Ekiti fẹ́ kówó s'ígbó fún papakọ tí àwọn ará ìlú kò le lò - Ojikutu

Oríṣun àwòrán, Akure Airport
Onimọ nipa irinna ofurufu kan ti tako igbesẹ ijọba Ipinlẹ Ekiti ti o n mura lati bẹrẹ iṣẹ lori papakọ ofurufu ni ipinlẹ naa.
Awakọ̀ òfúrúfú agba ati onimọ nipa irinna ofurufu tó ti fẹ̀yinti, John Ojikutu ni otubantẹ ni papakọ ofurufu ni ipinle naa, nitori orisirisi ipenija lo wa nipinlẹ naa to yẹ ki ijọba dojukọ.
Ojikutu mẹnu ba ọpọlọpọ idi ti iru papakọ ofurufu yii ko fi mọgbọn wa.
Awọn oun to sọ ree:
1. Ibo ni èrò ti yoo lo papakọ ofurufu naa wa?
Awakọ̀ òfúrúfú Agba, John Ojikutu sọ fun ikọ BBC wi pe, papakọ ofurufu mẹrindinlọgbọn lo wa ni orilẹede Naijiria, eyi ti ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ ati awọn aladani da silẹ.
O ni ọdun to lọ ni gbogbo wọn lapaapọ ṣẹṣẹ ri to awọn arinrinajo to to miliọnu mẹtadinlogun laaarin ọdun kan.
O fi iye arinrinajo yii we eleyi ti papakọ ofurufu South Africa n ri ni lọdọọdun.

Oríṣun àwòrán, O R Thambo
Gẹgẹ bi o ti sọ, "Ni papakọ O R Tambo ni Johannesburg nikan ṣoṣo ni South Africa, miliọnu mejilelogun arinrinajọ lo n lo papakọ lọdun."
2. Ọpọlọpọ papakọ ofurufu Naijiia kii pa owo wọle
Onimọ naa ni yatọ si papakọ to wa ni Eko ati Abuja, awọn yooku ko pa owo ti wọn le fi maa tun wọn ṣe daradara.
O ni ọpọlọpọ arinrinajo miliọnu mẹtadinlogun to rin ni ọdun to kọja ni papakọ ofurufu Naijiria, Abuja ati Eko ni wọn ti rinrin ajọ.
O ṣalaye wipe yatọ si papakọ Port Harcourt ati Kano to le ko to miliọnu kan lara ero naa lọdun, ko tumọ si wipe papakọ ofurufu Kano ati Port Harcourt naa n ṣiṣẹ debi to fi le pa owo lati fi maa boju to wọn wọle.

Oríṣun àwòrán, Per second news
3. Papakọ ofurufu Akure ko jina si Ipinlẹ Ekiti
Ojikutu ni ko si idi ti ko fi yẹ ki Ipinlẹ Ekiti ati Ondo jijọ maa ṣe akoso papakọ ofurufu to wa ni Akurẹ nitori wipe wọn sun mọ ara wọn.
O ni ko mọgbọn wa ki papakọ ofurufu Ipinlẹ Ondo ti ko ri iṣẹ ṣe wa nibẹ, ki Ekiti naa tun ni awọn fẹ da tiwọn silẹ.
O ni ṣugbọn kii ṣe Ekiti nikan lo fẹ da iru aba bayii, Anambra naa fẹ da papakọ ofurufu silẹ bo ti lẹ jẹ pe papakọ ofurufu Enugu ko jina.
O fi ero han wipe awọn gomina iru ipinlẹ wọnyii ni lati lọ kẹkọọ si nipa ṣiṣe iṣẹ akanṣe ni ilu.

Oríṣun àwòrán, Google
4. Eniyan meloo lo ni owo lati wọ ọkọ ofurufu ni Ekiti?
Onimọ Ojikutu ni iba diẹ laaarin awọn ara Ekiti lo ni owo lati le rinrin ajo ofurufu, eyi to tumọ si wipe, owo ti wọn ba na si iru ọkọ ofurufu bẹẹ, ofo ṣaa ni.

Oríṣun àwòrán, Fayose
Ojikutu ṣalaye wipe, awọn irinṣẹ to n juwe ọna fun ọkọ ofurufu jẹ oun to wọn. Ati wipe, o nilo atunṣe ni igba meji ni ọdun. O ni owo ti wọn o fi maa tun ṣe nikan, awọn papakọ wọnyii ko le pa iru owo bẹẹ.
O ni ti eniyan ba lọ awọn popona, ile iwe ati awọn ile iwosan to wa ni iru awọn ipinlẹ to fẹ na owo yanturu si dida papakọ ofurufu silẹ wọnyii, wọn yoo ri wipe ọpọ awọn nkan miiran wa to nilo iro owo yii.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo si ti n fi ero han lori ipinnu ijọba Ipinlẹ Ekiti yii lori Twitter:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3













