Ibadan Airport: Ìdí rèé tí pápákọ̀ ofurufú Ibadan ṣe n dá paroparo ní gbogbo ìgbà

Ko fi bẹẹ si ilu kan ti eeyan n lọ loriẹede Naijiria ti ko ni ri ọkọ ibẹ wọ nilu Ibadan.
Bo ṣe oke ọya ni bo si ṣe ilẹ Igbo tabi Hausa, ọna gbogbo ni awọn ọkọ Ibadan maa n rin.
Ṣugbọn ohun iyalẹnu ni wi pe pupọ ninu awọn olugbẹ ilu naa ni ko mọ wi pe papakọ ofurufu to n bẹ nibẹ n ṣiṣẹ titi di asiko yii.
Ikọ iroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si papakọ ofurufu naa lati fi idi ọrọ mulẹ lori bi ọwọ iṣẹ ṣe n ya si ati lilọ-bibọ awọn arinrinajo ni papakọ ofurufu naa.Bo tilẹ jẹ wi pe awọn alakoso ti o yẹ ki o ba oniroyin sọrọ ko si ni ofiisi lasiko ti a ṣe abẹwo sibẹ, oṣiṣẹ kan ti o ni ki a fi orukọ bo oun lasiri lo tu iṣu de isalẹ ikoko lori papakọ ofurufu naa.

Lati bii ọdun mẹtadinlogoji sẹhin ni papakọ ofurufu naa ti wa nilu Ibadan, ṣugbọn irinajo ofurufu ko fi bẹẹ ja gara ni papakọ naa bii ti awọn ilu nla ti o ku.Titi di asiko yii, ileeṣẹ irina ofurufu to ni ọkọ baalu meji pere lo n bẹ ni papakọ naa, irinajo ti wọn si n lọ ju ni lati Ibadan si ilu Abuja.

Oṣiṣẹ papakọ naa fi idi ọrọ mulẹ wi pe aigbepẹli eto ọrọ aje ni papakọ naa lo mu ki ọga agba ileeṣẹ to n ṣe akoso irina ofurufu lorilẹede Naijiria, Captain Rabiu Yadudu ṣe abẹwo si ilu Ibadan l'Ojoru lati pe fun ajọṣepọ laarin ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ lori papakọ ofurufu naa.

Lara awọn ohun ti Yadudu beere fun lọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ ni lati wa ojutu si awọn ipenija to niṣe pẹlu ala ilẹ, eto aabo ati bẹẹbẹẹ lọ.O tẹsiwaju pe ọkan lara awọn ileeṣe to n ṣe amojuto ọkọ ofurufu nilu Eko ti fi ifẹ han lati maa bọ nilu Ibadan to si ni igbesẹ naa yoo pa kun eto ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ.Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde tẹwọ gba ajọṣepọ naa pẹlu alaye wi pe isọdọtun papakọ ofurufu ilẹ Ibadan yoo mu ki eto ọrọ aje gun oke agba.

Oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa ti o ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ tẹsiwaju wi pe ibi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ijọba apapọ yanju ọrọ naa si ni lati gbe igbesẹ akọkọ lori awọn arinrinajo to n lọ si irinajo mimọ nilu Mecca.Dipo ki awọn to n lọ lati ipinlẹ Ọyọ ṣẹṣẹ lọ gbera lati ilu Eko, papakọ ofurufu to n bẹ nilu Ibadan ni wọn o ti maa gbẹrẹ bayii.Bo tilẹ lẹ jẹ wi pe ẹẹkan lọdun ni irinajo naa yoo maa waye, ireti wa wi pe awọn onikarakata to n bẹ ni agbegbe naa yoo maa jẹ ere gọboi lasiko ti irinajo naa ba n waye.












