Agbẹjọro àgbà: Ara Melaye ti ya láti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ padà

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye
Agbẹjọro àgbà fún orílèèdè Nàìjíríà tí fí ìwé ránṣẹ sí ilé ẹjọ gíga tó wà ní Maitama nilu Abuja, láti bèèrè pé kí wọn bẹrẹ ìgbẹjọ padà lórí ẹsùn tí wọn fí kàn Senato Dino Melaye.
Won fi ìwé náà ranṣẹ ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà lẹyìn tí Senato Dino padà sí ilé aṣòfin àgbà lọgbọjọ oṣù kàrún-un.
Ṣáájú ni ilé ẹjọ gíga náà dáwọ ìgbẹjọ Senato Dino dúró, títí di igba ti ara rẹ yóò fi yà.
Ṣùgbọ́n bayi ti ọ ti bẹrẹ iṣẹ padà, ìwé náà to wa láti ọdọ agbẹjọro àgbà nfẹ kí adájọ fún àwọn ni ''ọjọ ti awọn yóò bẹrẹ ẹjọ náà padà ni ìbámu pẹlú àṣẹ tí ilé ẹjọ pá ṣáájú''
Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fún Senato Dino Melaye, Gideon Oladele ní, lootọ láwọn ti gbọ nípa ìwé tí agbẹjọro àgbà fi ṣòwò sí adájọ ṣugbọn ''awọn kò ti fojú kan iwe kánkan láti ọdọ adájọ.''
Bí a kò bá gbàgbé, adájọ Olasunbo Goodluck, lọjọ ketadinlogun osu kàrún-un ọdún 2018 dajọ pe, ki wọn sun ẹjọ Senato Dino Melaye siwaju títí di ìgbà tí ará rẹ yóò fi yà.
Agbẹjọro àgbà wa n pé Senato Dino Melaye lẹjọ, lori ẹsùn méjì ọtọọtọ, eyi tó níi ṣé pẹlú pé, ọ paro fún àwọn agbofinro láti lè ṣe àkóbá fún Olori àwọn oṣiṣẹ ní ilé ìjọba ní ọfisi Gómìnà ipinle Kogi, ọgbẹni Edward Onoja wí pé o rán àwọn èèyàn láti pá òun.








