Oyo Grazing Bill: Ilé aṣòfin ní yóò di èèwọ̀ láìpẹ́ láti ta ilẹ̀ fún darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laipẹ ni yoo di eewọ nipinlẹ Ọyọ fun awọn darandaran lati maa da ẹran jẹ laarin igboro tabi loju popo, ti ọkọọkan awọn daradaran yii yoo si tun lọ gba iwe idanimọ lọdọ ijọba.
Idi ni pe aba ofin kan ti wa niwaju ile asofin ipinlẹ ipinlẹ Ọyọ, eyi ti yoo sọ di eewọ fun awọn darandaran lati da ẹran jẹ loju popo, wọn si ti ka ofin naa, ti wọn pe ni Open Rearing and Grazing Regulation Bill ti ọdun 2019, fun igba keji bayii.
Awọn asofin mẹta to se onigbọwọ aba naa, eyiun Asofin Asimiyu Alarape, Sanjọ Adedoyin ati Abiọdun Fadeyi naa salaye pe, darandaran to ba tapa si aba ọhun to ba di ofin tan, yoo lọ si ẹwọn osu meje, tabi ko san owo itanran tii se ẹgbẹrun lọna igba naira tabi ko se mejeeji.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ofin yii lo nkan nipa fun awọn ọlọsin ẹran lati ye da ẹran lati agbegbe kan si omiran, amọ wọn ni asẹ lati fi ọmọlanke abi ọkọ gbe awọn ẹran naa lati ibudo kan si ekeji, ẹnikẹni ti ọwọ ba si tẹ pe o n ko ẹran kiri pẹlu ẹsẹ yoo san ẹgbẹrun lọna aadọta naira owo itanran tabi ko lọ si ẹwọn ọdun kan abi ko se mejeeji papọ.

Koda, ofin naa tun ni awọn darandaran yoo lọ gba iwe idanimọ lọdọ ijọba eyi ti wọn yoo maa gbe kọrun ni gbogbo igba, eyikeyi wọn ti ko ba si se bẹẹ yoo san ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira tabi ko fi ẹwọn ọdun meji jura, abi ko se mejeeji papọ.
Lakotan, ti aba ọhun ba di ofin tan, o ti di eewọ patapata fun ẹnikẹni lati gbe ilẹ fun awọn ọlọsin ẹran lati maa fi sin ẹran tabi fi haya, tabi ta fun wọn, ti eyi ba si ti waye, gomina ipinlẹ Ọyọ ni asẹ lati gbẹsẹ le iru iwe asẹ ilẹ bẹẹ.








