Kà nípa àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba ológun tó ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria àti ìpa tó ní

Oríṣun àwòrán, @The Nigerian Army
Iditẹgbajọba ki i ṣe nnkan ana lorilẹede yii, ọdun tipẹ ti awọn ologun ti maa n kora jọ lasiko ti wọn ba ro pe o tọ lati yi ijọba to wa lori aleefa lagbo da sina.
Latari eyi to ṣi n ja rain-in ninu ijọba Aarẹ Tinubu yii, ti wọn ni awọn ṣọja kan fẹ gbajọba lọwọ Aarẹ, BBC News Yoruba sẹ atupalẹ awọn igba ti iditẹgbajọba ti waye lorilẹede yii.
Bakan naa ni iroyin ṣalaye awọn orilẹede Africa ti igbiyanju lati gbajọba ti waye laaarin asiko ti Aarẹ Tinubu di olori Naijiria.
Ati ipa ti iditẹgbajọba tilẹ maa n ni lara ilu to ba ti ṣẹlẹ.
Wọ̀nyí ni àwọn ìgbà tí Naijiria kojú ìdìtẹ̀gbàjọba láti ọwọ́ ológun
Latigba ti Naijiria ti gba ominira ni 1960 ni wọn ti n koju iditẹgbajọba.
Laaarin 1966 si 1999, awọn ologun lo dari Naijiria lai si idiwọ kan, yatọ si asiko ijọba awaraawa ranpẹ to waye ni 1979 titi de 1983.
Awọn iditẹgbajọba to ti waye ni Naijiria:
1).Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni ọdun1966: Ikọ ọjẹwẹwẹ ologun kan doju ijọba Naijiria de, wọn si fopin si ijọba awaarawa akọkọ ti Naijiria ni.
Kaduna Nzeogwu ni ṣọja to ṣaaju awọn ologun naa, wọn si pa awọn olori bii Tafawa Balewa, Ahmadu Bello, Ladoke Akintola, Festus Okotie-Eboh to jẹ minisita eto iṣuna ati awọn ọga ṣọja mẹrin l'Oke-Ọya.
Awọn to gbajọba naa sọ pe awọn fẹ gbogun ti ajẹbanu ati jagidijagan ni, Ọgagun Johnson Aguiyi Ironsi, lo pada di olori orilẹede
2) Oṣu Keje ọdun 1966: Iditẹgbajọba eyi lo da oju ijọba Ironsi de. Nigba to si di ọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹjọ, Ọgagun Yakubu Gowon di olori Naijiria.
Agunyi Ironsi ati Ọgagun Francis Adekunle Fajuyi to jẹ gomina Iwọ Oorun nigba naa wa lara awọn to ba a lọ.
Awọn iditẹgbajọba mejeeji yii lo bi ija ẹlẹyamẹya, to pada di ogun abẹle.
Lẹyin ti ogun pari, loṣu Kẹwaa ọdun 1970, Ọgagun Gowon loun yoo ri i pe ijọba ṣọja pari lọjọ akọkọ oṣu Kẹwaa ọdun 1970, ṣugbọn ni 1974, o tun sun un siwaju.
3) 1975: Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Keje ọdun 1975: Ọgagun Joseph Nanven Garba, ọrẹ timọtimọ fun Gowon, kede lorii Radio Nigeria, pe oun atawọn ologun kan ti pinnu lati gbajọba lọwọ Gowon.
Ko si ipaniyan ninu iditẹgbajọba yii, nitori Gowon ti rin irinajo lọ si oke okun lati ṣe eto kan ti Organisation of African Unity, gbe kalẹ, ni Kampala.
Ọgagun Murtala Muhammed lo gbajọba lọwọ Gowon, nigba ti Ọgagun Olusegun Obasanjo jẹ igbakeji rẹ.
4) 1976: Ọjọ kẹtala, oṣu Keji ọdun 1976: Wọn pa Murtala Muhammed ninu iditẹgbajọba, wọn si pa dẹrẹba rẹ ati amugbalẹgbẹẹ to n ṣọ ọ.
Bakan naa ni wọn pa Ibrahim Taiwo, gomina ologun ipinlẹ Kwara nigba naa.
Eyi lo sọ Obasanjo di olori orilẹede Naijiria, lẹyin iku Murtala.
Ijọba Naijiria kede pe Ọgagun Bukar Suka Dimka, lo lewaju iditẹgbajọba naa, pẹlu erongba lati da Yakubu Gowon pada sijọba.
Wọn mu eeyan 125 lori iditẹgbajọba yii, eeyan 32 si gba idajọ iku. Lara wọn ni Dimka ati Ọgagun Illiya D. Bisalla. Obasanjo lo pada ṣeto idibo to gbe Shehu Shagari wọle si ijọba alagbada.
5.) 1983: Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila ọdun 1983: Awọn ọga ṣọja kan kora jọ, fopin si ijọba alagbada ẹlẹẹkeji. Wọn le Shagari danu, Oloogbe Ọgagun Sani Abacha to kede opin ijọba naa si ṣapejuwe rẹ bii ijọba alajẹbanu.
Wọn pa Brigadier Ibrahim Bako lasiko ti wọn fẹ mu Sahagari l'Abuja, Ọgagun Muhammed Buhari si di olori Naijiria.
6. )1985: Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 1985: Ikọ ologun ti Ọgagun Ibrahim Babangida lewaju, gba ijọba mọ Buhari lọwọ, wọn pe e ni iditẹgbajọba aafin.
Buhari rin irinajo lọ siluu Eko nigba naa ni, igbakeji rẹ, Ọgagun Tunde Idiagbon, si rin irinajo lọ si Saudi Arabia fun iṣẹ ẹ̀sìn, ki wọn too de ni wọn ti gbajọba mọ wọn lọwọ.
Ọgagun Joshua Dogonyaro lo kede iditẹgbajọba naa lorii redio laaarọ, ki Babangida to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ.
Babangida sọ pe ijọba to duro tandi soju kan ni Buhari n ṣe lo jẹ kawọn gba a mọ ọn lọwọ, o ni ko kunju oṣunwọn.
7.) 1990: Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin ọdun 1990: Awọn ologun ti Ọgagun Gideon Orkar, dari, kọju ija si Bareke ologun; Dodan Barracks, ni igbiyanju lati gbajọba Babangida.
Ṣugbọn Babangida raye sa lọ, rogbodiyan naa si pari lẹyin wakati mẹwaa.
Awọn ọga ologun sọ pe ẹyin Babangida ni awọn wa, eeyan mejilelogoji (42) ni wọn lo jẹbi ẹsun yii, gbogbo wọn ni wọn si yinbọn pa loṣu Keje ọdun 1990.
8.)1993: Nigba ti ẹnu bẹrẹ si i kun Babangida ju, pe ko gbe ijọba fun alagbada, ṣọja yii yẹba nipo agbara, o si yan Ernest Shonekan bii olori ijọba Fidi-hẹ-ẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 1993.
Ṣugbọn ijọba Shonekan ko ju oṣu mẹta lọ.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 1993 ni Ọgagun Sani Abacha le e danu, lẹyin ti wọn fagile ibo June 12 ti MKO ti gbegba oroke.
Kí ni ipa tí ìdìtẹ̀gbàjọba máa ń ní lára orílẹ̀èdè?

Oríṣun àwòrán, @The Nigerian Army
Ọjọgbọn Kenneth Nweke, onimọ nipa oṣelu, to si tun jẹ olukọ nipa oṣelu nile ẹkọ giga Ignatius Ajuru University of Education, Rumuolumeni, ipinlẹ Rivers, ṣalaye pe bi iditẹgbajọba ba waye lasiko ijọba Dẹmokresi ni Naijiria, o maa n fa gbogbo ẹtọ ijọba awaarawa sẹyin ni.
O ni o si maa n gba ominira lọwọ awọn eeyan, ko ni i jẹ ki wọn ni anfaani ti awọn eeyan maa n ni lasiko ijọba alagbada.
Ọjọgbọn Nweke sọ pe inu awọn eeyan Africa maa n dun bi wọn ba ni ijọba awaarawa, ṣugbọn aiṣe deede lẹka ọrọ aje ati igbayegbadun araalu pẹlu awọn iṣoro miran maa n jẹ ki ọrọ wọn su awọn eeyan ti wọn fibo gbe depo.
"O ṣe ni laaanu pe bi alagabda ba de ori aleefa tan, ti wọn leri pe awọn yoo fi ọdun mẹrin awọn ṣe bẹbẹ, wọn ko ni i ṣe pupọ ninu ileri wọn, wọn yoo tun maa wa ọna ọdun mẹrin mi-in si ni.
"Eyi lo maa n mu ọrọ wọn su araalu, ti wọn yoo si sọ ireti nu ninu ijọba Dẹmokresi. Ohun to maa n fa a naa niyẹn ti ologun fi maa n wa gbajọba, gẹgẹ bi a ṣe ri i lawọn orilẹede kan l'Africa, paapaa, Iwọ-Oorun Africa. (West Africa.)
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Nweke ṣalaye.
O ni iwa awọn alagbada lo maa n mu ki araalu maa pe fun ijọba ṣọja, ti wọn nigbagbọ pe yoo le mu nnkan amayedẹrun wa fun araalu.
Ọjọgbọn Nweke sọ pe bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ologun ti ni irọ ni iroyin iditẹgbajọba to n lọ lọwọ yii, o ni o ṣi yẹ ki awọn oloṣelu mọ pe wọn ko ṣe ojuṣe wọn bo ṣe to.
Ati pe bi koko ba n fẹ ni lẹfẹẹ, a ki i jẹ ori imado.
Àwọn oriílẹ̀èdè Africa tí ológun ti gbàjọba láàárín ìṣàkóso Ààrẹ Bola Tinubu
Lati ọdun 2023 ti Aarẹ Bola Tinubu ti gun ori aleefa, wọnyi ni awọn ibi ti ṣọja ti gbajọba nilẹ Africa, ti wọn le alagbada lọ ráúráú.
Niger: Oṣu Keje ọdun 2023 ni iditẹgbajọba waye ni orilẹede Niger.
Awọn ologun to n ṣọ aarẹ Mohamed Bazoum lo ti i mọle, gba agbara lọwọ rẹ.
Wọn ni eto aabo mẹhẹ ninu iṣejọba rẹ, bẹẹ ni ilana iṣelu rẹ buru jai.
*Sudan: Ogun abẹle lo ṣẹyọ loṣu Kẹrin odun 2023 ni Sudan, lẹyin rẹ si ni iditẹgbajọba waye.
*Gabon: Loṣu Kẹjọ ọdun 2023, awọn ọga ologun da oju ijọba aarẹ Ali Bongo de, lẹyin ti wọn kede rẹ pe oun lo bori ibo.
Ọgagun Brice Oligui ni wọn yan sipo olori orilẹede lati maa ṣejọba lọ.
Burkina Faso:
Loṣu Kẹsan-an ọdun 2023, igbiyanju lati gbajọba waye, o si pada di ohun to gbe Ọgagun Ibrahim Traoré de ipo olori orilẹede naa, titi digba ti wọn yoo ba tun dibo.
Sierra Leone:
Igbiyanju lati da oju ijọba ilu yii dele waye loṣu Kọkanla ọdun 2023, ṣugbọn ko kẹsẹjari, wọn ko ri i ṣe.
Ṣé lóòòtọ́ọ́ làwọn ológun gbìyànjú láti gbàjọba Ààrẹ Bola Tinubu? Iléeṣẹ́ ológun fèsì

Oríṣun àwòrán, Defence headquarters/Bola Ahmed Tinubu/X
Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti sọ pe irọ nla to jina si oootọ ni iroyin kan to sọ pe awọn ologun gbiyanju lati gba ijọba Aarẹ Bola Tinubu.
Iroyin ọhun lo ni ileeṣẹ ologun Naijiria wọgile eto yiyan bi ologun nibi ayẹyẹ ayajọ ominira ọdun karundinlaadọrin orilẹede Naijiria nitori awọn ọmogun kan to gbiyanju lati doju ijọba Tinubu bolẹ.
Iroyin naa tun sọ pe awọn ọmogun mẹrindinlogun ti ileeṣẹ ologun Naijiria ju si ahamọ ti wọn si n sọ tẹnu wọn lọwọ lọwọ ni ṣe pẹlu igbiyanju lati gbajọba alagbada to wa lode.
Amọ, adari eto iroyin nileeṣẹ ologun Naijiria l'Abuja, Ọgagun Tukur Gusau, ti sọ pe iroyin ofege pọnbele ni iroyin ọhun, ati pe ọna lati da ibẹru-boju silẹ ni.
Ọgagun Gusau tun ni iru iroyin yii tun le kọ ẹyin araalu si ijọba to wa lode.
''A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe nnkan ti ko jẹ kawọn ọmogun yan bi ologun lati ṣayajọ ominira ọdun karundinlaadọrin Naijira ni ipade kan ti aarẹ Tinubu lọ fun nilẹ okeere lasiko naa.
Idi miran ni lati jẹ kawọn ọmogun le kọju mọ gbigbogun ti awọn agbesunmọmi, agbebọn atawọn janduku ti wọn n fẹmi araalu ṣofo.
A tun wa fi n dawọn eeyan loju wi pe awọn ọmogun mẹrindinlogun ti iwadii n lọ lọwọ lori wọn ko gbimọ pọ lati gba ijọba.
Iru iwadii bayii maa n waye fawọn ọmogun to ba ti tasẹ agẹrẹ ninu iṣẹ ologun, a o si jẹ ki araalu mọ abọ iwadii ọhun ti o ba ti jade,'' Ọgagun Gusau ṣalaye.
''Ileeṣẹ ologun ko ni kaarẹ nipa jijẹ oloootọ si iwe ofin Naijiria ati si ijọba Aarẹ Bola Tinubu''
Adari eto iroyin ileeṣẹ ologun Naijiria wa ke pe gbogbo araalu lati tubọ maa ṣatilẹyin fawọn ẹṣọ eleto abo.
Ọgagun Guasau ni ijọba apapọ, ile igbimọ aṣofin agba ati ẹka eto idajọ n ṣiṣẹ pọ fun aabo, idagbasoke ati ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
O wa rọ ọmọ Naijiria lati kọ eti ikun si iroyin to lawọn ologun fẹ gbajọba Aarẹ Tinubu, adari eto iroyin ileeṣẹ ologun ni awọn ọta orilẹede Naijiria lo n gbe iroyin naa kiri.
Ọgagun Gusau ni ileeṣẹ ologun ko ni kaarẹ nipa jijẹ oloootọ si iwe ofin Naijiria ati si ijọba apapọ labẹ alaṣẹ Aarẹ Bola Tinubu, GCFR.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















