnusọ fun Oba Saliu Adetunji, Oloko Adeola lo sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ awọn ọba yii.
Adeola ni ipade alaafia bẹrẹ ni Ọjọ Aje ni ibi ti Olubadan ati meji ninu awọn ọba naa se fọwọsowọpọ lati kuro lori rogbodiyan to wa laaarin Olubadan ati awọn ọba to je ijoye tẹlẹ labẹ Olubadan.
O ni oun ti awon ri ka yii ba awọn ninu jẹ pupo, amọ alaafia je awọn logun nitori naa ni awọn se sọ wi pe ipade alaafia n tẹsiwaju laaarin Olubadan ati awọn ọba yii.
Agbẹnusọ fun Oba Saliu Adetunji, Oloko Adeola fi kun un wi pe Olubadan ni baba gbogbo Ibadan nitori naa ni Olubadan ko lee fẹ ki ilu o tu.
Ti a ko ba gbagbe, laipe yii ni Olubadan sọ fun awọn ọba yii wi pe ki wọn pada wa si aafin, amọ ki wọn ma de ade wa si aafin ti wọn ba n bọ.










