Ọlọ́páà Kogi; Afunrasí méjì nínú ọ̀rọ̀ Melaye ti sá l’àhámọ́

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Melaye Facebook

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹnu kò sìn lára Dino Melaye

Iléesẹ́ ọlọ́ọ̀pá ní ìpínlẹ̀ Kogi sọ wípé àwọn afunrasi méjì tó wà ní pańpẹ́ àwọn lórí ẹ̀sùn wípé wọ́n ń sisẹ́ agbénipa fún Sẹ́nátọ̀ Dino Melaye àti Mohammed Audu ti na pápá bora.

Ìsẹ̀lẹ̀ yí wáyé lẹ́yìn tì iléesẹ́ ọlọ́ọ̀pá orílẹ̀èdè Nàíjìrìà kéde wípé wọ́n ń wá Melaye láti fi páńpẹ́ ọba mú un lórí ẹ̀sùn tí àwọn afunrasi méjì, Kabir Seidu,a.k.a Osama àti Nuhu Salisu a.k.a Small fi kàn kan an wípé òun ni bàbá ìsàlẹ̀ tó ń rán àwọn nísẹ́ agbénipa.

Komisona fún iléesẹ́ ọlọ́ọ̀pá ní ìpínlẹ̀ Kogi, Ali Janga ní àwọn afunrasi mẹ́fà ló na pápá bora ní òwúrọ̀ Ọjọ́ọ́rú ní iléesẹ́ ọlọ́ọ̀pá ti ìpínlẹ̀ Kogi, tó wà ní olú ìlu náà, Lokoja.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Àwọn afunrasí méjì tó níí se pẹ̀lú Sẹ́nátọ̀ Dino Melaye ni ọwọ́ pańpẹ́ àwọn ọlọ́ọ̀pá mú ní Osù Kínní, odún yìí, tí wọn sì sọ wípé sẹ́nátọ̀ náà ló rán àwọn ní isẹ́, láti da ìpínlẹ̀ Kogi rú sáájú ìdìbò gbogboògbò tọdún 2019.