Wo iye ìgbà tí ẹnu ti kun àwọn olọgun Naijiria pé wọ́n fẹ́ gbéna wojú àwọn adari

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ pe irọ ni iroyin kan to n lọ ni igboro pe awọn ọmọ ogun fẹ gbena woju awọn ọga wọn.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti ileeṣe naa fi lede loju opo X rẹ lọjọ Aje, ti agbẹnusọ rẹ, ọgagun Appolonia Anele, buwọlu.
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe awọn ọmọ ogun naa fẹ gbena woju awọn adari wọn latari awọn ọrọ kan ti owo oṣu atawọn ajẹmọnu wa ninu rẹ.
Amọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ pe irọ nla gbaa ni iroyin naa ati pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
Ileeṣẹ naa ni ko si asiko kankan ti awọn ọmọ ogun naa gbiyanju tabi dunkoko lati kọ ọrọ mọ awọn adari wọn lẹnu tabi gbena woju ẹkun wọn.
Anele sọ pe awọn ọmọ ogun ọhun mọ pe ẹṣẹ ni irufẹ iwa bẹẹ labẹ ofin ileeṣẹ naa, ati pe ijiya to nipọn lo si n bẹ fun ẹnikẹni to ba dan iru rẹ wo.
O ni digbi lawọn ọmọ ogun Naijiria wa lẹyin ijọba apapọ, wọn ko si ṣẹtan lati dalẹ ijọba to wa lode lonii.
Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ọrọ bayii yoo jẹyọ amọ ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria yoo sọ pe ko ri bẹẹ.
Iye igba ti ẹnu ti kun awọn ologun lori gbigbe ina woju awọn alaṣẹ ni Naijiria
Inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025
Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni iroyin gbode pe iditẹgbajọba kan ko ba waye ni Naijiria amọ awọn agba nileeṣẹ ọmọ Naijiria tete pa ina rẹ.
Ṣaaju iroyin naa ni ijọba apapọ ti kọkọ kede pe oun wọgile eto iyanfanda awọn ọmọ ogun to yẹ ko waye lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa kan naa, to jẹ ayajọ ọjọ ominira Naijiria.
Awọn iroyin kan sọ pe nitori idunkoko iditẹgbajọ naa ni Aarẹ Bola Tinubu ṣe wọgile ayẹyẹ iyanfanda awọn ologun naa.
Amọ ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọmọ ogun fi lede, o ni eredi ti Aarẹ fi wọgile ayẹyẹ naa ko ṣẹyin ati lọ yọju sawọn ipade kan to ṣe pataki si Naijiria nilẹ okeere.
Lẹyin eyii ni iroyin mii tun lu sita pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun fi ṣikun ofin gbe awọn ologun mẹrindinlogun, lori ipa ti wọn ko ninu igbiyanju lati ditẹgbajọ naa.
Koda, a tilẹ gbọ pe awọn oloṣelu kan bii Timipre Silva wa lara awọn to n ṣe onigbọnwọ iditẹgbajọ ọhun.
Ko pẹ si asiko yii ti ileeṣẹ ọmọ ogun tun fesi pe irọ ni iroyin naa.
O sọ lọjọ naa pe lootọ lawọn mu awọn ologun kan amọ kii ṣe nitori wọn n mura ati ditẹgbajọ, bikoṣe pe wọn ṣe awọn aṣemaṣe kan to lodi si ilana ileeṣẹ ọhun.
Lẹyinorẹyin, ileeṣẹ ọmọ ogun ni awọn ko nifẹ si ati ditẹgbajọba lọwọ Aarẹ Tinubu, awọn si ṣetan lati ṣatilẹyin fun ijọba rẹ ko le ṣe aṣeyọri.
Amọ ṣa, ko pẹ lẹyin gbogbo gbas-gbos naa ti ijọba apapọ paarọ awọn lọgalọga nileeṣẹ ọmọ ogun.
Oṣu Kinni ọdun 2026
Ni kutu hai ọdun 2026 ni iroyin mii tun gbode pe awọn ologun Naijiria n mura lati wo oju awọn ọga wọn lori owo oṣu wọn ti ko to nnkankan, atawọn nnkan mii.
Kii ṣe iroyin tuntun pe iye ti awọn ologun naa n gba, paapaa awọn ti ko si nipo adari, kere jọjọ.
A ti ri awọn fidio kan sẹyin nibi ti awọn ologun kan ti n sọ pe owo ti wọn n gba kere jọjọ.
Ọmọ ogun kan tilẹ sọ lọdnu kan pe owo oṣu oun ko to lati wọ ọkọ ayọkẹlẹ lati oju ogun ti oun wa ni Borno lọ sile lati lọ ri awọn ẹbi oun.
Ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters jabọ pe awọn ologun naa kọ lẹkan si Aarẹ Tinubu pe owo oṣu wọn ko to wọn ati pe iwa ajẹbanu awọn adari wọn ti pọ ju.
Ninu lẹta naa ni wọn ti sọ pe owo ti ko to 20,000 pere lo gun ori owo oṣu awọn ti wọn sẹṣẹ gbe ga lẹnu iṣẹ, eyii ti ko to nnkankan pẹlu bi igboro ṣe ri lonii.
Ṣe ologun ṣi le ditẹgbajọba n Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba bii mẹjọ ọtọtọ ni ologun ti ditẹgbajọ ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Naijiria kan, ti pupọ wọn jẹ 'Gen Z,' n pe fun iditẹjọgba gẹgẹ bo ṣe waye lawọn orilẹede Afrika kan.
Awọn ọdọ naa tun sọ pe ko fi bẹẹ si iwa jẹgudujẹra ati iwa ọdaran nigba ijọba ologun bi ti asiko yi, nitori naa ki ologun gbajọba.
Amọ awọn agba ti wọn ti ni iriri n sọ pe ijọba ologun ko ni ṣe anfani kankan fun Naijiria.
Ọjọgbọn Kayọde Sorẹmẹkun onimọ nipa itan tọka si i pe igbesẹ iditẹ gbajọba lo ṣeeṣe ko maa lee waye ni Naijiria mọ.
Adedeji Adekunle ẹni ọdun mọkandinlọgọta mẹnuba iriri rẹ gẹgẹ bii akẹẹkọ ni ibere ọdun 1998, O sọ fun BBC pe inira oun pọ lasiko ti ijọba ologun gbode.












