Ohun tá a mọ̀ nípa ìkọlù àwọn agbébọn tó ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Kaduna

Aworan awon araalu Birnin Gwari

Oríṣun àwòrán, Bashir Kutemeshi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbebọn tun ti se ikọlu tuntun si agbegbe Birnin Gwari ni ipinlẹ Kaduna, lẹyin ti ọpọ ijiroro alaafia waye ni agbegbe naa.

Ikọlu ọhun waye ni ilu Kuyallo, ti ọpọ ẹmi si ṣofo pẹlu.

Awọn araalu ni eeyan mẹsan an lo padanu ẹmi, ti ọpọ si tun farapa yanayan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna fi di iṣẹlẹ naa mulẹ ṣugbọn ni eeyan meje lo padanu ẹmi, ti eeyan marun si farapa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa DSP Mansir Hassan lo sọ eyi fun BBC.

O ti to ọdun kan bayii ni ijiroro alaafia ti waye laarin awọn eeyan Birnin Gwari ati awọn agbebọn, ti igbagbọ si wa pe ipade naa yoo mu alaafia wa si ilu naa.

Ẹwẹ, awọn araalu ni awọn agbebọn to ṣe ikọlu tuntun yii ni wọn wa lati ipinlẹ Katsina.

DSP Mansir Hassan ni awọn ọlọpaa koju awọn agbebọn naa kete ti wọn gbọ iroyin iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni ipinlẹ Kaduna, ọmọ ogun ileeṣẹ Ọlọpaa meji padanu ẹmi nigba ti awọn meji mii si farapa lasiko ti awọn agbébọn kan kọlu ileeṣẹ Ọlọpaa to wa ni agbegbe Zonkwa, ni ijọba ìbílẹ Zango-Kataf nipinlẹ Kaduna.

Bakan naa ni awọn agbebọn tun tu awọn ọdaran to wa ni atimọle silẹ lasiko ikọlu ọhun to waye ni alẹ Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa ọdun 2025

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti ọwọ tẹ awọn afurasi kan ti tu ẹrọ amunawa lọ ní agbegbe Ramai, agbegbe kan to sumọ ilu Zonkwa

Awọn agbebọn yìí, gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin abẹle, Channel TV ṣe ṣalaye, wa lati agbegbe Kachia ni ijọba ìbílẹ Kachia, tí wọn si yawọ ileeṣẹ Ọlọpaa ni Zonkwa.

Awọn tí iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ro pe olori wọn wa ni atimọle ni ileeṣẹ Ọlọpaa, ti wọn si gbiyanju lati gba itusilẹ rẹ pẹlu ikọlu ileeṣẹ Ọlọpaa.

Ọpọ awọn afurasi ọdaran to wa ni atimọle ni awọn agbebọn tu silẹ.

Ikọlu yii jasi ija nla laarin awọn agbebọn ati ileeṣẹ Ọlọpaa fun ọpọlọpọ wakati.