Àwọn wo ni àgbà amòfin márùn-ún tí Olubadan Ladoja gba láti gbógun ti àwọn ajagungbalẹ̀ n'Ibadan?

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Adewolu Ladoja, jokoo, o n rẹrin-in muṣẹ. O wọ agbada, de fila, o si fi ilẹkẹ oye sọrun
Àkọlé àwòrán, Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Adewolu Ladoja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lati koju iṣoro ọrọ awọn ajagungbalẹ ti ko fẹrẹ sibi ti ko si lorilẹede yii, Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, ti gba awọn agba lọọya ni Naijiria lati gbogun ti wahala naa nipinlẹ Oyo.

Olubadan gbe igbesẹ naa, gẹgẹ bi Akọwe iroyin rẹ, Adeola Oloko, ṣe kede ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọru.

Meji ninu awọn lọọya ti Olubadan gba lati koju iṣoro ijagungbalẹ lọna ofin ni wọn jẹ amofin agba, (SAN) ni Naijiria.

Awọn amofin ti Olubadan gbe iṣẹ naa le lọwọ ni:

Oloye Niyi Akintola, (SAN), Amofin Musibau Adetunbi, (SAN), Yinka Okunade, Rahman Abiodun AbdulRaheem ati Tunji Thomas

"Ohun tó fà á rèé tí mo ṣe fẹ́ gbógun ti àwọn ajagungbalẹ̀ n'Ibadan"

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tó fi gbé ìgbésẹ̀ náà, Ọba Ladọja ni ki awọn le ṣẹgun orukọ buruku ti awọn ajagungbalẹ n sọ ilu Ibadan ni igbesẹ yii ṣe waye.

Olubadan rọ awọn Amòfin náà lati ba awọn ẹka to n ri si aato ilu (Town planning) awọn wọnlẹ-wọnlẹ (Surveyor) ẹka aabo ati awọn to ba tun yẹ, ṣiṣẹ lati gbogun ti ijagungbalẹ.

Olubadan Ladoja sọ pe ijọba ipinlẹ Oyo pẹlu igbimọ Olubadan mọ nipa igbesẹ ofin yii, nitori fifi igba gba ilẹ onilẹ ko ọpọ nnkan sinu, o si yẹ ki ofin tu iṣu rẹ de isalẹ ikoko.

O paṣẹ ki wọn bẹrẹ iṣẹ kia, o si fun wọn ni ọjọ mọkanlelogun lati sọ awọn ohun ti wọn ba gbero.

Olubadan ṣalaye pe iṣẹ awọn lọọya yii ko di ti igbimọ ọrọ ilẹ ti Mogaji Asimiyu Ariori n dari lọwọ, bi ko ṣe lati ro o lagbara.

Diẹ lara awọn to wa nibi ipade naa ni: Otun Balogun, Oba Kola Adegbola; Otun Olubadan; Oba Eddy Oyewole; Osi Balogun, Oba Olubunmi Isioye-Dada; Osi Olubadan-, Oba Abiodun Kola-Daisi; Asipa Olubadan- Oba Hamidu Ajibade; Ekerin Balogun, Oba Akeem Adewoyin; Ekerin Olubadan, Oba Adebayo Akande ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Mọ nípa atimaasebọ àwọn àgbà amòfin tÍ Olubadan gbéṣẹ́ fún:

Amofin agba Niyi Akintola

Oríṣun àwòrán, @ Niyi Akintola (SAN)

Àkọlé àwòrán, Amofin agba Niyi Akintola

Oloye Adeniyi Micheal Akintola (SAN)

Ọmọ bibi ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo, ni Amofin agba Adeniyi Micheal Akintola. Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 1960 ni wọn bi i.

O lọ sile ẹkọ alakọọbẹrẹ I.D.C, ni Abule Seni, nitosi Omi Adio, ti Ogunsami ati ti Ebenezer African Church Primary School, Salvation Army Road, Ibadan.

Amofin agba Akintola kawe ni nile ẹkọ awọn ologun, Nigerian Army School of Education, Ilorin; ile ẹkọ Gbogboniṣe ipinlẹ Ogun, Yunifasiti ilu Ibadan, ati ile ẹkọ awọn amofin to wa nipinlẹ Eko, bẹẹ lo kawe loke okun.

Amofin Agba Akintola ṣiṣẹ olukọ ri nile ẹkọ Mac-Job Grammar School, l'Abeokuta, laaarin ọdun 1979-1981.

Ọmọwe to ja fafa ni laarin awọn ẹgbẹ rẹ nigba to wa nileewe awọn lọya l'Ekoo, o si yege ni gbogbo ẹka ẹkọ to ṣe.

Ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) lo wa nigba to gba oye amofin agba ni Naijiria (SAN).

Amofin Musibau Adetunbi (SAN

Agba amofin to ti ṣe ọpọlọpọ ẹjọ, to si ti jare ni Amofin agba Musibau Adetunbi.

Yunifasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife lo ti kẹkọ ofin, o gboye nile ẹkọ awọn lọya pẹlu, o si ti ṣe asẹyọri pupọ lẹka ofin ko to di Amofin agba Naijiria (SAN).

Ẹka ofin ti Amofin Adetunbi ti pegede ki i ṣe ẹyọkan.