Oluwo ní Aso Rock: Ààrẹ gbàléjò Ọọ̀ni, Oluwo, àtàwọn ọba Yorùbá mìí

Oríṣun àwòrán, emperortelu1
Lẹyin ti Oluwo ti ilu Iwo Oba Abdulrasheed Akanbi kọ lẹta si aarẹ Muhammadu Buhari lori ibi ti abo de duro ni Naijiria, aarẹ ti gbalejo Ọọni atawọn ọba alade mii nilẹ Yoruba ati ẹya miiran.
Lara wọn ni Oluwo ti Iwo t'oun naa da si ọrọ abo Naijiria laipẹ yii pẹlu lẹta to kọ si aarẹ ninu eyi ti o ti kìlọ̀ fún ìjọba láti dojú kọ ètò ààbò tó mẹ́hẹ kí ogun má bá a wáyé.
Nibi ipade awọn lọba lọba lati iha Guusu-Ila Oorun Naijiria iyẹn awọn ọba Yoruba pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari, Oluwo tunbọ ṣe afikun ọrọ to fi ranṣẹ si aarẹ nipa ṣiṣe adura fun un.
Ọba Abdulrasheed fi si oju opo instagram rẹ pe "ki Ọlọrun tunbọ fun aarẹ ni oye lati ṣe aṣeyọri ni gbogbo ọna".
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ipade yii waye ni Aso Rock, ile aarẹ niluu Abuja. Nibẹ wọn tẹpẹlẹ mọ ọrọ abo ni Naijiria eyi ti wọn ni o kan tolori tẹlẹ mu to fi mu ki awọn oriade dide lọ ba aarẹ ṣepade.






















