Ex Boko Haram: Àwa ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram kan kìí kírun, à ń mu ìmukúmu, a sì ń ṣe ṣìná

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní àsìkò tí ìjà Boko Haram pé ọdún mẹ́wàá ní àríwá Nàìjíríà, ọmọ ẹgbẹ́ náà tẹ́lẹ̀rí ti ṣàlàyé fún BBC pé, àwọn kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà kìí kí ìrun rara.
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó sọ pé òun ti túbá, tí òun kò sì bá ẹgbẹ́ náà ṣiṣẹ́ mọ́, tún fikun pé àìsí iṣẹ́ ló fàá tóun fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà.
Ó ṣàlàyé pé, ẹgbẹ́ náà tan ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ wọ inú rẹ̀, nígbà tó sì mú àwọn kan ní dandan lẹ́yìn tí wọ́n jí wọn gbé, tí wọ́n sì ń fi ikú dẹ́rù bà wọ́n tí wọ́n bá gbìyànjú àti jáde.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Da ẹran jẹ̀ nígboro, ko fẹ̀wọ̀n oṣù méje jura tàbí san ₦200,000 - Ilé aṣòfin Ọyọ dábàá
- Kí ni Oluwo lọ ṣe ní Aso Rock lẹ́yìn lẹ́tà rẹ̀ sí ààrẹ Buhari?
- Ọpọ̀ èèyàn ní kó mọ pẹ pápákọ̀ ofurufú ń bẹ nílùú Ibadan- Òṣìṣẹ́
- Òwò ẹrú pé irinwó ọdún tó bẹ̀rẹ̀, àwọn Amẹrika tó jẹ́ dúdú wá sí Afirika láti bẹ ilé wò
- Àkúntúnkú, ìgbà márùn ún rè é tí Shekau kú tí wọ́n ní kò kú mọ
Ó sọ pé lẹ́yìn ìgbà tí òun wọ inú ẹgbẹ́ náà, òun rò pé òun ń ṣe gbogbo nǹkan fún ẹ̀sìn Islam ni, kí òtítọ́ tó wá padà yéè.
"Nígbà tí wọ́n tàn wá wọ inú ẹgbẹ́ yìí, ẹ̀sìn Islam ni wọ́n fi tàn wá. Nígbà tí a ronú síi, a bá ríi pé kìí ṣe ẹ̀sìn Islam ni, ẹ̀tan lásán ni."
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó fi Boko Haram sílẹ̀ bá BBC sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kò fẹ́ ká dárúkọ rẹ̀.
Ó sọ pé àìníṣẹ́ ló fàá tí àwọn fi wọ ẹgbẹ́ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ . Ó ní nígbà tí àwọn yoo fi wọ̀ọ́, àwọn ríi pé ọ̀rẹ́ awọ́n kan ń máa ń mú owó wá.
O ni asiko yii si jẹ ígbà tí àwọn ń wa iṣẹ́ tí àwọn yóò máa ṣe láti fi rí owó.

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Ó fi kún u pé, ọ̀rẹ́ wọn ọ̀hún kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí mú díẹ̀ nínú wọn lọ, tí wọ́n sì ń rí N3,000 gbà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá jà tábí tí wọ́n bá digun jale àbí tí wọ́n gba owó ìtúsílẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin náà ṣe sọ, nígbà tí wọ́n fi wà nínú ìlú, iṣẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ni íjínigbé nítorí owó ìtúsílẹ̀.
Lẹ́yìn náà ló sọ pé, wọ́n padà sí inú igbó níbi tí wọ́n ti ń rán wọ́n níṣẹ́ láti lọ ṣe alamí àti kíkó àlàyé jọ nípa ibi tí wọ́n fẹ́ kọlù.
O sọ pé ní àsìkò náà, nǹkan tí wọ́n ń fún awọn kò ju ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta náírà lọ. Amọ o fikun pe àwọn ni ọ̀gá tí wọn n fún wọn ní ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, ₦500,000 tàbí ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira, ₦600,000 náírà ńbẹ.
Ṣùgbọ́n ó sọ pé tití tó fi jáde kuro ninu ẹgbẹ́ náà, òun kò fi ojú kan ọ̀gá kan nínú ẹgbẹ́ náà rí, tí kìí bá ṣe àwọn kan tí wọn yóò gbé ìbọn ńlá-ńlá ní àwọn ìgbà kọ̀kan.
Ó ní àwọn padà tẹ̀lé wọn wọnú igbó lọ níbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ko wọn ní pápámọ́ra.

Oríṣun àwòrán, AUDU MARTE
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, tó lo ọdún mẹ́jọ nínú ẹgbẹ́ Boko Haram sọ pé, inú òun kọ́kọ́ dùn pe ẹ̀sìn Islam ni òun ń ṣiṣẹ́ fún.
Ṣùgbọ́n ọ̀kàn òun bàjẹ́ nígbà tó hàn sí òun pé ẹgbẹ́ náà ti kùnà níbi ẹ̀sìn náà.
"Alkurani nìyí…nígbà tí mo wòó, mo ríi pé Ọlọ́run fi òfin de ṣìná àti ìmukúmu, mo si ríi pé wọ́n ń mu ìmukúmu, wọ́n ń ṣe ṣìná ọ̀hún.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Wọn yóò mú àwọn obìnrin wá tí wọ́n á máa bá lòpọ̀. Ẹlòmíràn kò tiẹ̀ ní bìkítà nípa ìrun kíkí, wọ́n yóò sì wá pa ẹni tó ń kí irun." Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ náà ṣe sọ.
Ó sọ wípé, eléyìí ló fàá tí wọ́n fi pinnu pé kìí ṣe nítorí Ọlọ́run ni wọ́n ń fi ń ṣe nǹkan yìí, tí wọ́n sì pinnu láti jáde kúrò nínú ẹgbẹ́ náà.













