Mí ò mọ nípa ilé Bukola Saraki ti wọn ti pa- agbẹnúsọ EFCC

bukola

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán, Mí ò mọ nípa ilé Bukola Sara ki ti wọn ti pa- agbẹnúsọ EFCC

Ajọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgúdujẹrá lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà (EFCC) ní àwọn ò mọ nípa ilé ààrẹ ilé igbìmọ aṣòfin Bukola Saraki ti wọn ti pa oo

Adele agbẹnusọ fún iìròyìn àti ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ọgbẹ́ni Tony Orilade ló sọ èyí di mímọ fún àwọn oníròyìn nílu Abuja.

" kò si ẹni to tíì sọ èyí fún mi "

Àkọlé fídíò, Àwọn onímọ̀ ọpọlọ ní to bá gbé ìgésẹ̀ yí, aṣeyege dájú ní ìdánwò

Ilé ìgbé Saraki to wà ní Ikoyi ní wọn fẹ̀sún kàn pé àwọn ajọ tó ń gbógun ti ìwá jẹgudujẹra tìí pa ní ìlú Eko.

Láìpẹ yìí ni àjọ to n ri si ìwá jẹgudujẹra tún si iwe ìránti kan àwọn ẹsún tuntun míràn fún Bukola Saraki láti wá wi tẹnu rẹ̀ lásìkò to lò gẹ́gk bii ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin àti bí ó ṣe ná owó ìpínll Kwara lásìkò to jẹ gómìnà láàrin ọdún 2003 si 2011.Bukola Saraki kò kọjá òfin - EFCC