Ilé Aṣòfin: Buhari ni yoo dahun fun awọn to yan sipo

Ibrahim Idris

Oríṣun àwòrán, @NG_Police

Àkọlé àwòrán, Idris kọ̀ láti yọjú sí ilé aṣòfin l'Abuja lórí ètò ààbò

Lẹyin ìpàdé ijiroro alátìlẹ̀kùn mọ́rí se oní wakati mẹta, ile aṣofin àpapọ̀ l'Abuja ti fẹnu ko pe, awọn ko ni igbẹkẹle mọ́ ninu Ọga Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ibrahim Idris.

Wọn si tun fẹnu ko pe, awọn yoo ṣakitiyan lati ri pe ijọba awarawa fẹsẹ mulẹ.

Aarẹ ile Aṣofin Agba, Bukola Saraki lo ka igbese ile mejeeji naa jade, lẹyin ipade wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile aṣofin mejeeji tun paṣẹ nibi ipade naa, fun gbogbo ajọ eleto aabo ni orilẹede Naijiria, lati maa daabo bo awọn ọmọ orilẹede yìí.

Lori ọrọ Ọga ọlọpaa, wọn fẹnu ko wi pe, Aarẹ Muhammadu Buhari ni yoo dahun fun gbogbo awọn to yan sipo.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, awọn ile igbimo aṣofin mejeeji l'Abuja ti ranṣẹ pe Ọga ọlọpaa Ibrahim Idris, fun ifọrọwanilẹnuwo lori eto aabo ilẹ Naijiria.

Sugbọn ko ti i figba kankan da wọn lohun.